Ọwọ́ ta a ló ti wá láàrin ọkọ àti ìyàwó, tí gbogbo ọmọ wọ́n bá jẹ́ obìnrin nìkan?
Ero Yoruba ni pe ọmọkunrin lo maa n gbe ile ro, ti ọmọbinrin ko si ni ojuse kankan to le se nile baba rẹ, ju pe ko dagba, ko gba ile ọkọ rẹ lọ.
Wọn gba pe Adekunle ni ọmọkunrin jẹ, ti ọmọbinrin si jẹ Adetule.
Ni ọpọ igba, ija, asọ ati awuyewuye alagbara lo maa n waye ninu awọn idile nitori pe wọn ko bi ọmọkunrin.
Nigba miran, irufẹ idile naa maa n daru, ti ọkọ yoo si na ẹsẹ sita lati wa obinrin miran ti yoo bi ọmọkunrin fun.
Iru ọkunrin bayi ati awọn ẹbi pẹlu ọrẹ rẹ si maa n di ẹbi le iyawo rẹ lori pe oun lo kuna lati fun ọkọ rẹ ni ọmọkunrin ti yoo gbe ile ro.
Ta lo wa ni ẹbi, bi idile kan ba bi kikida obinrin tabi ti ọmọbinrin pọ ju ọmọbinrin lọ?
Se iyawo ni tabi ọkọ?
Ọna lati wa idahun si ibeere yii lo mu ki BBC News Yoruba fi se iwadii sirufẹ isẹlẹ yii lati mọ ohun to n fa a, ti idile kan ko ba bi ọmọkunrin, ẹbi ta si ni?

Eroja XY to wa ninu atọ ọkunrin lo n sokunfa irufẹ ọmọ ti aya rẹ yoo bi, boya akọ ni tabi abo – Iwadii
Ninu iwadii BBC News Yoruba, a ri pe eroja pataki meji lo wa atọ ọkunrin nigba ti eroja ile ẹyin obinrin si ni eroja kan soso.
Awọn eroja naa ni X ati Y , ti oloyinbo n pe XY Chromosomes.
Awọn ọkunrin maa n ni eroja mejeeji ninu atọ, eyiun eroja X ati Y nigba ti obinrin maa n ni eroja X nikan.
Eroja Y yii to wa ninu atọ ọkunrin lo duro fun eroja to jẹ ti bibi ọmọkunrin amọ eroja X lo duro fun eroja to n jẹ ka bi ọmọbinrin.
Ti eroja X ninu atọ ọkunrin ba dapọ mọ eroja X to duro sinu ẹyin obinrin lati di oyun, awọn eroja mejeeji naa yoo darapọ di XX, a jẹ pe ọmọbinrin ni obinrin naa naa yoo fi oyun inu rẹ bi.
Amọ to ba jẹ pe eroja Y to wa ninu atọ ọkunrin lo dapọ mọ eroja X to wa ninu ẹyin obinrin, yoo wa di XY, a jẹ pe ọkunrin ni obinrin yoo fi oyun inu rẹ bi.
Eyi si fi han pe eroja to wa ninu atọ ọkunrin, to ba tu sinu ẹyin obinrin, ni yoo sọ irufẹ ọmọ ti wọn yoo bi, boya akọ ni tabi abo.
Sugbọn ohun to yẹ ka maa ranti ni pe gbogbo ni ọmọ. Ko si eyi ti ko dara ninu akọ ati abo, ki Ọlọrun sa ma se w ani agan lo ja ju.






