Ìfẹ́ àwọn ọ̀dọ́ Gen-Z tó ń ṣe ìwọ̀de ṣẹ, bí ológun ṣe gba ìjọba ní Madagascar lẹ́yìn tí ààrẹ jápa

Iléeṣẹ́ ológun ní orílẹ̀ èdè Madagascar ti kéde pé àwọn ti gba ìjọba orílẹ̀ èdè náà kúrò lọ́wọ́ ààrẹ Andry Rajoelina.
Ọ̀gágun Michael Randrianirina, olórí àwọn ológun CAPSAT nínú ìkéde kan tó ṣe lórí rédíò sọ pé àwọn ti gba ìjọba orílẹ̀ èdè náà.
Ṣáájú ni ikọ̀ ológun CAPSAT, tó jẹ́ ológun tó ń ṣọ́ Ààrẹ Andry Rajoelina, lópin ọ̀sẹ̀ darapọ̀ mọ́ àwọn olùwọ́de tí wọ́n ń pè fún pé kí ààrẹ náà kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀.
Ọ̀gágun Michael Randrianirina àtàwọn olórí ikọ̀ ológun CAPSAT míì dúró síwájú ilé ààrẹ láti kéde pé àwọn ti gba ìjọba.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n sọ pé àwọn máa gbé ìgbìmọ̀ kan dìde tí yóò jẹ́ èyí tí àwọn ológun àtàwọn ọlọ́pàá yóò wà níbẹ̀ tó sì jẹ́ pé àwọn ni yóò máa ṣe àkóso orílẹ̀ èdè náà fún ìgbà kan ná.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Iléeṣẹ́ ìròyìn AFP sọ pé ọ̀gágun Randrianirina ní ìgbìmọ̀ náà máa ní àwọn aráàlú gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ fún ìgbà kan ná.
Wọ́n ní àwọn máa ṣètò bí ìjọba ṣe máa padà sọ́wọ́ ìjọba alágbádá láìpẹ́.
Bákan náà ni wọ́n ṣe ìdádúró àwọn iléeṣẹ́ lábẹ́ ìjọba alágbádá tó fi mọ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, ilé ẹjọ́ àti àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò orílẹ̀ èdè náà àyàfi ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin tó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ yíyọ ààrẹ Rajoelina nípò.
Ikọ̀ ológun CAPSAT tí wọ́n gba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Rajoelina wà lára àwọn tó ṣe ìrànwọ́ fún-un láti di ààrẹ Madagascar.
Ní ọdún 2009, CAPSAT ṣe àtìlẹyìn fún Rajoelina nígbà tó gba ìjọba lọ́wọ́ ààrẹ tó wà nípò nígbà náà, Marc Ravalomanana.
"A máa ṣe àgbékalẹ̀ ìjọba tuntun," Ọ̀gágun Randrianirina sọ fún àwọn akọ̀ròyìn.
Ó ní àwọn máa ṣètò ìdìbò láàárín ọdún kan àbọ̀ sí ọdún méjì sí àsìkò yìí.
Ọ̀gágun náà ìbéèrè àwọn ọ̀dọ́ Gen Z tó ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn jẹ́ ohun tí wọ́n yóò mú gbọ́.
Ó fi kun pé òun àtàwọn ọ̀gágun yòókù pinnu láti gba ìjọba láti mú àtúnṣe bá orílẹ̀ èdè.
"Kò sí ààrẹ, kò sí ìjọba… kò sí ohun tó ń ṣiṣẹ́ níbí."
Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé sọ pé ilé ẹjọ́ fi fìdí ìjọba Ọ̀gágun Randrianirina múlẹ̀, tí wọ́n sì kéde ipò ààrẹ àti ààrẹ ilé aṣòfin àgbà bí èyí tó ṣófo.
Ṣáájú ni ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ti bẹ̀rẹ̀ ìbò láti yọ Ààrẹ Rajoelina nípò fẹ́sùn pé ó fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, sá kúrò ní orílẹ̀ èdè náà.
Àwọn ológun bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de káàkiri ìlú

Oríṣun àwòrán, EPA

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Lẹ́yìn tí Ọ̀gágun Randrianirina kéde gbígba ìjọba ni àwọn ológun bẹ̀rẹ̀ sí ní yíde káàkiri olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, Antananarivo.
Níṣe ni àwọn aráàlú tó sí ojú pópó, tí wọ́n ń dunnú, tí wọ́n sì ń juwọ́ sáwọn ológun ọ̀hún bí wọ́n ṣe ń kọjá.
Láti ọjọ́ Ajé ni àwọn aráàlú Antananarivo ti ń fi ìdùnnú hàn bí wọ́n ṣe ti ń gbọ́ fìnfìn pé ó ṣeéṣe kí ìjọba orílẹ̀ èdè náà yí padà àti pé bí wọ́n kò ṣe gbọ́ ohunkóhun láti iléeṣẹ́ ààrẹ.
Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, Ààrẹ Rajoelina kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí pé wọ́n ti gba ìjọba lọ́wọ́ rẹ̀.
Bákan náà ni ẹnikẹ́ni kò le sọ pé ibi báyìí pàtó ló wà àmọ́ tó ní òun wà níbi tí ààbò ti wà fún ẹ̀mí òun nítorí àwọn kan ń dúnkokò mọ́ ẹ̀mí òun.
Àwọn ìròyìn kan tí BBC kò le fìdí rẹ̀ múlẹ̀ sọ pé France ti fi ọkọ̀ òfurufú gbé ààrẹ Rajoelina kúrò ní Madagascar.















