Bí ikọ̀ Hamas ṣe tú ogún sílẹ̀ nínú ọmọ Israel tó wà nigbèkùn wọn, ẹ wo àkójọ̀pọ̀ èèyàn 48 tó wà nígbèkùn, àwọn tó ti kú, àwọn tí wọn kò gbúròó wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn eeyan ogun (20) to wa nigbekun ogun Hamas ti gba itusilẹ bayii.
Meje ninu wọn ni wọn kọkọ kede ominira wọn laaarọ oni, ki iroyin to n tẹ wa lọwọ to sọ pe, wọn ti fi awọn mẹtala yoku silẹ ninu awọn ogun eeyan to wa nigbekun naa.
Apapọ awọn eeyan to ti gba itusilẹ naa si jẹ ogun (20) bayii.
Guusu ilẹ Israel ni wọn yoo ti darapọ mọ awọn ẹbi wọn.
Nibẹ naa ni wọn yoo ti kọkọ ṣe ayẹwo ara fun won, ki wọn to darapọ mọ awọn ẹbi to waa ki wọn kaabọ.
Orukọ awọn meje akọkọ ti Israel fi lede lowurọ ọni ni:
Eitan Mor
Gali Berman
Ziv Berman
Omri Miran
Alon Ohel
Guy Gilboa-Dalal
Matan Angrest.
Awon to wa nigbekun Hamas lo ku ti wọn yoo gbe kalẹ.
Awọn ẹlẹwọn Palestine ti wọn ju 1,700 lati Gaza, naa yoo gba itusilẹ.
Bakan naa ni awọn ileewosan Gaza ti n gbaradi lati bẹrẹ iṣẹ pada.
Ààrẹ Donald Trump yoo gba àmì ẹ̀yẹ tó ga jùlọ ni Israel
Lori aṣeyọri yii, Aarẹ orilẹede America,Donald Trump, ni wọn ti ni yoo gba ami ẹyẹ to ga julọ ni Israel bayii.
Ọfiisi Aarẹ Israel, Isaac Herzog lo fidi eyi mulẹ.
Ami ẹyẹ ọhun ni wọn fẹẹ fi mọriri igbiyanju Trump lati ri i pe eeyan mejidinlogoji to wa ni igbekun Hamas, gba itusilẹ.
Ogun (20) ninu awọn eeyan yii ni igbagbọ wa pe wọn ṣi wa laye.
Ni nnkan bii oṣu to n bọ ni wọn yoo fi ami ẹyẹ naa da Trump lọla bi wọn ṣe wi.
Ṣaaju ni Trump naa ti balẹ si Israel, to si tun ni oun yoo nifẹẹ lati lọ si Gaza pẹlu.
Nigba to n dahun ibeere pe ṣe yoo fẹ lati yọju si Gaza naa, Trump dahun pe yoo wu oun lati lọ.
"Mo mọ bi ibi ṣe ri gan-an lai tiẹ debẹ, mo maa fẹ lati lọ sibẹ, mo maa fẹ lati fi ẹsẹ mi tẹ ibẹ."
Àwọn wo ni ọmọ Israeli 48 ti Hamas yoo tu silẹ?


Oríṣun àwòrán, The Hostage and missing families forum
Àwọn tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n ṣì wà láyé
Ariel Cunio: Ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) ti wọn ji gbe ni Kibbutz Nir Oz lọjọ ikọlu naa.
David Cunio: Ẹni ọdun marundinlogoji ni (35), iyekan Ariel ti wọn jọ ji wọn gbe papọ ni.
Gali ati Ziv Berman: Tọkọ-taya ni awọn wọnyi, wọn ji wọn gbe ni Kibbutz Kfar Aza, pẹlu alajọgbele wọn torukọ tiẹ n jẹ Emily Damari.
Angrest Women: Ẹni ọdun mejilelogun ni, ṣọja ọmọ orilẹede Israeli si ni pẹlu, wọn ji gbe lọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2023 .
Awọn ẹbi rẹ sọ pe awọn gbọ pe o ṣi wa laye, ṣugbọn ikọ seemi-seemi (Asthma) n ba a ja, o si ni awọn egbo kan lara.
Zangauker: Wọn mu un lọ si Nir Oz pẹlu iyawo rẹ, Ilana Gritzewsky. Wọn fi Ilana silẹ loṣu Kọkanla ọdun 2023 ninu adehun ogun pari.
Eitan Horn: Ẹni ọdun mejidinlogoji (38) ,ọmọ orilẹede Argentina, ṣugbọn to n gbe ni Israel, wọn gbe oun ati aburo rẹ , Yair in Nir Oz.
Nimrod Cohen: Ṣọja ẹni ọdun mọkanlelogun ti Hamas mu lasiko ikọlu Nahal Oz attack.
Omri Miran: .Loṣu Kẹrin ọdun yii ni Hamas fi fidio ibi to ti n ṣajọyọ ọjọ ibi rẹ sita.
Guy Gilboa-Dalal: Ẹni ọdun merinlelogun (24) ti wọn ji gbe nibi to ti n ṣajọyọ ọdun Nova pẹlu ẹgbọn rẹ .
Alon Ohel : Ẹni ọdun 24 yii ṣi wa laye, awọn eeyan ri I ninu ọkọ Hamas ni Gaza loṣu Kẹjọ.
Yosef-Chaim Ohana , ibi ayẹye Nova ni wọn ti ji oun naa gbe.
Elkana Bohbot , ẹni ọdun 36, wọn gbe e nibi ayẹyẹ Nova.
Israel sọ pe o ṣi wa laye, ṣugbọn ikọ seemi-seemi to lagbara n yọ ọ lẹnu.
Avinatan Or: ẹni ọdun 32, wọn ji I gbe pẹlu ọrẹbinrin rẹ ,Noa Argamani.Awọn Israeli ri ọrẹbinrin gba pada pẹlu awọn mẹta mi-in loṣu Kẹfa ọdun 2024, ṣugbọn ni oṣu Kẹta, 2025, awọn ẹbi Or sọ pe awọn gbọ pe o ṣi wa laye.
Eitan Mor
Maxim Herkin: O han ninu fidio kan ti Hamas fi sita loṣu Kẹta.
Bar Kupershtein : O han ninu fidio kan ti Hamas fi sita loṣu Kẹrin.
Segev Kalfon
Evyatar David
Rom Braslabski
Àwọn tí ẹnikẹ́ni kò gbúróò wọn
Tamir Nimrodi , ẹni ọgun ọdun , ologun Israeli .
Bipin Joshi, ẹni ọdun 24.Oṣu Kọkanla ọdun 2023 ni wọn ti ri i gbẹyin.
Àwọn tó ti kú
Tamir Adar : Ninu ikọlu ọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2023 naa ni Hamas ti gbe oku rẹ.
Sonthaya Akrasri :,wọn pa a ni Kibbutz Be'eri. Ọmọ Thailand ni. Minisita ilẹ okeere fun Thailand, sọ pe oku rẹ ṣi wa lọdọ awọn Hamas.
Muhammad al-Atarash: Ẹni ọdun 39 ni, ṣọja ni, wọn fidi iku rẹ mulẹ ni Nahal Oz lọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ṣugbọn wọn ko ri oku rẹ.
Sahar Baruch: ẹni ọdun 24, ọmọ Palestine. Wọn ji i gbe, ṣugbọn Israel sọ pe wọn pa a lasiko ti awọn fẹ gba a silẹ ni Gaza.
Uriel Baruch: Wọn sọ fun ẹbi rẹ pe o ti ku si Gaza.
Inbar Hayman: ẹni ọdun 27, awọn ẹbi rẹ sọ pe wọn ti pa a si Gaza.
Itay Chen: Ẹni ọdun 19, ṣọja. Wọn fidi iku rẹ mulẹ lọjọ ikọlu naa. Ikọ ologun IDF ṣọ pe wọn pa a ni Nahal Oz, ṣugbọn Hamas lo gbe oku rẹ lọ.
Amiram Cooper: Ẹni ọdun 85 ni, wọn ni wọn pa a loṣu Kẹfa ọdun 2024, lẹyin ti wón ji i gbe.
Oz Daniel: Ẹni ọdun 19 to jẹ ṣọja, ku ninu ogun to waye pẹlu Hamas lọjọ ikọlu naa, wọn gbe oku rẹ lọ.
Ronen Engel: Ẹni ọdun 54,ku si igbekun Hamas bi IDF ṣe kede.
Meny Godard: Wọn pa a ni Be'eri pẹlu iyawo rẹ, Ayelet, wọn gbe oku rẹ lọ si Gaza.
Ran Gvili: Ẹni ọdun 24, ọlọpaa ọmọ Israeli, ku lọjọ ikọlu naa ni Kibbutz Alumim, Hamas gbe oku rẹ lọ si Gaza.
Tal Haimi: Ẹni ọdun 41,wọn pa a lọjọ ikọlu, gbe oku rẹ lọ si Gaza.
Asaf Hamami: Ologun ti wọn pa nitosi Kibbutz Nirim, Hamas gbe oku rẹ lọ.
Guy Illouz: Wọn yinbọn fun un nibi ayẹyẹ, awọn ẹbi rẹ sọ pe ọdọ awọn Hamas lo ku si, ni Gaza.
Eitan Levi : Awakọ taxi ti wọn yinbọn fun lọjọ ikọlu, Hamas gbe oku rẹ lọ.
Eliyahu Margalit : Hamas pa a ni Nir Oz lọjọ ikọlu.
Joshua Mollel: Ẹni ọdun 21, ọmọ orilẹede Tanzania.
Ijọba ilu rẹ fidi iku akẹkọọ yii mulẹ, wọn ni oku rẹ wa lọdọ awọn Hamas.
Omer Neutra: Ṣọja Israeli ti Hamas pa lẹnu ibode. Wọn ni Hamas lo gbe oku rẹ lọ.
Daniel Peretz: Ọmọ orilẹede South Africa, ṣọja ni. Wọn kọlu u nitosi Nahal Oz, ṣugbọn wọn gbe oku rẹ lọ si Gaza.
Dror Or: Wọn pa a pẹlu iyawo rẹ Yonat. Wọn ko awọn ọmọ rẹ meji; Noam ati Alma lọ. Wọn fi awọn omọ naa silẹ loṣu Kọkanla ọdun 2023, ṣugbọn oku Dror wa lọwọ Hamas.
Suthisak Rintalak: Ẹni odun 43, agbẹ ọmọ orilẹede Thai. Wọn ni oku rẹ wa lọwọ Hamas.
Lior Rudaeff: Ẹni ọdun 61, wọn pa a nibi ikọlu, gbe oku rẹ lọ si Gaza.
Yossi Sharabi: Wọn kede iku re ni oṣu akọkọ ọdun 2024, oku rẹ wa ni Gaza.
Arie Zalmanowicz: Ẹni ọdun 85 ti wọn ji gbe ni Nir Oz lọjọ ikọlu, Hamas kọkọ fi fidio kan sita to kede pe o rẹ baba naa, oṣu kan leyin eyi ni wọn kede iku rẹ.
Hadar Goldin: Ẹni ọdun 23, ṣọja, wọn pa a ni Gaza ni 2014, ṣugbọn akata Hamas ni oku rẹ wa latigba naa.














