Hajj 2026: Ìdí rèé tí ìjọba Saudi ṣe mú àdínkù bá iye ọmọ Naijiria tí yòó lọ Hajj lọ́dún tó n bọ̀

Aworan awọn arinrinajo Hajj to fẹ wọ baaluu.

Oríṣun àwòrán, NAHCON

Àkọlé àwòrán, Awon arinrinajo to fẹ wọ baaluu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni igbaradi fun iṣẹ Hajj ọdun 2026, orilẹede Saudi Arabia, ti mu adinku ba iye ọmọ Naijiria ti yoo wọ ilu naa fun isin ọlọdọọdun naa lọdun to n bọ

Atẹjade kan ti ajọ to n ri si irinajo Hajj ni Naijiria, National Hajj Commission of Nigeria (NAHCON) fi sita l'Ọjọbọ ana, kede adinku naa.

Atẹjade ọhun ti Igbakeji Alukoro NAHCON, Fatima Usara, buwọlu, ṣalaye pe apapọ aaye to wa fun awọn ọmọ Naijiria fun Hajj 2026 jẹ 66,910, ninu rẹ ni wọn si ti fun wọn ni 95,000.

Itumọ eyi bi wọn ṣe ṣalaye ni pe iye eeyan to le lọ si Mecca ni 2026 lati Naijria, jẹ 51,513 lati awọn ipinlẹ ati ẹka ijọba, nigba ti eeyan 15,397 yoo lọ pẹlu awọn ileeṣẹ arinrinajo aladaani.

Kí ló fa àdínkù yìí?

Gẹgẹ bi alaye NAHCON, adinku ba iye eeyan ti yoo wọ Saudi fun Hajj lọdun to n bọ lati dena ohun to ṣẹlẹ ni 2025.

Ohun to ṣẹlẹ bi wọn ṣe wi ni pe awọn arinrinajo Naijiria ko ba ijọba rin lọ si Saudi bi wọn ṣe fi aaye pupọ silẹ fun wọn to.

NAHCON sọ pe aaye ti iye rẹ jẹ 52,544 ni wọn fi silẹ fawọn ọmọ Naijiria fun iṣẹ Hajj ọdun 2025, ti yoo ba ijọba ipinlẹ wọn lọ.

O ni ṣugbọn iyalenu lo jẹ, pe eeyan 41,218 pere lo ba ijọba ipinlẹ wọn lọ si Saudi.

Awọn alalaaji ẹgbẹrun mejidinlogun (18,000) si ba ileeṣẹ aladaani rin irinajo naa bi NAHCON ṣe sọ.

Eyi lo mu apapọ arinrinajo lọ si Saudi ni 2025 jẹ 59,128, ti aaye 35,872 si wa nilẹ lai jẹ pe ẹnikẹni lo o, bi ileeṣẹ to n pin in fun Hajj ati Umrah ṣe pin in.

Ìpàdé wáyé

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbesẹ yii ti mu ki ẹka to n ri si irinajo Hajj lorilẹede yii (State Pilgrims Welfare Boards) ṣe ipade l'Ọjọbọ ana pẹlu NAHCON.

Kọmiṣanna to n ri si bo ṣe n lọ nileeṣẹ naa, Ọmọọba Anofiu Elegushi, sọ pe atunyẹwo yoo waye lori igbesẹ adinku yii.

Elegushi sọ pe ipinlẹ ti awọn eeyan rẹ ko ba lo aaye ti wọn fun wọn tan ni ti 2025 ni yoo faragba adinku ọtẹ yii ju.

Bakan naa ni Alaga NAHCON, Ọjọgbọn Abdullahi Usman, rọ awọn ti ọrọ yii kan lati ṣiṣẹ pọ, ki wọn le kapa idena yowu to ba fẹ waye, ṣaaju Hajj 2026.

O ni iṣẹ n lọ lori owo Hajj to n wọn si i lọdọọdun, NAHCON n gbe igbesẹ lori bi owo awọn nnkan kan, titi kan owo ẹru arinrinajo yoo ṣe dinku.

Bakan naa ni aṣoju ileefowopamọ apapọ ile wa CBN ni NAHCON,Ọmọwe Adetona Adedeji, naa ṣeleri lati ri i pe CBN din ida meji owo ti wọn maa n gba lori idunaa-dura awọn arinrinajo ku.

NAHCON ko ṣai sọ pe ilana ẹru gbigbe lagbaaye ni HAJJ 2026 yoo tọ, arinrinajo kan ko le gbe ju ẹru to wọn ida 23kg meji lọ, ati baagi apamọwọ kan.

Lafikun, ajọ to n ri si irinajo lọ si Saudi sọ pe oun ko ni i gbe alaarẹ ni 2026.

Wọn ni awọn eeyan ti wọn ni iṣoro ẹya ara to daṣẹ silẹ, awọn ti ilera ọpọlọ wọn ko pe, awọn ti igbagbe n yọ lẹnu, awọn oloyun, ẹni to ni jẹjẹrẹ to si n gba itọju (chemotherapy) lọwọ, awọn ko ni i gbe wọn.

Bakan naa ni ẹni to ni ikọ ife, (Tuberculosis) ati awọn arun mi-in to ba le ran ẹnikeji.