Joash Amupitan, alága tuntun fájọ INEC búra láti ṣètò ìdìbò níbi tí ẹni tó fìdí rẹmi yóò ti kí ẹni tó yege ìbò kú oríire

Oríṣun àwòrán, JOSEPH AYO BABALOLA UNIVERSITY
Ilé aṣòfin àgbà Nàìjíríà ti buwọ́lu ìyànsípò Ọ̀jọ̀gbọ́n Joash Ojo Amupitan gẹ́gẹ́ bí alága àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn aṣòfin láti ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́ àti ẹgbẹ́ alátakò da àwọn ìbéèrè bò ó nígbà tó yọjú sílé aṣòfin náà lọ́jọ́bọ̀.
Ìrètí wà pé ààrẹ Bola Tinubu yóò búra wọlé fún-un láìpẹ́.
Ààrẹ Tinubu kéde ìyànsípò Ọ̀jọ̀gbọ́n Amupitan gẹ́gẹ́ bí alága INEC tó sì forúkọ rẹ̀ ránṣẹ́ sílé aṣòfin lẹ́yìn tí alága àjọ náà tẹ́lẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood Yakubu parí sáà rẹ̀ tó sì ipò náà sílẹ̀ lọ́jọ́ Keje, oṣù Kẹwàá.
Àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ ààrẹ fi síta sọ pé "inú mi dùn láti fi orúkọ Ọ̀jọ̀gbọ́n Joash Amupitan ránṣẹ́ sí ilé aṣòfin láti buwọ́lu ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alága INEC.
ÀÀRẸ Tinubu ní ìyànsípò Amupitan wà ní ìbámu pẹ̀lú abala 154(1) ìwé òfin Nàìjíríà, tó sì rọ àwọn aṣòfin láti tètè ṣe àyẹ̀wò rẹ̀, kí wọ́n tètè buwọ́lu ìyànsípò náà.
Ṣáájú ni ìgbìmọ̀ àkóso orílẹ̀ èdè ti kọ́kọ́ buwọ́lu ìyànsípò Amupitan.
Ẹ̀wẹ̀, àwọn kan ti ń kọminú lórí ìyànsípò Amupitan gẹ́gẹ́ bí alága INEC bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn kàn án pé ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC.
Wọ́n ní ó wà lára àwọn agbẹjọ́rò ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
"Afojusun mi ni pe ka seto idibo nibi ti awọn to fidi rẹmi yoo ti maa ki awọn to yege ku oriire pẹlu inu mimọ"
Nibayii tile asofin agba ti fontẹlu Amupitan gẹgẹ bii Alaga fun ajọ INEC, lo ti bẹrẹ saa rẹ.
Nigba to n dahun ibeere lọdọ awọn asofin agba, Amupitan seleri pe lasiko ti oun eto idibo nilẹ yii ko ni lọwọ magomago ninu, bẹẹ si ni ẹni to ba fidi rẹmi ninu ibo ni yoo maa ki ẹni to ba jawe olubori ku oriire.
Amọ o ni oun nilo atilẹyin awọn ileesẹ ijọba miran bii ajọ to n seto iforukọsilẹ ati ipese kaadi idanimọ fawọn ọmọ Naijiria, NIMC, ileesẹ to n se akoso eto ibaraẹnisọrọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Amupitan lo sọ awọn ọrọ yii ki ile asofin to seto ifọrọwanilẹnuwo fun ati lẹyin eto naa.
"Afojusun wa ni pe ka seto idibo nibi ti awọn to fidi rẹmi yoo ti maa ki awọn to yege ku oriire pẹlu inu mimọ.
Bakan naa, awọn adajọ yoo gbe idajọ kalẹ, ti inu awọn olupẹjọ ati olujẹjọ yoo si dun, ti wọn yoo si tẹwọ gba esi idibo naa.
"N ko farahan niwaju igbimọ oluwadi esi ibo aarẹ fun Tinubu tabi nile ẹjọ kotẹmilọrun abi nile ẹjọ to ga julọ, n ko sisẹ gẹgẹ bii ara ọmọ ẹgbẹ iselu PDP tabi ẹgbẹ Labour abi ikọ agbẹjọro wọn"
Nigba to n dahun ibeere lọdọ awọn asofin naa, Amupitan tii se ọjọgbọn imọ nipa ofin lati ipinlẹ Kogi, Amupitan ni oun kọ lo lewaju ikọ amofin fun Aarẹ Bola Tinubu lasiko awuyewuye to suyọ lori esi ibo aarẹ to kọja.
O ni oun ko tiẹ farahan niwaju igbimọ oluwadi nipa esi ibo aarẹ naa tabi nile ẹjọ kotẹmilọrun abi nile ẹjọ to ga julọ.
Bakan naa lo ni oun ko sisẹ gẹgẹ bii ara ọmọ ẹgbẹ iselu PDP tabi ẹgbẹ Labour abi ikọ agbẹjọro wọn.
Ọkan lara nnkan akọkọ ti a gbọdọ se ni lati fidi ilana kan gboogi mulẹ lati tọpinpin ihuwasi ati isesi awọn osisẹ ajọ eleto idibo.
Bakan naa, Amupitan tun seleri pe oun yoo seto ayẹwo oju opo ti wọn n fi esi ibo si labẹ ajọ INEC, (IReV) lọna ati wa ojutu si awọn asise to n mu kawọn araalu ma ni igbẹkẹle mọ lori oju opo naa lọdun 2023.
O ni bawọn ẹrọ ti wọn fi n se ayẹwo orukọ oludibo, BVAS ati IreV ba gbegede, ni yoo mu ki esi ibo naa jẹ itẹwọgba lọdọ araalu, gẹgẹ bo se n waye jakejado agbaye.
"Mo setan lati se agbekalẹ igbimọ ti yoo maa risi ihuwasi osisẹ ajọ INEC, lọna ati se agbeyẹwo awọn ẹsun to ni se pẹlu ihuwasi awọn osisẹ wa"
Alaga INEC tuntun wa fikun pe o yẹ ki ijọba se agbekalẹ ajọ ti yoo maa tanna wadii awọn ẹsun to nii se pẹlu idibo ati awọn eeyan to huwa kotọ lasiko idibo.
Amupitan ni " Pẹlu igbẹkẹle tawọn eeyan ni ninu mi ni mo fi gba ipo yii, gbogbo awọn eeyan ti yoo si ba mi sisẹ lo gbọdọ gba pe awọn wa lori igbẹkẹle araalu ni.
Mo setan lati se agbekalẹ igbimọ ti yoo maa risi ihuwasi nibamu peẹlu ilana ofin ati atẹle rẹ laarin ajọ INEC, lọna ati se agbeyẹwo awọn ẹsun to ni se pẹlu ihuwasi awọn osisẹ wa."
"Ọpọ ẹsun nipa sise magomago lasiko idibo lo ti waye sẹyin, ọpọ ẹsun yii si ni wọn ko se ayẹwo rẹ.
Fun apẹrẹ, awọn ẹsun to waye lasiko eto idibo ni ipinlẹ Bayelsa ati Adamawa, wọn se iwadi awọn eeyan kan to lọwọ ninu ẹsun naa, ti wọn si gbe wọn lọ sile ẹjọ, bẹẹ ni wọn gba ijiya labẹ ofin.
A setan lati tẹle iru igbesẹ bayii, ki awọn esi ibo ta ba kede le jẹ itẹwọgba lọdọ araalu, ka si le jiyin isẹ iriju wa bo se yẹ."
Ta ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Joash Amupitan?
Ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta (58) ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Joash Amupitan, tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Aiyetoro-Gbede, ìjọba ìbílẹ̀ Ijumu ní ìpínlẹ̀ Kogi.
Ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin, ọdún 1967 ni wọ́n bí i.
Onímọ̀ nípa òfin ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Amupitan.
Ọdún 2014 ló di agbẹjọ́rò àgbà, ìyẹn Senior Advocate of Nigeria, SAN.
Lẹ́yìn tó parí ilé ẹ̀kọ́ girama ló tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ìpínlẹ̀ Kwara ìyẹn Kwara State Polytechnic, Ilorin láàárín ọdún 1982 sí 1984 àti ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Jos láàárín ọdún 1984 sí 1987.
Ọdún 1988 ló di agbẹjọ́rò, tó sì gba oyè ọ̀mọ̀wé lọ́dún 2007.
Ṣáájú ìyànsípò rẹ̀, Amupitan ni igbákejì gíwá àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Jos tó ń rí sí àkóso ilé ẹ̀kọ́ náà.
Ó ní ìyàwó pẹ̀lú ọmọ mẹ́rin.
Bákan náà ló tún jẹ́ alága alákòso ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ayo Babalola University tó wà ní ìpínlẹ̀ Osun.
Yàtọ̀ sí ètò ẹ̀kọ́, Amupitan ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìgbìmọ̀ àwọn lájọlájọ tó fi mọ́ Integrated Dairies Limited, Nigerian Institute of Advanced Legal Studies Governing Council, Council of Legal Education, Riss Oil Limited, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Alága tuntun fún INEC náà tún jẹ́ òǹkọ̀wé tó sì ti kọ ọ̀pọ̀ ìwé lórí òfin bíi Models and Principles (2008); Documentary Evidence in Nigeria (2008); Evidence Law: Theory and Practice in Nigeria (2013), Principles of Company Law (2013) àti Introduction to the Law of Trust in Nigeria (2014).
Iṣẹ́ àkọ́kọ́ tó máa ṣe gẹ́gẹ́ alága INEC ni láti ṣètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra tó máa wáyé lọ́jọ́ Kẹjọ, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025.















