Èèyàn mẹ́ta bá òkú olóòtù ìjọba tẹ́lẹ̀ ní Kenya rìn lọ sọ́run bí ọlọ́pàá ṣe yìnbọn àti afẹ́fẹ́ tajútajú sọ́pọ̀ èrò tó ń kí òkú ọ̀hún káàbọ̀

Awọn abanikẹdun nibi eto isinkun Raila Odinga

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan, eeyan mẹta lo ti jade laye ni Kenya lẹyin ti ọlọpaa yin ibọn ati gaasi tajutaju ni papa iṣere ti ọpọ ero ya bo lati ṣọfọ olootu ijọba tẹlẹ, Raila Odinga.

Ẹgbẹ ajafẹtọọmọniyan kan, Vocal Africa sọ fun BBC pe wọn ti ko oku eeyan mẹta naa lọ si ile igbokupamọsi.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle mii jabọ pe eeyan mii tun ku, eyii to sọ apapọ gbogbo awọn to jade laye di mẹrin lasiko ti ọlọpaa n tu awọn ọgọrọ ero ọhun ka.

A ko ti le sọ boya ọta ibọn gidi tabi ọta ibọn onirọba ni wọn yin ni gbagede eto isinku naa to waye niluu Nairobi.

Amọ Vocal Africa fidi rẹ mulẹ pe ọta ibọn lo ṣekupa gbogbo awọn to padanu ẹmi wọn nibẹ.

Ọjọru ni Odinga, to jẹ agba ọjẹ oloṣelu ni Kenya papoda lorilẹede India.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye

Nigba ti yoo di Ọjọbọ ni oku rẹ balẹ si papakọ ofurufu orilẹede naa ni owurọ, amọ awọn ero to jade wa pade oku rẹ pọ to bẹẹ ti papakọ ofurufu ọhun fi dawọ iṣẹ duro fun akoko diẹ.

Awọn abanikẹdun ri aye wọ ibi ti ko yẹ ki ọgọrọ ero wọ, eyii to jẹ ki wọn fi lilọ-bibọ awọn ọkọ ofurufu rọ fun nnkan bii wakati meji.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bẹrẹ lati papakọ ofurufu ọhun ni ẹgbẹgbẹrun eeyan ti n tẹle oku Odinga lọ si papa iṣere to wa laarin ilu Nairobi, eyii to jẹ nnkan bii kilomita mẹwaa si papakọ ofurufu ọhun.

Nitori ọgọrọ ero to wa wo oku naa, wọn ni lati sun ayẹyẹ itẹ oku naa ni gbangba si gbagede Moi International Sports Centre to wa ni Kasarani.

Lẹyin iṣẹju diẹ ti oku Odinga de papa iṣẹre naa, ni ọpọ ero ya bo odi rẹ ti wọn si wo lulẹ, eyii to mu ki ọlọpaa yin gaasi tajutaju lati tu wọn ka.

Bi gaasi tajutaju ọhun ṣe n balẹ ni awọn eeyan naa n sare kiri lati jade kuro ninu gbagede ọhun.

Akọroyin BBC to wa nibẹ ni oun foju ganni awọn kan ti wọn n fi igi lu araalu amọ wọn ko wọ aṣọ agbofinro.

Wayi o, awọn mọlẹbi Odinga ni lati sin oku rẹ laarin ọjọ mẹta pere to fi aye silẹ gẹgẹ bii alakalẹ to fun wọn ṣaaju iku rẹ.

Odinga ṣubu lulẹ ni India lasiko to n rin irin ere idaraya laarọ Ọjọru ki wọn to gbe digbadigba lọ ile iwosan Devamatha nibi to dakẹ si.

Ijọba kenya ti kede ọjọ meje gbako lati ṣọfọ oloogbe ọhun.