Agbébọn kọlu àwọn fijilanté ní Zamfara, èèyàn mẹ́jọ kú, ọ̀pọ̀ farapa yánayàna

Awọn agbebọn ti wọn fi aṣọ bo oju pẹlu igbọn Ak47 lọwọ wọn

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan, fijilante mẹjọ lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti awọn agbebọn dena de wọn nipinlẹ Zamfara.

Ikọlu yii lo jẹ ọkan lara awọn ikọlu lemọlemọ to n waye nipinlẹ naa lẹnu lọọlọ yii lati ọwọ awọn agbesunmọmi ti ijọba n pe ni janduku.

Ọlọpaa Zamfara fidi rẹ mulẹ pe awọn to ku lo wa ninu ikọ agbarijọpọ ẹṣọ alaabo 'Civilian Joint Task Force' ti wọn jẹ ara awọn fijilante to n ṣeranwọ fun ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria atawọn ọlọpaa nibẹ.

Iroyin ni abule Yan Doto ni wọn ti n ṣiṣẹ ki wọn to gba ipe kan pe awọn agbebọn naa fẹ kọlu abule ọhun.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn araalu ọhun sọ, awọn fijilante naa koju awọn agbebọn naa ni nnkan bii aago mọkanla ale.

Amọ awọn agbebọn naa pọju awọn fijilante ọhun lọ, ti wọn si bori wọn lasiko ti wọn kọju ibọn si ara wọn.

Mẹjọ ninu awọn fijilante naa padanu ẹmi wọn nigba ti ọpọ awọn mii farapa yanayana.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Yazid Abubakar, sọ fun BBC pe awọn ti lọ ko oku awọn to padanu ẹmi wọn, awọn ọmọ ogun si ti n tọpinpin ibi ti awọn agbesunmọmi naa wọ lọ.

Yan Doto, to jẹ abule ti awọn Musulumi pọ si, to si wa ni aala ipinlẹ Katsina ni ikọlu awọn agbebọn ti n waye lemọlemọ laarin ọsẹ diẹ si asiko yii.

Lọsẹ meji sẹyin, awọn agbebọn ya bo ilu naa lasiko irun idaji nibi ti wọn ti ṣekupa eeyan mẹrin – ti imaamu kan wa lara wọn – ti wọn si tun ji eeyan meje mii gbe lọ.

Ipinlẹ Zamfara jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ ti awọn agbebọn kọlu julọ ni Ariwa Naijiria nibi ti wọn ti n kọlu awọn abule, ti wọn si n ji awọn eeyan ati dukia lọ.

Bo tilẹ jẹ pe ikọ ileeṣe ọmọ ogun Naijiria wa nibẹ lati koju wọn, amọ ọpọ igba lawọn agbebọn naa maa n ṣe aṣeyọri ninu iṣe laabi ti wọn n ṣe nibẹ.

Ijọba ni oun n gbiyanju lati rẹyin awọn agbebọn naa ṣugbọn awọn eeyan agbegbe naa ni awọn ko tii ri aṣeyọri ijọba lati ṣẹgun awọn agbebọn ọhun.