Òrìṣà Àńṣòògún-Ọ̀lálá: Jagunjagun Iresa-Adu tó bínú wọlẹ̀ pẹ̀lú ẹmẹ̀wà rẹ̀, ọba kìí dé ojúbọ rẹ̀, ó ń dáhùn àdúrà láàrin ọjọ́ méje
Ilu Ansoogun jẹ ilu kan to gbajumọ ni agbegbe Iresa-Adu to wa nilu Ogbomoso.
Amọ ilu naa gbajumọ gidi nitori orisa kan ti wọn n bọ ni ọdọọdun eyi ti wọn n pe ni Ansoogun-Ọlala.
Orisa Ansogun se pataki si ilu naa nitori wọn gbagbọ pe oun lo n daabo bo ilu naa.
Bakan naa, wọn gbagbọ pe ohunkohun ti eeyan ba beere lọwọ orisa Ansoogun, laarin ọjọ meje, yoo ri idahun si ibeere rẹ.
Amọ iyalẹnu ni pe Ọba ilu Ansoogun ko gbọdọ foju kan orisa naa.
BBC News Yoruba de ilu Ansoogun lati foju se mẹrin bi wọn se n bọ orisa naa lọdun yii.
A si sewadii nipa idi ti wọn se n bọ orisa Ansoogun, awọn ohun to n se fun ilu naa ati idi ti ọba ilu naa ko se gbọdọ de idi orisa ọhun.

"Idi ree ti Ansoogun-Ọlala se di wọlẹ, di orisa akunlẹbọ pẹlu awọn ẹmẹwa rẹ, ti iyawo rẹ si di omi"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, ọkan ninu awọn afọbajẹ, to tun jẹ Bara-Rẹ̀sà ti ilu Iresa-Adu, Oloye James Olawale ni Ọ̀lálá ni orukọ Ansoogun gangan.
Oloye Olawale wa sọ itan to rọ mọ orisa naa nigba aye rẹ ati pe igba to di orisa akunlẹbọ lo di pe awọn n bọ bii Ògún Ọ̀lálá ní ọdọọdun.
"Jagunjagun alagbara ni Ọlala, ko si si ogun ti yoo lọ, ti ko ni sẹgun rẹ.
Nigba naa, bi jagunjagun kan ba n ti oju ogun bọ, awọn ara ile rẹ yoo ko ilu ati ijo lọ pade wọn loju ọna.
Amọ nigba ti Ọlala n ti oju ogun bọ, dipo ki awọn eeyan pade rẹ tilu tifọn, ko ri ẹnikankan pade rẹ.
Idi ni pe ogun ti wọ ilu rẹ, awọn ẹbi rẹ ti ko yẹ ko ku, ti ku, ilu ti tu, iroyin naa si ba ninu jẹ, to si binu wọlẹ.
Iyawo rẹ gan pẹlu nalẹ, to si di omi, koda, awọn ẹmẹwa rẹ ti wọn dijọ n ti oju ogun bọ naa yi pada di okuta nla lorisirisi.
Lati igba naa si ni Ansoogun-Ọlala ti di orisa akunlẹbọ nilu Iresa-Adu to wa lẹba ilu Ogbomoso.

"Alaye ree lori idi ti ọba wa kii se lọ sidi ojubọ Ansogun-Ọlala tori ọba to ba de ibẹ, oun kọ ni yoo pada lọ sile"
Ni ilẹ Yoruba, ọpọ ilu lo jẹ pe awọn ọba wọn lo maa n lewaju araalu lọ si ojubọ orisa ilu naa amọ eyi ko ri bẹẹ pẹlu ilu Iresa-Adu.
Idi ni pe awọn ọba ilu Iresa-Adu ko gbọdọ de ojubọ orisa Ansoogun-Ọlala rara nitori awọn idi kan.
Nigba to n salaye idi ti eyi fi ri bẹẹ, Bara-Rẹsa ni awọn ọba ko tọju ojubọ Ansooun-Ọ́làlà lo mu ko binu.
"Ọba kan wa, ti wọn ko tọju ojubọ naa, o wa lọ sidi rẹ, o wa n dẹsun, amọ nnkan pada sẹlẹ si loju ẹsẹ.
Lati igba naa ni awọn ọba ilu naa kii ti lọ si ojubọ Ansoogun-Ọlálá mọ́ tori ọba to ba de ibẹ, ohun kọ ni yoo pada lọ sile."
Bakan naa, Oloye Olawale salaye awọn eroja ti wọn fi n bọ orisa Ansoogun-Ọlala ati eewọ to rọ mọ bibọ rẹ.
"Lara awọn eroja ti a fi n bọ Ansogun-Ọlala ni Aja dudu, epo pupa, iyọ, ẹmu ogidi, orogbo.
Amọ eewọ to rọ mọ eto bibọ orisa naa ni pe a ko gbọdọ se idi rẹ basubasu tori ẹni to ba se bẹẹ, loju ẹsẹ ni yoo gba ijiya rẹ."

"Ohun ti ẹ ba beere lonii lọdọ orisa Ansogun-Ọ̀lálá, laarin ọjọ meje, yoo ri bẹẹ, ko gbọdọ ma ri bẹẹ"
Oloye Olawale ni Ansogun ko ipa pataki lori idagbasoke ilu Iresa-Adu.
"Lara awọn ipa ti orisa naa n ko silu yii ni pe bi nnkan ibi to n bọ wa sinu ilu, ti yoo le wọ ilu naa.
Aitọju orisa naa mọ la se n ri awọn ohun ti a n ri yii, o si yẹ ki wọn ba wa gbe isẹse ni arugẹ.
Ti wọ̀n ba gbe awọ̀n orisa wa larugẹ, awọn eeyan yoo maa pe wa wo o bi wọn se n lọ si ilu Mecca ati Jerusalem.
Koda, mo n fi da yin loju npe ki ẹ beere ohunkohun ti ẹ ba fẹ nidi orisa Ansoogun-Ọlala, yoo si ri bẹẹ.
Ohun ti ẹ ba beere lonii, laarin ọjọ meje, yoo ri bẹẹ, ko gbọdọ mọ ri bẹẹ.
Awisẹ wa nibi, ohun ti wọn ba wi, yoo ri bẹẹ ni, ki ijọba kan gbe larugẹ ni, awọn eeyan ko nilo lati maa fo loju ofurufu, ki adura wọn to gba."







