Àlàyé rèé lórí bí ọkọ̀ tó sálọ ṣe pa Abiodun Aremu, aṣaájú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ẹni

Oríṣun àwòrán, Others
Ajafẹtọ ọmọniyan, Abiodun Aremu ti padanu ẹmi lẹyin tí ọkọ kan kọlu lasiko to fẹ sọda ní ilu Ota nipinlẹ Ogun.
Dẹrẹba ọkọ naa gba a Aremu lai duro lẹyin to kọlu u lasiko ti Aremu fẹ sọda titi to n lọ si ile.
Eto isinku rẹ ni o yẹ ko waye lọjọ Aje ṣugbọn ti ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ti sun si ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹwaa lati fi bu ọla ìkẹyìn fun.
Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?
Awọn Osojumikoro salaye pe iṣẹlẹ naa wáyé ní deede ago mẹfa ni ọjọ kọkanla oṣu kẹwaa ọdun 2025 nigba ti oloogbe naa ń lọ sí ile.
Awọn eeyan suure gbe oloogbe naa lọ si ile iwosan níbi tí awọn dokita ti saa ipa wọn lati doola ẹmi Aremu
Aremu kuro nibi to ti n ṣísẹ ni nnkan bii ago meje abọ, to si morile ile ni agbegbe Sango Ota, nipinlẹ Ogun State.
Ṣadede ni ọkọ yii gba Aremu, ti wọn si suure gbe lọ sí ile iwosan.
Ọkan ninu awọn eeyan olugbe agbegbe naa, Olugbenga Abdul Salam, Aremu jade laye ni ile iwosan ti wọn gbe lọ.
NLC pe fun iwadii lori iṣẹlẹ iku Aremu
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, NLC, Egbẹ awọn oṣiṣẹ ile epo, NUPENG ati ẹgbẹ awọn akẹkọọ, NANS ni wọn banujẹ lori Iku Aremu, tí wọn si sapajuewe iṣẹlẹ gẹgẹ bii eyi to gba omije loju.
Ninu atẹjade ti Aarẹ NLC, Joe Ajaero buwọlu fun awọn akorọyin, NLC bere fun iwadii lori Iku Aremu.
Ajaero sapejuwe Oloogbe gẹgẹ bii ọkùnrin takuntakun tí iṣẹlẹ iku rẹ jẹ ajalu nla fun orilẹede Naijiria.
"Comrade Aremu jẹ eeyan ńlá, to n lewaju ogun fun ilọsiwaju ẹgbẹ oṣiṣẹ.
"Gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ Labour Civil Society Coalition, LASCO, ati awọn ẹgbẹ yooku bii Joint Action Front, JAF, Aremu ko ipa nla ninu idagbasoke awọn ẹgbẹ fun ilọsiwaju awọn oṣiṣẹ Naijiria."
NUPENG ninu atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Ọmọọba Williams Akporehe ati akọwe ẹgbẹ, Afolabi Olawale buwọlu fun awọn akorọyin fi sapejuwe Oloogbe gẹgẹ olori to n wa ilọsiwaju fun ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ilọsiwaju orilẹede Naijiria.
Ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹede Naijiria, NANS, ẹka tí ipinlẹ Eko naa pẹlu awọn ẹgbẹ to tí kan sara si oloogbe.
NANS, ninu atẹjade ti wọn fi lede, sapejuwe oloogbe gẹgẹ bii olori to n ja fẹtọ awọn eeyan.

Oríṣun àwòrán, NLC
KI ni awọn ohun pataki ti Abiodun Aremu se nigba aye rẹ?
Comrade Abiodun Aremu to jẹ asaaju iran awọn osisẹ ni Naijiria lo se agbekalẹ ilana to tọjọ ninu ẹgbẹ osisẹ.
Igbesẹ naa ko si yọ awọn agbarijọpọ ẹgbẹ ajafẹtọẹni LASCO silẹ ati ajọ alaanu Kolagbodi silẹ.
Abiodun Aremu lo se idasilẹ ile ẹkọ nipa ero itẹsiwaju ti wọn n pe ni Amilcar Cabral Ideological School (ACIS-M).
Afojusun ile ẹkọ naa ni lati maa se ilanilọye ati irolagbara fawọn ọdọ, ki wọn lee jẹ ẹni ti yoo maa ja fun imupada nnkan rere si awujọ.
Bakan naa, Abiodun Aremu tun jẹ akọwe ẹgbẹ ajijagbara Nigeria Movement for the Liberation of Western Sahara ati ẹgbẹ Nigerian Movement of Solidarity with Cuba.
Oniruuru ami ẹyẹ ni wọn fi da Abiodun Aremu lọla fun awọn aayan rẹ to se yika agbaye.















