Ààrẹ fún ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀èdè tó kúsẹ̀ẹ́ jùlọ ní àgbáyé jápa torí àwọn tó fẹ́ pa á

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Natasha Booty
- Author, Sammy Awami
- Role, BBC Africa
- Reporting from, Antananarivo
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ọgbọọgbọ́n ni agbalagba fi n sa fun maaluu ni ohun ti Aarẹ Andry Rajoelina, fi ọrọ ara rẹ ṣe pẹlu bo ṣe yẹba kuro lorilẹede rẹ, lẹyin to ni awọn kan fẹ pa oun.
Aarẹ orilẹede Madagascar ni Andry Rajoelina.
Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni awọn araalu Madagascar, paapaa awọn ọdọ, fi ẹhonu han, ti wọn ni awọn ko fẹ Rajoelina nipo aarẹ mọ.
Ninu ọrọ ti Aarẹ Rajoelina, ẹni ọdun mọkanlelaadọta (51) ba awọn araalu rẹ sọ loju opo Facebook lọjọ Aje ana, lo ti ni oun wa nibi aabo, ṣugbọn ko sọ ibẹ pato.
"O di dandan fun mi lati wa aaye ti aabo wa fun ẹmi mi.
" Lati ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Kẹsan-an ni awọn ologun ati oloṣelu kan ti n gbiyanju lati pa mi, wọn si tun n fẹ ditẹ gbajọba mi.
"Ọna kan ṣoṣo naa lo wa lati yanju ọrọ yii; eyi naa si ni lati tẹle ohun ti ofin sọ".
Aarẹ naa lo sọ bẹẹ.
O pe ki Rajoelina to le sọrọ rẹ naa lori ayelujara, pẹlu bi awọn ologun ṣe leri lati gba olu ileeṣẹ tẹlifiṣan naa to wa ni Ocean Island.
Iroyin kan ti a ko le fidi ẹ mulẹ, sọ pe Rajoelina ti sa kuro ni Madagascar patapata, ati pe baaluu ilẹ Faranse kan lo ba japa.
Lati Ọjọru ọsẹ to kọja ni ẹnikẹni ko ti gburoo aarẹ naa mọ.
Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?
Ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni awọn ọdọ ṣewọde ni Madagascar, "Gen Z Mada" ni wọn pe e, wọn si n pe fun ifiposilẹ Raejoelina ni.
Ai le pẹtu si awọn ọdọ naa lọkan lo mu ko le awọn igbimọ ijọba rẹ danu nipo, o si gbe awọn igbesẹ miran ti ko pada mu esi kankan jade.
Ọdun 2009 ni ikọ ologun alagbara kan, CAPSAT, gbe Rajoelina depo, ṣugbọn lọsẹ to kọja ni wọn pada lẹyin rẹ, wọn ni awọn ni olori ijọba.
Koda, awọn kan ninu awọn CAPSAT yii darapọ mọ awọn araalu to n ṣe iwọde naa, iyẹn ni olu ilu naa, Antananarivo.
Olori ogun CAPSAT, Demosthene Pikulas, fi da awọn araalu loju pe ologun n ṣiṣẹ lati ri i pe alaafia jọba ni Madagascar.
Olori ijọba alatako kan to ni ka fi orukọ bo oun laṣiri, sọ fun BBC pe awọn ologun lo n dari Madagascar bayii.
Bakan naa ni ẹgbẹ alatako TIM party naa ti ni awọn ṣetan lati gbe igbesẹ iyọkuro nipo fun Rajoelina, fun bo ṣe kuro lọfiisi lojiji.
Pupọ ninu awọn eeyan to ba Rajoelina ṣe lo ti sa lọ si ilu to sun mọ wọn ti i ṣe Mauritius.
Lara wọn ni Olootu ijọba tẹlẹ, Richard Ravalomanana ati olokoowo; Maminiaina Ravatomanga.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Ọkan lára àwọn orílẹ̀èdè tó kúṣẹ́ jù lágbàáyé ni Madagascar, pẹ̀lú bó ṣe ní nǹkan àlùmọ́nì púpọ̀ tó
Gẹgẹ bi akọsilẹ Banki Agbaye (World Bank), orilẹede Madagascar yii wa lara awọn ibi ti ìṣẹ́ n ṣẹ́ ju laye, bo tilẹ jẹ pe wọn ni nnkan alumọni rẹpẹtẹ.
Ida marundinlọgọrin (75%) awọn eeyan to n gbe nibẹ bayii ni wọn jẹ akuṣẹẹ bi Banki Agbaye ṣe wi.
Bakan naa ni akọsilẹ International Monetary Fund (IMF) Ajọ Ayanilowo Agbaye, sọ pe ida kan ninu mẹta eeyan Madagascar lo ni anfaani si ina mọnamọna.
Eyi wa lara idi ti awọn olufẹhonu han ṣe wọde laipẹ, wọn binu si ai si ina ati omi.
Wọn koro oju si ijọba Rajoelina ti ko pese iṣẹ, ti ajẹbanu pọ fun, ti igbesi aye si nira bii oju ẹja.
O kere tan, eeyan mejilelogun (22) ni wọn ku ninu iwọde to waye kọja ni Madagascar, eeyan to le ni ọgọrun-un kan (100) lo si farapa gẹgẹ bi ajọ Iṣọkan Agbaye (UN) ṣe sọ.
Lati 1960 ti Madagascar ti gba ominira ni aibalẹ ọkan ti wa nibẹ, ọdun 2009 si ni iwọde alagbara kan waye, eyi to le aarẹ igba naa, Marc Ravalomanana lọ, ti Rajoelina si gba ipo lọwọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (34) pere ni Rajoelina nigba naa, oun si ni aarẹ to kere ju nilẹ Africa nigba yẹn.
O ṣejọba naa fun ọdun mẹrin, o si tun pada sipo ni 2018.
Ọmọ ọlọla ni Rajoelina lati ibẹrẹ aye rẹ ko too darapọ mọ oṣelu, oniṣowo ni pẹlu, bẹẹ lo si tun maa n ṣe oloootu orin ti a mọ si DJ.
Ṣugbọn ko sẹni to fẹ ri oju Rajoelina ni Madagascar lasiko yii mọ, wọn ni ooru rẹ n mu awọn.














