Kókó pàtàkì nípa ìtàn ayé Uma Ukpai, ajíhìnrere tí ikú rẹ̀ ń jà ràìnràìn lórí ayélujára

Uma Ukpai wọ aṣọ funfun, mú gbohùngbohùn dání

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àwọn ẹbí gbajúmọ̀ ajíyìnrere, tó tún jẹ́ olùdásílẹ̀ ìjọ Uma Ukpai Evangelistic Association, Dókítà Uma Ukpai ti kéde ikú rẹ̀.

Ẹbí olóògbé náà nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹwàá ọdún 2025 sọ pé ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹwàá ni àgbà ajíyìnrere náà ti jáde láyé.

Ẹni ọgọ́rin ọdún ni ajíyìnrere náà fi ayé sílẹ̀.

Wọ́n ní inú àwọn dùn fún ìgbé ayé olóògbé náà gbé àti pé o lé ní ọgọ́ta ọdún tó fi ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run, tí àwọn sì ní ìgbàgbọ́ pé ó ń sinmi báyìí.

Àmọ́ wọn kò ì tíì sọ bí ètò ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe lọ.

Àtẹ̀jáde náà sọ pé "ó fi ohun tó lé ní ọgọ́ta ọdún nínú ayé rẹ̀ jíyìn rere fún Ọlọ́run, kọ́ àwọn èèyàn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ní ipa rere nínú ayé ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn, tó sì mú àyípadà rere bá ìgbé ayé àwọn èèyàn ní Nàìjíríà àti lókè òkun.

Ìtàn ayé Dókítà Uma Ukpai

Ní ọjọ́ Keje, oṣù Kìíní, ọdún 1945 ni wọ́n bí Dókítà Uma Ukpai ní ìpínlẹ̀ Abia.

Nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá ló pàdánù bàbá rẹ̀.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ìbẹ̀rẹ̀ 1970 ló ṣe ìdásílẹ̀ ìjọ Uma Ukpai Evangelistic Association èyí tí oríkò rẹ̀ wà ní ìlú Uyo, ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.

Ó wà lára àwọn tó ṣe ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ Pentecostal Fellowship of Nigeria, PFN pẹ̀lú àwọn míì bíi Bíṣọ́ọ̀bù Ben Idahosa, Pásítọ̀ Enoch Adeboye àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìròyìn sọ pé ìṣọ́ òru kan tó ṣe tí wọ́n pè ní Greater Lagos for Christ Crusade lọ́dún 1985 ló bí ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ Pentecostal Fellowship of Nigeria.

Dókítà Ukpai kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ẹ̀kọ́ School of Journalism and Television, Frisham, Hermitage, United Kingdom.

Bákan náà ló lọ sí ilé ẹ̀kọ́ South Florida Christian College ní Amẹ́ríkà àti ilé ẹ̀kọ́ Carolina Christian University pẹ̀lú Burke Bible College, Kentucky.

Ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí ló ti gba ìwé ẹ̀rí nípa ìmọ̀ ìkọ̀ròyìn, onímọ̀ ẹ̀rọ nípa iná mọ̀nàmọ́ná àti oyè ọ̀mọ̀wé.

Ajíyìnrere náà pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ méjì ní ọjọ́ kan náà, tó sì máa ń fi ṣe ìwàásù.

Ọ̀pọ̀ àwọn ìyìnrere ni wọ́n ṣe káàkiri Nàìjíríà tó fi mọ́ ti ọlọ́dọọdún Greater Ohafia For Christ Crusade, Anioma One-Million Man Crusade àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alága ẹ̀ka tó ń ṣe ìtọ́jú ojú ní ilé ìwòsàn King of Kings Hospital tó wà ní ìpínlẹ̀ Abia.

Ó fẹ́ ìyàwó rẹ̀, Philomena Ukpai lọ́dún 1975, tí wọ́n sì bí ọmọ mẹ́jọ, gba ọmọ kan tọ́ si.

Níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe ló ti sọ nípa obìnrin nínú ìgbé ayé ọkùnrin. Ó ní tí èèyàn bá ti fẹ́ ìyàwó tó dára, ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ṣe é ṣe fún ọkùnrin.

Ní oṣù Kọkànlá, ọdún 2008, ọ ṣe ìfilọ́lẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì Uma Ukpai School of Theology.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lójú ìtàkùn ayélujára ilé ẹ̀kọ́ náà, àwọn pásítọ̀ àtàwọn ọ̀dọ́ yóò máa kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀. Àfojúsùn ilé ẹ̀kọ́ náà ni láti máa kọ ẹ̀kọ́ bíbélì àti ìṣòwò, tó fi mọ́ iṣẹ́ ọwọ́.