"Ọdún 42 rèé tí mo ti ń fọ mọ́tò, eré ìdárayá la fi ń ṣe lọ́jọ́ ogbó"

Àkọlé fídíò, "Ọdún 42 rèé tí mo ti ń fọ mọ́tò, eré ìdárayá la fi ń ṣe lọ́jọ́ ogbó"
"Ọdún 42 rèé tí mo ti ń fọ mọ́tò, eré ìdárayá la fi ń ṣe lọ́jọ́ ogbó"

Yoruba ni idi isẹ ẹni, la ti n mọ ni ọlẹ, ẹni ti ojo ko pa, ti oorun ko si pa, o seese ko jẹ pe isẹ ni yoo pa a.

Bi ọrọ se ri ree pẹlu awọn baba arugbo kan ti ọjọ ori wọn wa laarin aadọrin si ọgọrin ọdun, ti wọn yan isẹ kan laayo lati maa se.

Isẹ ọkọ fifọ ni wọn yan laayo, eyi to nilo okun ati agbara lati se e.

Ki lo wa sun awọn baba arugbo yii de idi isẹ ọkọ fifọ, bawo ni wọn se n ri okun ati agbara lati sisẹ naa?

Ẹwẹ, ki lawọn anfaani ti wọn n ri nidi isẹ naa ati ipenija to wa nidi rẹ.

BBC bawọn baba to n fọ ọkọ naa sọrọ, ti wọn to mẹsan niye, alaye wọn lo wa ninu fidio oke yii.

Awọn baba arugbo mẹsan to n fọ mọto, ikọọkan wọn gbe ike ipọnmi lọwọ, wọn wọ oniruuru asọ ati sokoto penpe, ti wn si de fila bẹntigọọ sori.

"N ko le rin daadaa tẹlẹ, amọ lati igba ti mo ti n wa fọ mọto, ni ara mi ti le si."

Nigba ti wọn n ba BBC sọrọ, Emeka Oke, to jẹ ọkan lara awọn baba arugbo to n fọ ọkọ naa ni ẹni ọdun aadọrin ni oun, ti oun si ti n sisẹ ọkọ fifọ lati ọdun mejilelogoji sẹyin.

Gbogbo awọn baba to ti ni ọmọ-ọmọ yii si lo si gba pe awọn eeyan maa n bi awọn pe nibo ni awọn ti ri okun lati fọ mọto pẹlu ọjọ ori awọn.

Amọ wọn ni isẹ naa lo n mu ki okun awọn le si daadaa, ti awọn si dangajia.

Koda, ọkan ninu wọn sọ fun BBC pe "N ko le rin daadaa tẹlẹ, amọ lati igba ti mo ti n wa fọ mọto ni ara mi ti le si."

Bakan naa, wọn sọ fun BBC pe owo ti awọn n ri lati ara ọkọ fifọ yii ni awọn n lo lati fi tọju ara wọn ati ẹbi pẹlu.

Ọkan ninu awọn baba naa wọ asọ ati sokoto penpe alawọ eeru, o wọ bata rọba konko, to si n fi ọsẹ fọ mọto alawọ pupa kan.