Defence HQ: Ilé iṣẹ́ ológun Nàìjíríà fèsì sí awuyewuye pé wọ́n yọ́lẹ̀ sìnkú

Oríṣun àwòrán, AFP
Ile iṣẹ awọn ọmọ ogun alaabo Naijiria ti bu ẹnu at lu iroyin to n tan kalẹ pe wọn ni saree ikọkọ ni iha Ila Oorun-Ariwa Naijiria.
Eyi ni esi ti wọn fi sita si iroyin ti awọn oniroyin kan Wall street Journal fi si oju opo wọn pe ile iṣẹ ogun yọlẹ sin oku ọpọlọpọ awọn ọmọ ogun ni saree ikọkọ wọn lati bo onka iye awọn to ku loju ogun pẹlu awọn agbesunmọmi mọlẹ.
Gẹgẹ bi ọrọ ti ile iṣẹ ogun fi sita, wọn awọn ni aṣa ati ilana ti awọn maa n tẹle lati ṣe isinku awọn akọgun to ba ku lara awọn nitori naa awọn ko yọ nkankan ṣe.
"Ni ilana aṣa ti ile iṣẹ ogun Naijiria, a maa n buyi fun awọn akọgun a si maa n pọn wọn le nigba ti a ba n ṣelede lẹyin wọn.
Lara ohun taa ma n ṣe ni yiyan gẹgẹ bi ologun, ọrọ ikẹyin leti iboji, adura ni aafaa Islam tabi alufa Kristẹni to fi mọ yiyin ibọn soke ati bẹẹ bẹẹ lọ" lo wa ninu ọrọ ti wn fi sita.
Ile iṣẹ ogun fi kun un wi pe saare ti iroyin naa n sọ nipa rẹ iyẹn to wa ni bareke ologun Maimalari jẹ ti ile iṣ ogun sọ́ọ́ to si wa apa Ila Oorun- Ariwa Naijiria.
Lati igba yii lawn eniyan ti n tu ọrọ sita lori ohun ti wọn gbọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ẹwẹ, awọn oniroyin WSJ ni awọn ni aridaju orisun iroyin laarin awọn ologun Naijiria gan to fi mọ ọga kan lẹnu iṣẹ ọba.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ọ, sọ́jà kan to ba wọn sọ̀rọ lati bareke ologun to wa ni Maimalari sọ fun wọn pe "wọn sin ọpọlọpọ ologun sinu saree ikọkọ naa ni alẹ nibi ti o to ẹgbẹrun kan ologun to n gbe nibẹ, bi wọn ṣe n ku ni wọn n pa orukọ wọn rẹ ninu itan".
Ṣugbọn ile iṣẹ ologun Naijiria ni ki awọn eeyan kọ eti ikun si ọrọ yii patapata.
Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ si















