Ìdí tí mo ṣe faramọ́ kí ọkùnrin fẹ́ ìyàwó méjì rèé àti ọ̀pọ̀ ànfààní tó wà níbẹ̀ - Ali Baba

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Nedu official/Instagram
Gbajugbaja adẹrin-inpoṣonu, Atunyota Alleluya Akpobome, ti ọpọ mọ si Ali Baba, naa ti ṣatileyin fun ki ọkunrin fẹ iyawo meji dipo ẹyọkan ti ọpọ eeyan n fẹ nitori ẹsin wọn tabi ọlaju.
Ali Baba fidi ọro yii mulẹ lori eto kan ti ilumọọka adẹrin-inpoṣonu ati sọrọ-sọrọ n ni, Nedu ṣagbatẹru rẹ.
Agbaọjẹ adẹrin-inpoṣunu naa ṣalaye pe ọpọ iyawo ile lo ti fi ọkọ rẹ silẹ yala nitori ọkọ rẹ n yan ale tabi o ti bimọ sita.
Ali Baba ni ''Amọ, lọpọ igba ọkunrin to ti ni iyawo nile ni iru awọn obinrin bẹẹ maa n yan lale.
Ti ọkunrin ba n yan ale tabi ti ale ba bi ọmọ fun un nita, iru ọkunrin bẹẹ ko le mu ọmọ naa wale.
Ṣugbọn obinrin le gbe ọmọ ale wa sinu ile lati ita, ti yoo si parọ wi pe ọkọ rẹ lo lọmọ naa.
Nnkan to jẹ ki ọrọ yii jẹ jade lasiko yii ni pe ọpọ eeyan to n japa lọ soke okun lo n ṣe ayẹwo DNA fawọn ọmọ wọn lati le mọ bo ya wọn kii ṣe ọmọ ale,'' Ali Baba ṣalaye.
Ali Baba ni fifẹ iyawo meji dara fun iṣọkan ati ibaṣepọ to dan mọran laarin awọn obinrin ile ati ọkọ wọn.
O ni bi obinrin pe meji lọọdẹ ọkọ, ko ni jẹ ki wọn ṣiwa hu.
''Awọn kan sọ pe ọkunrin le ma lanfaani lati dari iyawo kan, amọ, ti iyawo rẹ ba mọ pe o ni orogun; ko ni ṣiwa hu.
Iru obinrin bẹẹ yoo fara balẹ, yoo si huwa pẹlẹ tori o mọ wi pe oun ni orogun.''
Mo mọ obinrin kan n'Ibadan to fẹ iyawo kekere fun ọkọ rẹ - Ali Baba
Ali Baba tun fi awọn obinrin kan toun loun mọ niluu Ibadan ṣe akawe wi pe awọn funra wọn ni wọn fẹ iyawo fun ọkọ wọn ki o ma ba wo ita ati lati jẹ ki iṣọkan wa ninu ẹbi.
''Oriṣiiriṣii idi ni eeyan fi le fẹ iyawo meji, Mo tiẹ mo obinrin kan n'Ibadan to rọ ọkọ rẹ lati fẹ iyawo keji.
Ọpọ iru awọn obinrin bayii nigba naa lo maa n fẹ iyawo kekere fun ọkọ wọn.
Wọn maa n ṣe eleyii ki awọn ọkọ wọ ma baa ni ale nita.
Bakan naa, ọkunrin le di oniyawo meji ti o ba ṣupo, iyẹn ti o ba fẹ iyawo ẹgbọn rẹ to ku, ti o si bẹrẹ si ni gbe gẹgẹ bii lọkọ laya pẹlu iyawo ẹgbọn rẹ.
Wọn maa n ṣe eleyii lati le tọju awọn ọmọ oloogbe, ati lati dena ki iyawo to jẹ opo lo fẹ ẹbi mii,'' Ali Baba lo sọ bẹẹ.
Ali Baba ni awọn olori ẹbi lo maa beere lọwọ awọn ọkunrin ile wi pe ta lo le tọju iyawo oloogbe daadaa.
Ti ẹni to ba ṣu iru obinrin bẹẹ lopo ko ba ti ni iyawo nile, o di oniyawo meji niyẹn.
Gbajugbaja adẹrin-inpoṣonu naa ni bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan ni ko faramọ ki ọkunrin ṣupo, iru awọn ọkunrin bẹẹ lo maa n pada bi ọmọ to bii mẹta si marun un.
Amọ, Ali Baba duro lori ẹsẹ rẹ wi pe ko si nnkan to buru ninu ki ọkunrin fẹ iyawo meji.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ta a ni Ali Baba tawọn eeyan n sọ nipa lori ayelujara?
A bi adẹrin-inpoṣonu, Atunyota Alleluya Akpobome, ti orukọ rẹ n jẹ Ali Baba lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹfa lọdun 1965.
Ọmọ idile ọlọba Agbarha Otor ni ipinlẹ Delta ni Ali Baba i ṣe.
Ali Baba ni ọkunrin akọkọ fun awọn obi rẹ, o si ni ọpọlọpọ aburo lẹyin.
Adẹrin-inpoṣonu naa gbe niluu Warri fun ọdun mẹjọ nigba to n dagba nipinlẹ Delta.
Ajagun fẹyinti ni baba rẹ, o si ṣiṣẹ nipinlẹ Eko ki o to fẹyin ti.
Ali Baba lọ sile ẹkọ girama Command Secondary Scholol, Ipaja nipinlẹ Eko.
O tun kẹkọọ bakan naa nile ẹkọ giga Ibru College, Agbarha, nipinlẹ Delta.
Gbajugbaja adẹrin-inpoṣonu naa tẹsiwaju ẹkọ rẹ nile ẹkọ giga fasiti ipinlẹ Bendel ti wọn n pe ni Ambrose Alli University bayii, niluu Ekpoma.
Ali Baba kẹkọọ gboye ninu imọ ẹsin ati ẹkọ imoye.
Lasiko kan naa loun ati ilumọọka pasitọ Chris Oyakhilome jọ wa nile ẹkọ fasiti niluu Ekpoma.
Ali Baba pada si ilu Eko lẹyin to pari ẹkọ rẹ ni fasiti lọdun 1990.
Niluu Eko lo ti tẹsiwaju ṣiṣe adẹrin-inpoṣonu eyi to ti bẹrẹ nigba to wa ni ile ẹkọ giga fasiti niluu Ekpoma.
Bayii ni Ali Baba bẹrẹ sii pa awọn eeyan lẹrin-in nibi ayẹyẹ kaakiri ipinlẹ Eko.
Bakan naa lo tun bẹrẹ si ni ṣe awada pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ bii Patrick Doyle, Charly Boy ati Danladi Bako lori ẹrọ tẹlifisan.
O tun bawọn alẹnulọrọ lẹka igbosafẹfẹ mii bii Bisi Olatilo, Sani Irabor, Mani Onumonmu ati Ọmọba Adedapo Adelegan ṣiṣẹ pọ.
Lọdun 2014 ni Ali Baba bẹrẹ eto adẹrin-inpoṣonu ọlọdọọdun eyi to pe no ''1 January concert.''
Oniruuru awọn adẹrin-inpoṣonu lo maa n wa pa awọn eeyan lẹrin in nibi eto naa, wọn si maa n fawọn to ba fakọyọ nibẹ ni ẹbun gidi.















