Àlàyé rèé lórí iṣẹ́ tó wà níwájú alága INEC tuntun, Ọ̀jọ̀gbọ́n Joash Amupitan

Oríṣun àwòrán, Others
Bi Ọjọbọn Mahmood Yakubu ṣe n kuro nipo Alaga ajọ eleto idibo Naijiria ni ipari oṣu to n bọ, eto ijọba awarawa Naijiria yoo bọ ṣabẹ isakoso tuntun ti Ọjọgbọn Ojo Amupitan, alaga INEC tuntun.
Yatọ si pe Amupitan yoo jogun awọn iṣẹ akanṣe ti Yabuku, yoo tun jogun awọn kudiẹkudiẹ to wa lasiko saa rẹ.
Iṣẹ Amupitan ko pin ni ṣiṣe amojuto eto idibo nikan, ṣugbọn dida igbagbọ nini ninu ajọ INEC pada sọkan araalu.
Aisha Abdullahi, ajafẹtọ awọn ọdọ niluu Kano ni "A ko nilo oludari ere, a nilo eeyan ti a le fọkan tan. Ki n ṣe bi a ṣe n dibo lo n dun wa ṣugbọn ki esi idibo ma parẹ nibi tie to idibo ti n waye n dojutini."
Ifilọlẹ imọ ẹrọ Bimodal Voter Accreditation System (BVAS) ati INEC Result Viewing Portal (IReV) figba kan fi ireti sọkan araalu ṣugbọn lọdun 2023, imọ ẹrọ yii ja ọpọ araalu lulẹ nigba to bẹrẹ si ni ma ṣe segesege.
"Imọ ẹrọ ko lo n igbagbọ wa, eeyan lo ma n mu igbagbọ wa," Ezenwa Nwagwu ṣalaye.
"Alaga INEC tuntun gbọdọ ni oye pe ki n ṣe nipa mọ ẹrọ nikan, ṣugbọn nipa fifi ara han awọn araalu."
Ki lo waye ni ọdun 2023?
Ọpọ awọn araalu ati ẹgbẹ oṣelu lo kọ esi idibo ọdun 2023, ti wọn si fẹsun ajọ INEC pe wọn lọwọ ninu bi ẹrọ BVAS ati IREV se taku lasiko ibo.
Ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko naa pe fun ki alaga ajọ eleto idibo INEC ni Naijiria, Mahmood Yakubu kọ iwe fi ipo silẹ ni kiakia.
Eyi ko ṣẹyin bi PDP ṣe fi idirẹmi ninu idibo sipo aarẹ to waye ni Naijiria ni Ọjọ Karundinlọgbọn, Oṣu Keji, ọdun 2023.
Akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP, Debo Ologunagba lasiko ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ ni ilu Abuja ni esi idibo sipo aarẹ fihan pe ọpọlọpọ magomago lo waye lati rii pe oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu lo wọle ninu idibo naa.
Koda, awọn oludije ẹgbẹ oṣelu to wa ni ipo keji ati ipo kẹta, Atiku Abubakar ati peter Obi sọ pe esi ibo naa ko tẹ awọn lọrun, wọn si morile ile ẹjọ.
Wọn ni awọn kudiẹkudiẹ kan waye lasiko eto idibo naa, paapaa nibi ti wọn ti n ko idibo ọhun jọ titi ti wọ fi kede ẹni to bori.
Tinubu lo ni iye ibo to pọ ju, eyii to le ni ida 25% ni ipinlẹ mọkandilọgbọn, eyii to mu ko bori, gẹgẹ bii alakalẹ ofin.
Ninu atẹjade ti INEC fi lede ni wọn ti ni ki PDP ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ lori ẹsun orisirisi ti wọn fi n kan adari ajọ naa.
Ajọ eleto idibo naa ni ko si ẹri to daju lati pe fun ki alaga Ajọ INEC naa kọ iwe fi ipo silẹ.
Nigba ti Obi ati Atiku bori ni ipinlẹ mejila-mejila, eyii to jẹ akọkọ iru rẹ ni Naijiria.
Ki ni awọn nnkan ti Alaga tuntun gbọdọ mojuto?
Eto idibo ni awọn ipinlẹ bii Anambra, Ekiti, Osun ni Alaga tuntun yoo kọkọ koju ṣaaju eto idibo gbogbo ni ọdun 2027.
Awọn omoye gbagbọ pe ohun akọkọ ti alaga tuntun fun INEC gbọdọ mojuto ni pe ko da igbagbọ ninu INEC pada si ọkan araalu.
Oṣiṣẹ INEC tẹlẹri, Ọjọgbọn Okey Ibeanu ni "INEC le ni BVAS, IReV, ati awọn nnkan mẹwaa ṣugbọn ti awọn to n dari INEC ko ṣe ohun to yẹ, gbogbo awọn nnkan yooku ko ni leto."
"Eeyan to ba jẹ alaga INEC gbọdọ jẹ eeyan to ni otitọ ọkan, ti ko si eeyan kan ti wọn le ko si inu rẹ. O gbọdọ ni oye lati koju awọn ipenije ti yoo la kọja", Austin Aigbe ṣalaye
Gomina Ahmed Usman Ododo ṣapejuwe Ọjọgbọn Amupitan bi ẹni to ṣee fọkan tan to si tun jẹ Ọmọluabi.
Gẹgẹ bi alakalẹ iwe ofin orilẹede Naijiria, ohun to kan bayii ni pe Aarẹ Tinubu yoo forukọ Ọjọgbọn Amupitan ranṣẹ sile igbimọ aṣofin agba l'Abuja fun ayẹwo














