Imisi: Àbùdá mẹ́ta ni mo fi hàn yín, àmọ́ mẹ́rin ni mo ní, èyí tí mo bá fẹ́, ni máà lò

Àkọlé fídíò, Àbùdá mẹ́ta ni mo fi hàn yín, àmọ́ mẹ́rin ni mí, èyí tí mo bá fẹ́, ni máà lò
Imisi: Àbùdá mẹ́ta ni mo fi hàn yín, àmọ́ mẹ́rin ni mo ní, èyí tí mo bá fẹ́, ni máà lò

Fun ọpọ eeyan to jẹ ololufẹ eto Big Brother Naija, ikẹwa iru rẹ to waye ninu ọdun 2025 taa wa yii, orukọ eeyan kan ni wn ko le gbagbe laelae.

Orukọ onitọhun ni Imisioluwa Ayanwale, obinrin to se ipo kinni ninu ile BB Naija naa fun ọdun yii.

Ọpọ eeyan to jẹ ololufẹ ọmọge naa si lo se atilẹyin fun lati yege ninu ile BB Naija naa.

Idi ree ti BBC News Yoruba se sawari obinrin naa lati mọ nipa igbe aye rẹ, ihuwasi rẹ ati idi to se bori idije naa.

Bakan naa, a fẹ mọ boya lootọ Imisioluwa jẹ ọmọ agbaọjẹ osere tiata kan, Kolawole Ajewole, gẹgẹ bawọn eeyan kan se n gbe kiri.

Imisioluwa Ayanwale to se ipo kinni nile Big Brother Naija fun ọdun 2025 joko lori aga kan, o na ọwọ osi soke bii ẹni to n ta ika, o fi irun wiigi dudu sori, o si fi igo akọ soke sori irun rẹ, o wọ asọ shaat alawọ miliki, o ọ sokoto alawọ buluu, to si lo bẹliti sori sokoto naa.

"Mo ni ipele to mẹrin ihuwasi ati abuda ti mo maa n hu, eyi to ba fẹ, ni maa fun ẹ"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Imisioluwa Ayanwale, ti ọpọ ololufẹ rẹ maa n pe ni Imisi ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aseyọri naa.

"Onigbagbọ gidi ni mi, mo si maa n sin Ọlọrun lotitọ ati ni ododo tori o ni ka sin oun pẹlu ọkan mimọ at ọwọ mimọ.

Ogo Ọlọrun lo kan fara han ninu aye mi tori n ko mọ se, ti ẹyin gan ba gbọ awn nnkan ti mo ti se sẹyin, ẹyin gan maa la ẹnu."

Nigba to n salaye iru eeyan to jẹ paapaa pẹlu ihuwasi rẹ nigba to wa ninu ile BB Naija, Imisi ni oun ni ọpọlọpọ ihuwasi.

"Mo ni ipele to mẹrin ihuwasi ati abuda ti mo maa n hu, eyi to ba fẹ, ni maa fun ẹ.

O le ri Imisi kan loni, ki o ri Imisi miran ni ọla, ko tun ri Imisi kẹta, o dabi pe Imisi mẹta ni mo fi han awọn eeyan nile BB Naija.

Ikẹrin ni ẹ maa wo lọ amọ Imisi yin ti ẹ si mọ naa ni."

"Mo maa n wọ kaba dabolẹ, bi mo se maa n mura niyẹn amọ nigba miran, mo le mura, to jẹ pe tawọn ọkunrun gan ba ri, yoo da bi ki wọn gba mi mu ni"

Nigba to n sọrọ lori awọn imura rẹ ninu ile BB Naija naa, Imisi salaye pe oun kii saba ro iro ati buba nibẹ.

"Iro ati buba bawo, boya mo maa n wọ Kaba, asọ kaba dabolẹ, bi mo se maa n mura niyẹn.

Amọ nigba miran, mo le mura, to jẹ pe tawọn ọkunrun gan ba ri, yoo da bi ki wọn gba mi mu ni.

Igba miran, mo kan maa n fẹ ki n kan mura, inu ile la wa o, gbogbo nnkan ta fẹ se, ko ju inu yara kan lọ.

Igba miran, maa kan fẹ mura lai kan gbogbo rẹ papọ, loju aye naa, bi mo se maa n mura niyẹ, bi mo si se n se ile aye mi niyẹn.

Ile aye yii ko le amọ ọbẹ ko ran."

Imisioluwa Ayanwale to se ipo kinni nile Big Brother Naija fun ọdun 2025 joko lori aga kan, o na ọwọ osi soke bii ẹni to n ta ika, o fi irun wiigi dudu sori, o si fi igo akọ soke sori irun rẹ, o wọ asọ shaat alawọ miliki, o ọ sokoto alawọ buluu, to si lo bẹliti sori sokoto naa.

"Buọda Kolawole Ajewole jẹ eeyan ti mo maa n gba imọran lọwọ wọn, wọn maa n tọ mi sọna, eeyan to daa ni wọn amọ n ko mọ ibi ti wọn ti gbọ pe ọmọ wọn ni mi"

Ọpọ eeyan lo n gbe kaakiri loju opo ayelujara pe ọmọ bibi inu Kolawole Ajeyemi, toun ati aya rẹ, Toyin Abraham Ajeyemi dijọ jẹ osere tiata, ni Imisioluwa Ayanwale.

Amọ nigba ti a bi Imisi pe se lootọ ni Kola Ajewole jẹ baba rẹ gangan, se lo bu sẹrin.

"Buọda Kola jẹ eeyan kan ni agbo osere tiata wa ti mo maa n gba imọran lọwọ wọn nipa awọn igbeseẹ ti mo ba fẹ gbe.

Wọn si maa n tọ mi sọna pe bayii ni ki o se see, wọn jẹ eeyan to daa amọ n ko mọ ibi ti wọn ti gbọ pe ọmọ wọn ni mi.

Awọn ọmọ wọn ti mo mọ ni Temitope ati Ireoluwa."

Imisioluwa Ayanwale to se ipo kinni nile Big Brother Naija fun ọdun 2025 joko lori aga kan, o n wo ilẹ, o fi irun wiigi dudu sori, o si fi igo akọ soke sori irun rẹ, o wọ asọ shaat alawọ miliki, o ọ sokoto alawọ buluu, to si lo bẹliti sori sokoto naa.

"Mo maa n bọwọ fun ofin, mo nifẹ ofin gan, bi ofin ba sọ pe maa san owo ori ninu ẹbun mi, maa kuku san-an"

Lẹyin ti Imisi yege nile BB Naija bii oludije to se ipo Kinni, ẹ́=bun owo ti yoo gba lapapọ jẹ miliọnu lọna aadọjọ Naira (N150m).

Amọ eyi to jẹ owo ti yoo gba ninu apapọ owo naa jẹ miliọnu lọna ọgọrin Naira.

Ko si pẹ ni iroyin n ja rain nilẹ pe ijọba yoo yọ owo gọbọi ninu ẹbun Imisi gẹgẹ bii owo ori.

Idi ree ti BBC News Yoruba fi beere lọwọ rẹ pe se o setan lati san owo ori naa.

Nigba to n fesi, Imisi ni eeyan to maa n bọwọ fun ofin ni oun.

"Mo maa n bọwọ fun ofin ni mo jẹ, bi ofin ba sọ pe maa san owo ori naa, maa kuku san-an."

Imisioluwa Ayanwale wa rọ awọn ọdọ, akẹẹgbẹ rẹ, pe ki wọn sisẹ, ki wọn si maa gbadura.

"Ti wọn ba n sisẹ, ki wọn maa gbadura, ti wọn ba si n gbadura, ki wọn mase dawọ isẹ duro."