Àwọn olórí orílẹ̀èdè lágbàáyé sọ èrò wọn lori ìkọlù Syria

àwọn orílẹ̀èdè lágbàáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹ́yín ti orilẹede Amerika, France ati ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí pawọ́pọ̀ se ìkọlu si orilẹede Syria, awọn orilẹede àgbàye ti n fi èrò wọn hàn lorisirisi.

Awọn kan sọ pe ìgbésẹ̀ ọ̀ún jẹ́ eyi tó tọ́ tó sì yẹ, nigba ti awọn mìíran ríi gẹgẹ bii oun tí kò tọ̀nà rárá.

Díẹ̀ lara awọn orilẹede ti wọn sọ sí ọ̀rọ̀ naa nìyí:

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Amerika

Aarẹ Donald Trump sọ pe, ìgbésẹ̀ naa jẹ èyí to mu èròngbà awọn wá sí ìmúsẹ. O ni àseyege gbaa ni ni ìkọlù naa jẹ́, ti ó sì tún dúpẹ́ lọ̀wọ̀ awọn orilẹede to fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹlu rẹ̀.

Orilẹede China

China ni tirẹ̀ ni awọn kò faramọ́ ikọlu naa nitori pe ó lòdì si òfin ìbásepọ̀ laarin awọn orilẹede lágbàáyé. China pe fun àtúntò ètò òsèlú lagbaye, ati pe, o ni ó tó ki awọn orilẹede agabye ''maa tẹ̀lé ìlànà to'tọ́".

Orlẹede Isreal

Benjamin Netanyahu ti orlẹede Isreal ní tirẹ̀ sọ pe, lati ọdún to kọjá ni oun ti sọọ́ pe, oun faramọ́ ki aarẹ Amerika Donald Trump "gbé ìgbésẹ̀ to tọ́ lori lílo Kẹ́míkà olóró" láàárín awn orilẹede lagbaaye.

Orilẹede Russia

Russia ni gbogbo ara lòún fi lòdì si bi orilẹede Amerika se kọlu orilẹede Syria "níbití orilẹede Russia ti n se ìrànlọ́wọ́ fun ìjọba to ba òfin mu lorilẹede Syria lati koju awọn ajìjàgbara."

Ó ní oun n pè fun ìpàdé pàjáwìrì ninu àjọ ìsọ̀kan àgbáyé.

Saudi Arabia

Saudi Arabia ni awọn faramọ́ bi Amerika, France ati ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì se kọlu Syria, nitori pe ikọlu ọun |"jẹ́ ìdáhùn si awọn ìwà ọ̀daràn ti ìjọba Bashar al-Assad n hù."

Turkey

Orilẹede Turkey ni "awọn fi ọwọ́ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá si ikọlu naa, nitori pe, o mu ẹ̀rì ọkàn fun ìwà ọmọnìyàn kuro, lẹ́yìn ìkọlù to wáyé ni Douma."