Àwọn oúnjẹ àti ọbẹ̀ Yorùbá tí kò wọ́pọ̀ mọ́ táwọn ọ̀dọ́ 'Gen Z' lè má mọ̀

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Yoruba bọ wọn ni ounjẹ lọrẹ awọ, ati pe ọna ọfun lọna ọrun, eyi lo difa fun ajọ iṣọkan agbaye UNN ti wọn kede gbogbo ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹwaa ọdọọdun gẹgẹ bi ayajọ ọjọ ounjẹ.
Akori ayajọ ounjẹ lagbaaye tọdun yii ni ṣiṣẹ pọ lagbaaye lati ni ọjọ iwaju ti ounjẹ yoo pọ yanturu, ti ounjẹ yoo si sun awọn olugbe aye bọ.
Idi niyii ti a fi ṣe akojọpọ awọn irufẹ ounjẹ Yoruba kan ti ko wọpọ mọ atawọn ọbẹ kan tawọn ọdọ ode oni ko ṣaba jẹ mọ.
Wọnyii ni awọn ounjẹ ti ko wọpọ mọ nilẹ Yoruba yala tori ọwọngogo kan tabi tori pe awọn eeyan ko ṣaba jẹ wọn mọ:
Egbo

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Egbo jẹ ọkan lara awọn ounjẹ ti kọ ṣaba wọpọ mọ nilẹ Yoruba, koda, ọpọ awọn ọdọ aye ode oni ni ko mọ ounjẹ ti wọn n pe ni egbo.
Agbado gbigbẹ ni wọn maa n fi se egbo, ẹrọ ni wọn maa n fi bo agbado gbigbẹ naa lati ṣi awọ ara rẹ kuro.
Wọn si tun le gun un ninu odo lati ṣi awọ ara agbado naa.
Lẹyin ti wọn ba ti bo awọ ara agbado naa tan ni wọn maa fi ẹrọ wẹ ẹ.
Agbado ti wọn ba ti wẹ yii ni wọn yoo se lori ina titi ti yoo fi rọ pẹtẹpẹtẹ ti yoo si di egbo.
Wọn maa n din ata si egbo ni, awọn mii si maa n fi ororo jẹ egbo bakan naa.
Koda, awọn eeyan tun maa n jẹ egbo ati ẹwa papọ.
Ekuru

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ekuru jẹ ounjẹ kan to wọpọ tẹlẹ nilẹ Yoruba, amọ, o dabi ẹni pe ounjẹ yii ko wọpọ mọ nilẹ Yoruba bayii.
Tẹlẹ, nibi ti ẹ ba ti ri mọin-mọin, ekuru naa maa n ṣaba wa nibẹ.
Ṣadeedee ni mọin-mọin gbori lọwọ eku ti a ko si saba ri ekuru mọ bii ti tẹlẹ.
Ẹwa ni wọn maa n fi se ekuru, ninu omi ni wọn maa kọkọ rẹ ẹwa naa si ko le rọ daadaa.
Lẹyin to ba rọ tan ni wọn yoo fi ọwọ bo ẹwa naa lati yọ ireju rẹ kuro.
Bayii ni wọn yoo lọ ẹwa to ti rọ yii, wọn maa n fi iyọ ati alubọsa si ti wọn ba ti lọ ọ tan.
Lẹyin naa ni wọn yoo da a sinu agolo ti wọn yoo si gbe e lena.
Wọn maa n din ata gbigbẹ lati jẹ ekuru ni, ati pe wọn kii lọ ata ti wọn maa n lo kun-na.
Mọsa
Mọsa naa jẹ ọkan awọn ounjẹ to wọpọ nilẹ Yoruba tẹlẹ, amọ, ti a ko ṣaba maa ri daadaa mọ.
Bi awọn ọmọde ṣe maa n ra pọọpọọfu naa ni wọn maa n ra mọsa tẹlẹ.
Bo tilẹ jẹ pe mọsa ati pọọpọọfu jọ ara wọn, nnkan ti wọn fi n ṣe mejeeji yatọ sira.
Fulawa ni wọn maa n fi ṣe pọọpọọfu, nigba ti wọn maa n lo agbado gbigbẹ fun mọsa.
Agbado gbigbẹ yii ni wọn yoo lọ ti wọn yoo si po o lomi.
Ṣuga ni wọn maa n po pọ mọ agbado ti wọn ba ti lọ yii, ti wọn yoo si da a sori ina ninu ororo.
Wọn maa n fi ṣuga fọn mọsa to ba jina tan.
Igbalọ
Igbalọ naa wa lara awọn ounjẹ Yoruba ti ko wọpọ mọ bayii.
Tẹlẹ, ẹni to ba n kiri ọọlẹ naa lo maa n ṣaba kiri igbalọ.
Oju igbalọ maa n funfun ni nigba ti mọin-mọin maa n pọn loju tori epo pupa ti wọn maa n da si i.
Bi wọn ṣe maa n ṣe mọin-mọin ati igbalọ jọ ara wọn, ṣugbọn iyatọ diẹ si wa nibẹ.
Iyatọ to wa nibẹ ni pe wọn maa n lọ ẹgusi gbigbẹ pọ mọ ẹwa tutu ti wọn ba ti bo tan.
Ohun miran ni pe ororo ni epo ti wọn maa n fi se igbalọ dipo epo pupa ti wọn maa n lo fun ọọlẹ.
Ṣapala

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ṣapala tawọn mii maa n pe ni abari naa wọpọ tẹlẹ nilẹ Yoruba, koda, wọn maa n ṣaba kiri rẹ kaakiri adugbo nigba kan.
Amọ, lode oni ko ri bẹẹ mọ tori o loju ibi ti ẹ ti le ri ṣapala ra bayii.
Agbado tutu to ba ti kale ti wọn maa n pe ni agbado ṣikiti ni wọn maa n fi ṣe ṣapala.
Agbado yii ni wọn maa n lọ bi ẹwa ti wọn yoo si po o mọ epo pupa.
Lẹyin ti wọn ba ti fi ata ati alubọsa si i tan ni wọn yoo gbe e lena.
Awọn mii maa n fi epo pupa jẹ ṣapala ti o ba ti jina papaa julọ ni gbigbona.
Ṣakada

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ṣakada jẹ nnkan ipanu to wọpọ tẹlẹ lawọn apa ibikan nilẹ Yoruba bii ipinlẹ Oyo.
Amọ, ṣakada ko wọpọ mọ bayii, koda, ọpọ eeyan papaa julọ awọn ọdọ Gen Z ni ko mọ ohun to n jẹ bẹẹ.
Ẹgẹ ni wọn maa n fi ṣe ṣakada, lẹyin ti wọn ba ti bẹ ẹgẹ tan ni wọn yoo fọ ọ ko le mọ daadaa.
Lẹyin eyi ni wọn yoo rin ẹgẹ naa bi ẹni pe wọn fẹ fi ṣe gaari.
Ẹgẹ ti wọn ba rin yii ni wọn yoo da sinu agolo ti wọn yoo si gbe sori agbada to wa lori ina.
Agbọn ni wọn maa n ṣaba fi jẹ ṣakada, to ba ti jina tan.
Akara kengbe
Akara kengbe naa wọpọ tẹlẹ kaakiri ilẹ Yoruba, akara yii ni ọpọ ṣaba maa n jẹ ki awọn eeyan to maa fi ororo din akara daadaa.
Epo pupa ni wọn maa n fi din akara kengbe, wọn si maa n po o ki daadaa.
Ẹwa ti wọn ba ti bo to ba ti rọ ninu omi ni wọn yoo lọ ti wọn yoo si po o ki daadaa.
Eyi lo maa n jẹ ki akara kengbe fun ẹni to ba n jẹ ẹ lọrun tori o maa n ki daadaa.
Ṣugbọn akara olororo lọ pọ kaakiri ilẹ Yoruba bayii, akara kengbe ko wọpọ mọ.
Awọn ọbẹ Yoruba ti ọpọ ọdọ Gen Z ko mọ
Ilaṣa

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ilaṣa jẹ ọbẹ ti Yoruba maa n fi ewe ila se.
Amọ, lati ara ila yii, awọn ọbẹ mii wa ti ko gbajumọ to si jẹ ọbẹ ti Yoruba fẹran lati maa jẹ, to si maa n ṣe ara loore.
Ewe ila ni ilaṣa, ti wọn si maa n ge wẹwẹ bii ewedu.
Laaarin awọn eeyan ilu Igbo-Ora ati Ibarapa ni ipinlẹ Oyo ni ọbẹ yii ti gbajumọ.
Eeyan le se ilaṣa ni ọbẹ alasepọ gẹgẹ bi ila, ti oun naa si maa n yọ bii ila.
Ko si okele ti eeyan ko le fi ọbẹ ilasa jẹ yala amala, ẹba, sẹmo, fufu tabi iyan.
Amọ, ọbẹ ilaṣa ko wọpọ mọ nilẹ Yoruba bii ti tẹlẹ, koda ọpọ ọdọ ni ko le da a mọ gan an.
Ọrunla
Ọkan lara awọn ọbẹ ti eeyan le ri lara ila naa ni ọrunla wa.
Ti a ba fẹ se ọrunla, a maa ge ila si wẹwẹ, ti a o si sa a loorun ti yoo fi gbẹ.
Lẹyin to ba gbẹ tan ni a maa lọ ọ kuna lubulubu, ti eeyan yoo si maa bu u se diẹ diẹ.
Ọrunla naa ṣe e se ni alasepọ tabi ki ẹ se e lasan ki a bu omi ọbẹ le e lori lati fi gbe okele sọhun-un.
Ṣugbọn ọpọ ọdọ nilẹ Yoruba le ma da ọbẹ ọrunla mọ tori ko wọpọ mọ.
Iṣapa
Iṣapa toro mọyan ni Yoruba maa n wi.
Ọbẹ iṣapa fi ara jọ ila amọ kii ṣe ila, koda kii ṣe ọbẹ to maa n yọ rara.
Laarin awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ati Ondo ni ọbẹ yii ti wọpọ julọ nitori iyan ni ọpọlọpọ fẹran lati maa fi ọbẹ yii jẹ.
A le se iṣapa pelu ẹgusi tabi ki eeyan se e lasan.
Ko si ounjẹ ti eeyan ko le fi iṣapa jẹ koda to fi mọ irẹsi.
Amọ, ọbẹ iṣapa ko ṣaba wọpọ mọ nilẹ Yoruba.
Ẹku
Ẹku jẹ ọbẹ to maa n yọ, to si farajọ ewedu koda awọn eeyan ilu Ilorin fẹran lati maa se ewedu ati ẹku papọ.
Ẹku jẹ ọbẹ to maa n yọ gidi ti o si pọ ni awọn agbegbe Oyo, Iseyin ati apa Oke Ogun.
Ọbẹ ẹku ṣe e se ni tutu bii ewedu tabi ki eeyan se e ni gbigbẹ, eyi tumọ si pe eeyan maa n sa ẹku titi ti yoo fi gbẹ.
Lẹyin ti o ba gbẹ tan ni a maa n fi ọwọ run un to maa fi kun-na lubulubu.
Ṣugbọn ọbẹ yii ko saba wọpọ mọ bayii nilẹ Yoruba.
Elegede
Elegede jẹ eso kan to farajo ẹgusi.
Elegede ni a maa n se bi awọn ẹfọ yooku ti a si maa n se eso rẹ bii ti ẹgusi.
Olu
Bi o tilẹ jẹ pe gbogbo olu kọ ni o se e jẹ amọ awọn olu kan wa ti Yoruba maa n jẹ.
Lara rẹ ni olu ogogo ati olu ọran.
A le se awọn olu yii pẹlu ẹgusi ti a le fi jẹ okele.
Wọọrọwọ
Wọrọwọ wọpọ laarin awọn eeyan ilu Iwo ni ipinlẹ Osun, bẹẹ naa, o si wa nipinlẹ Ekiti.
Lasiko ti iṣu tuntun ba ṣẹṣẹ jade ni ẹfọ yii maa n pọ nita.
Bi a ṣe maa n se awọn ẹfọ riro naa ni a maa n se wọrọwọ.
Ti a ba ni ki a maa ka a, a o le ka ọbẹ Yoruba tan nitori a si ni awọn ọbẹ bii ẹfọ odu, osungbagba, yanrin, ebolo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Amọ, ọpọ awọn ọbẹ yii ni ko wọpọ mọ, ati pe ọpọ ọdọ nilẹ Yoruba ni wọn o mọ awọn ọbẹ naa.















