Asset Declaration: Gbogbo ẹni tí ó máa búra wọlẹ́ gẹ́gẹ̀ bíi Mínísítà gbudọ̀ kéde dùkìá

Rauf Aregbesola
Àkọlé àwòrán, Ọ̀kan lára àwọn Mínísítà tuntun

Igbimọ eleto idajọ to n gbọ ẹsun iwa aṣemaṣe awọn eeyan to dipo oselu mu ati oṣiṣẹ ọba, CCB ti paṣẹ fun awọn ti aarẹ Buhari fẹ yan sipo minisita lati kede dukia wọn ki wọn to ṣebura wọle tabi ki w n koju ofin.

Ajọ naa n gbero lati ṣewadi awọn dukia naa ni ẹka ijọba to n ṣabojuto ọrọ ilẹ, ile ifowopamọ ati awọn ile iṣẹ ti wọn ba ni, ati eyi ti wọn ba nipin ninu rẹ.

Babatunde Fashola

Oríṣun àwòrán, @PeckyOfficial/Twitter

Àkọlé àwòrán, Mínísítà tó bá kọ̀ láti kéde dùkìá yóò kojú òfin

Siwaju si, ajọ naa yoo tun ṣiṣẹ pẹlu ile iṣẹ otẹlẹmuyẹ lati wadi awọn dukia ti wọn ba ni ni oke okun.

Alaga CCB, Prof. Muhammed Isah wi pe ko si ẹnikẹni ninu awọn minisita tuntun naa ti wọn yoo ṣebura wọle fun lai kọkọ kede dukia wọn.

Àkọlé fídíò, Àìsàn jẹ́ kí àwọ̀ ara Amida dàbí ara ẹja

O tun ni lara awọn minisita yii ti gba iwe ikede dukia bẹẹni awọn miran ko tii gba.