Wo àwọn orílẹ̀èdè tó ṣeéṣe kí Super Eagles bá pàdé nínú 'Play Off' láti yege lọ sí ìdíje fún ife ẹ̀yẹ àgbáyé

Oríṣun àwòrán, NurPhoto via Getty Images
Ajọ ere bọọlu ni ilẹ Adulawọ CAF, ti jẹ kede ibi ti ifẹsẹwọnsẹ idije awọn ipo keji orilẹede ti wọn ko ni anfani lati lọ si idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni ọdun to n bọ.
Ninu atẹjade ti CAF fi lede, orilẹede Morocco, to n gba alejo idije ife ẹyẹ adulawọ ti ọdun 2025 naa ni yoo gba alejo idije Play Off yii laarin awọn orilẹede ilẹ Afrika.
Awọn orilẹede mẹrin ti wọn wa ni ipo keji ṣugbọn ni ọpọ ami ni wọn yoo ni anfani lati kopa ninu idije Play Off yii.
Ikọ Super Eagles orilẹede Naijiria yoo pẹlu awọn orilẹede yii bi wọn ṣe bori awọn akẹgbẹ wọn lati orilẹede Benin pẹlu ami ayo mẹrin si odo.
Victor Oshimen mi awọn ni igba mẹta ọtọọtọ, ti Frank Onyeka naa sig be ikọ Super Eagles wọ ipile Play Off fun idije ife eye agbaye.
Irinajo ikọ Super Eagles lati yege lọ si ididje fun ife ẹyẹ agbaye
Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ ikọ Super Eagles pẹlu Benin ni ilu Uyo laana, wọn yoo gbera lọ sinu idije Play Off nibi ti wọn ti ma wọ ija pẹlu orilẹede mẹrin mii lati ilẹ Adulawọ.
Awọn orilẹede mẹrin ti yoo kopa ninu Play Off yii ni Orilẹede Naijiria, Gabon, Cameroon ati Democratic Republic of Congo.
Inu oṣu kọkanla ni awọn ifẹsẹwọnsẹ yii ma waye ni orilẹede Morocco, ti Ikọ Super Eagles yoo si lọkitipọ pẹlu orilẹede Gabon, ẹni to to ba bori ni yoo ba orilẹede to ba bori laarin Cameroon ati DR Congo.
Orilẹede to ba bori idije Play Off yii ni yoo lọ soju ilẹ Afrika ninu idije Play Off miiran ti ajọ FIFA, ti yoo si ma pade awọn orilẹede miiran kaakiri agbaye lati tikẹẹti lọ si idije ife ẹyẹ agbaye ti ọdun to n bọ.
Awọn orilẹede to gba tikẹẹti fun idije ife ẹyẹ agbaye
Lẹyin ọpọ ifẹsẹwọnsẹ kaakiri fun awọn orilẹede lati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye, BBC News Yoruba ṣe akojọpọ awọn orilẹede to ti gba tikẹẹti lati le kopa.
Awọn orilẹede to n gba alejo: Canada, Mexico, United States
Ilẹ Asia: Australia, Iran, Japan, Jordan, Qatar, Saudi Arabia, South Korea, Uzbekistan
Ilẹ Africa: Algeria, Cape Verde, Egypt, Ghana, Ivory Coast, Morocco, Senegal, South Africa, Tunisia
Ilẹ Yoruupu: England















