Àwọn ìdí rèé tí a ṣe fẹ́ kí ìbò wáyé lóṣù Kọkànlá ọdún 2026, dípò oṣù kejì ọdún 2027 - Ilé aṣòfin Naijiria

Aworan awọn obinrin meji to n dibo, awọn ike idibo naa wa niwaju wọn, bẹẹ ni awọn oludibo mi-in naa wa nibẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn obinrin meji to n dibo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lodi si ọdun mẹrin-mẹrin ti idibo apapọ maa n waye lorilẹede Naijiria, ile igbimọ aṣofin agba ti dabaa pe ki eyi to yẹ ko waye loṣu Keji ọdun 2027, waye ni oṣu kọkanla ọdun 2026.

Eyi yoo mu ki idibo naa waye ni oṣu mẹfa ṣiwaju asiko to yẹ ko waye ni 2027.

Alaga igbimọ to n ri si eto idibo nile igbimọ aṣofin agba Naijiria, Adebayo Balogun, sọ pe aba naa ti wọn da lọjọ Aje ana yii, nibi ipade igbimọ to n ri si idibo niluu Abuja, wa ni ibamu pẹlu iwe ofin (Amendment) ọdun 2025.

Ibo oṣu kọkanla yii ni yoo yi ilana ti Naijiria n lo tẹlẹ pada, iyẹn ti ofin idibo ọdun 2022, wọn yoo si gbe tuntun kalẹ fun 2025.

Kí ní ìdí èyí?

Gẹgẹ bi alaye ti wọn fi gbe aba naa lẹsẹ, wọn ni idibo si ọfiisi aarẹ ati awọn gomina gbọdọ waye nigba ti yoo ba fi ku ọjọ márùndínláàdọ́wàá (185), ti awọn to wa nipo naa yoo kuro nibẹ.

Idi keji ti wọn la kalẹ ni pe eyi yoo mu ki gbogbo ẹsun idibo ati ẹjọ to wa ni kootu lori ibo ti yanju pata ki idibo too waye.

" Aba ti a da yii wa lati jẹ ki gbogbo ẹsun lori idibo ti yanju pata ko too di ọjọ kọkandinlọgbọn,oṣu Karun-un ọdun 2027 ti ijọba tuntun yoo bẹrẹ.

Bẹẹ ni atẹjade to ṣalaye ilana naa wi.

Amọ, awọn aṣofin fi kun un pe ayipada yii nikan le ma to, bi ko ṣe pe ki kootu ṣetan lati yanju gbogbo ẹsun idibo ti wọn ba n gbọ lọwọ.

Awọn nnkan miran to rọ mọ aba idibo tuntun naa ni pe awọn to wa lẹwọn naa yoo ni anfaani lati dibo bii ẹtọ.

Awọn ọmọ Naijiria to wa loke okun naa yoo le tete ri ibo di, lilo NIN fun iforukọsilẹ ṣaaju idibo, didi ibo pẹlu imọ ẹrọ ati fifi ayelujara kede esi idibo.

'Káàdì ìdìbò alálòpẹ́ (PVC) lè má pọn dandan mọ́ lati máa lò fún ìdìbò'

Aworan kaadi idibo alalopẹ (PVC) ti wọn di jọ

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Aworan kaadi idibo alalopẹ (PVC)
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Yatọ si ọjọ idibo ti yoo ya kankan, awọn aṣofin tun dabaa pe kaadi idibo alalopẹ le ma pọn dandan fun oludibo lati ni mọ.

"Lilo kaadi idibo alalopẹ (PVC) le ma pọn dandan mọ, niwọn igba ti ẹrọ 'Bimodal Voter Accreditation System'(BVAS) ko ti da ohun to wa ninu rẹ (microchip) mọ."

Wọn fi kun un pe awọn oludibo to forukọ silẹ yoo le lo ẹrọ ayelujara lati tẹ kaadi wọn jade nigbakugba ti wọn ba fẹ lo o.

Eyi yoo tun gba agbara lọwọ awọn to ba n ra kaadi idibo lọwọ awọn eeyan bi awọn aṣofin ṣe wi.

Ojúṣe ẹgbẹ́ òṣèlú

Aba miran to tun waye ni pe awọn ẹgbẹ oṣelu naa yoo tẹle ojuṣe wọn nipa fifi orukọ awọn oludije wọn ranṣẹ ṣiwaju ọjọ idibo.

Bakan naa ni awọn oludije to ba yege ninu idibo abẹle nikan ni ofin yoo gba wọle.

Lati fi ofin gbe awọn atunto yii lẹsẹ, awọn aṣofin n gbe igbesẹ aba kan ti yoo yi ofin 1999 pada, eyi ti yoo fun wọn lagbara lati sọ asiko idibo labẹ ofin.

Bi aba yii ba di ofin, ajọ eleto idibo ilẹ wa (INEC), yoo ṣe atunto si ọna iṣẹ wọn, eyi ti yoo mu ki idibo orilẹede Naijiria bẹrẹ si i yá ju ti tẹlẹ lọ.

Orilẹede UK ṣetan lati ti Naijiria lẹyin

Lori aba yii, orilẹede United Kingdom, sọ pe oun ṣetan lati ti Naijiria lẹyin, nipa atunṣe ofin idibo ọdun 2022.

Olori ẹka idagbasoke ati ifọwọsowọpọ, Head of Development Cooperation, Foreign, Commonwealth and Development Office (FCDO), Cynthia Rowe, gboriyin fun Naijiria lori ọna lati mu idagbasoke ba ilana idibo rẹ.

Rowe sọ pe o dun mọ UK lati ti Naijiria lẹyin, lori igbiyanju rẹ lati gbe ijọba awaarawa ga.