NAPTIP tún mú afurasí tó n kó ómódébìnrin lọ ilẹ̀ òkèèrè

Oríṣun àwòrán, NAPTIP/facebook
Àjọ to ń rí sì fayawọ ọmọniyan lorile-ede Naijiria (NAPTIP) ti gba àwọn ọmọbìnrin mẹ́tàlá kan silẹ.Wọn tú àwọn ọmọbìnrin náà silẹ lásìkò tí wọn ṣèwádìí lọ sí ilé ìgbàfẹ́ kàn to ń jẹ Amazonia Guest House ni agbègbè Gwagwalada n'ilu Abuja.Bákan náà ni ọwọ sinkun àjọ NAPTIP tó ọkùnrin kan, Afeez Abdulsalam, tí wọn ti ń wà fún ẹ̀sùn kíko àwọn ọmọbìnrin lọ sí orile-ede Saudi Arabia, ni bí ti wọn ti ń lò wọn fún onírúurú ìṣe ìdọ̀tí.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Adarí ẹ̀ka kan nínú àjọ NAPTIP, Ogbẹ́ni Josiah Emerole, salaye pe, o tí pẹ́ tí àwọn tí ń ṣọ́ agbègbè náà kí àwọn tó rí wọn gbà sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, NAPTIP/facebook
Àjọ NAPTIP gbé ìgbése ọ̀hún pẹlu atileyin àṣẹ ilé ẹjọ́ láti sabewo sì ilé ìgbàfẹ́ náà tí wọn sì ti tíì pa báyìí títí tí ìwádìí yóò fi parí.









