Big Jake Tallest Horse: Mọ̀lẹ́bí tó ní ẹṣin tó ga jùlọ lágbayé ń ṣé ìdàrò, wò nkán tí wọ́n fí n ṣé ìrántí rẹ̀

Aworan ẹṣin to ga julọ lagbaye

Oríṣun àwòrán, GUINNESS WORLD RECORDS

O ṣe diẹ ti a ti mu iru ikede iku bíi eyi wa si eti igbọ yin.

Ohun to si mu ka ṣe bẹẹ ni pe iru iku yi ṣọwọn laarin awọn ẹranko.

Tori naa, ẹ sunmọ ibi ki ẹ wa gbọ labari nipa iku Big Jake, ẹsin aramanda to ga julọ lagbaye.

Àkọlé fídíò, Wo obìnrin kanṣoso láàrin àwọ́n ọkunrin agunẹṣin gbafẹ́ nílùú Ilorin àmọ́ tọ́kàn rẹ̀ yii

Big Jake ti a bi ni nkan bi ogun ọdun sẹyin jade laye ni oko olowo rẹ Smokey Hollow Farm,Poynette to wa ni ilu Wisconsin lorileede Amẹrika.

Iyawo olowo rẹ, Valicia Gilbert sọ pe nkan bi ọsẹ meji sẹyin ni Big Jake jade laye ṣugbọn ko sọ pato ọjọ tii ṣe tabi ohun to ṣeku pa.

Valicia ati ọkọ rẹ Jerry Gilbert ni iku ẹṣin yi fọwọ kan awọn lẹmi koda awọn ẹsin to ku tawọn n sin naa n ṣe idaro Big Jake.

Nigba aye rẹ, Big Jake ni ẹṣin ti akọsilẹ wa ninu iwe manigbagbe Guiness Book of World Records pe o ga julọ lagbaye.

Jerry sọ pe iwọn mita meji o le diẹ ni iwọn giga rẹ to si to iwọn ẹgbẹrun kan o le ni mẹrindinlogoje kilograamu.

''Aramanda ẹṣin ni Big Jake to si wọn to mọkandinlaadọfa kilograamu nigba ti wọn bi. O fi kilograamu marundinlaadọta ju awọn ọmọ ẹṣin mii lọ.Akanda ẹṣin nii ṣe''

Àkọlé fídíò, BBC Yoruba pada lọ ṣabẹwo si ọja Bode nibi ti ọkọ to kun fọọ fun afẹfẹ gaasi ti dede sina wọ inu ọja to si pa awọn kan.

Jerry ṣalaye fawọn akọroyin pe awọn n gbero lati ṣe iranti Big Jake nipa ki wọn ma gbe ẹṣin kankansinu ibusun rẹ ati fifi aworan ati orukọ rẹ sara okuta nla nibẹ.

''Awọn ẹṣin to ku naa mọ pe o ti ku mo si lero pe awọn naa n ṣe idaro rẹ bi o ti ṣe ye wọn si.Gbogbo eeyan ati ẹranko lo maa n fi Jake ṣe iranwo nibi.O dabi pe o ṣi wa nibi ṣugbọn o ṣeni laanu pe o ti fiwa silẹ lọ''