Queen Elizabeth: Èyí ni ìtàn ìgbé ayé Ọbabìnrin Elizabeth kejì

Ọbabìnrin Elizabeth kejì

Oríṣun àwòrán, Baron/Camera Press

White Line 1 Pixel

Ọdun gbọọrọ tí Ọbabìnrin Elizabeth kejì lórí ìtẹ́ lo se afihan ọkan akin to ni lati se ojúse rẹ ati ipinnu ọkan lati fi aye rẹ jin fun ori itẹ to wa ati awọn eniyan rẹ.

Fun ọpọ eeyan, Ọbabìnrin Elizabeth keji jẹ òpó to duro digbi ninu aye to n fi ojoojumọ yipo kiri, nibayii ti agbara ilẹ Gẹẹsi n din ku, ti iyipada si n ba awujọ wa kọja idamọ, ti iyemeji si n waye lori ojuse ipo ọba gan.

Aseyọri rẹ lati mu ki itẹ rẹ duro re lai yẹsẹ, paapa lasiko ti ààrá n san, ti iji si n ja, gan ko see gbagbe, taa ba wo akoko igba ti wọn bii, ko si ẹni to lee mọ rara pe ori itẹ yii ni yoo jẹ ayanmọ rẹ.

A bi Elizabeth Alexandra Mary Windsor lọjọ kọkanlelogun osu kẹrin ọdun 1926, ninu ile kan to wa lẹyin gbagede Berkeley Square, nilu London, oun si ni Bẹ́ẹ́rẹ̀ ( akọbi ọmọbinrin) fun Albert, tii se Ọlọla Duke ti York, ẹni to jẹ ọmọkunrin keji fun Ọba George Karun-un ati iyawo rẹ, Ayaba Elizabeth Bowes-Lyon tẹlẹ.

Ọmọọbabinrin Elizabeth pẹlu awọn obi rẹ lọjọ ti wọn n sọọ lorukọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọmọ tuntun jojolo Elizabeth pẹlu awọn obi rẹ lọjọ ti wọn n sọọ lorukọ
White Line 1 Pixel

Elizabeth ati aburo rẹ obinrin, Margaret Rose, ẹni ti wọn bi lọdun 1930, ni wọn kẹkọọ ninu ile, ti wọn si tọ wọn dagba ninu ayika to jẹ ti ẹbi alayọ. Elizabeth sun mọ baba rẹ ati baba-baba rẹ, George Karun pẹki-pẹki.

Nigba to pe ọmọ ọdun mẹfa, Elizabeth sọ fun ẹni to n kọ ọ ni ẹsin gungun pe, oun fẹ jẹ "obinrin ti yoo maa gbe ni arọko lọjọ ọla, pẹlu ọpọlọpọ ẹsin ati aja."

A gbọ pe lati kekere ni Elizabeth, ti yoo jẹ asamu lọjọ ọla, ti n jẹ ẹnu ṣamu-ṣamu, to si n se afihan ọmọ to mọ ojuse rẹ. Winston Churchill, to jẹ olootu ijọba lọjọ iwaju, la gbọ pe, o sọ nigba kan pe, Elizabeth ni "afẹfẹ asẹ lara eyi to ya ni lẹnu pupọ lati ri lara majesin."

Ọmọọbabinrin Elizabeth n ba orilẹede sọrọ fun igba akọkọ, ti aburo rẹ obinrin, ọmọọbabinrin Margaret Rose si tẹle lẹyin. lọjọ kejila osu kẹwa ọdun 1940 nilu London
Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọọbabinrin, Elizabeth (ọwọ ọtun) ati Margaret, ti wọn n ba orilẹede sọrọ lasiko ogun agbaye keji

Bi o tilẹ jẹ pe Elizabeth ko lọ sile ẹkọ, sibẹ, o safihan imọ pupọ ninu oniruuru ede, to si kọ itan nipa ofin lẹkunrẹrẹ.

Wọn se agbekalẹ akanse ẹgbẹ ọmọbinrin kan, ti wọn pe ni Girl Guides, akọkọ iru rẹ ni aafin Buckingham, ki Elizabeth lee ni anfaani lati ba awọn akẹẹgbẹ rẹ lobinrin, ti wọn jọ jẹ irọ̀, kẹgbẹ pọ.

Aibalẹ ọkan n le koko si

Nigba ti Ọba George Karun waja lọdun 1936, Arẹmọ rẹ, ti wọn n pe ni David, di Ọba Edward kẹjọ.

Amọ aya to yan laayo, Wallis Simpson, to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika, to ti kọ ọkọ fun igba meji, ni awọn ẹlẹsin ati oloselu ko fara mọ. Lẹyin ọdun kan, Ọba Edward kẹjọ fi ori oye silẹ.

Ọlọla Duke ti York, tii se baba Elizabeth, to n lọra tikọ lati di Ọba, lo papa wa di Ọba George Kẹfa. Ayẹyẹ igbade Ọba yii si lo mu ki Elizabeth kọkọ tọ awọn ojuse to wa niwaju rẹ wo. O kọ ọ silẹ nigba to ya pe, oun ri iriri naa gẹgẹ bii "ohun to ya ni lẹnu pupọ, pupọ".

Ọba tuntun to sẹsẹ gba ade, Ọba George Kẹfa ati Ọmọọbabinrin Elizabeth pẹlu aburo rẹ, Margret.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọmọọbabinrin Elizabeth, pẹlu awọn obi rẹ ati aburo rẹ obinrin, Margaret, lasiko ti igbade baba rẹ jẹ "ohun to ya ni lẹnu pupọ, pupọ".
White Line 1 Pixel

Pẹlu bi ikaya-soke se n gbinlẹ sii ni ilẹ Europe, Ọba tuntun naa, aya rẹ ati Ọmọọbabinrin Elizabeth bẹrẹ igbesẹ lati mu ki igbagbọ awọn araalu ninu Ọba yii gbopọn sii. Apẹrẹ rere ti wọn n fi lelẹ yii ko si sọnu lara akọbi wọn.

Lọdun 1939, Ọmọọbabinrin ọmọ ọdun mẹtala naa, kọwọ rin pẹlu Ọba ati Ayaba lọ si ile ẹkọ ọmọ ogun oju omi, ti wọn pe ni Royal Naval College, to wa ni ilu Dartmouth.

Ọkan lara awọn ipẹẹrẹ ọmọ ogun oju omi naa, to tun jẹ ibatan rẹ, Ọmọọba Philip ti ilẹ Greece, lo se ẹsọ fun Ọbabìnrin Elizabeth ati aburo rẹ, Margaret, lẹnu abẹwo naa.

Awọn Ipenija

Kii se igba akọkọ ti wọn yoo foju kan ara wọn niyi, amọ, igba akọkọ ree ti Elizabeth yoo fi ifẹ han si.

Ọmọọba Philip wa se abẹwo si awọn ibatan rẹ lasiko isinmi rẹ lẹnu isẹ ologun oju omi - nigba ti yoo si fi di ọdun 1944, ti Elizabeth di ẹni ọdun mejidinlogun, o ti han gbangba pe ifẹ Ọmọọba Philip ti gbinlẹ lookan aya rẹ. O fi aworan rẹ pamọ sinu yara rẹ, ti wọn si maa n fi iwe sọwọ si ara wọn.

Nigba to ku diẹ ki ogun pari, Ọmọbabinrin naa dara pọ mọ ẹgbẹ olurannilọwọ kan, ti wọn n pe ni Auxiliary Territorial Service (ATS), to si n kọ nipa ọkọ wiwa ati itọju ọkọ akẹru.

Ọmọọbabinrin Elizabeth se igbeyawo pẹlu Philip Mountbatten

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán, Igbeyawo Ọmọọbabinrin Elizabeth pẹlu Phillip Mountbatten mu ki oju ojọ lẹyin ogun agbaye tubọ dara sii.
White Line 1 Pixel

Ni aisun ayajọ ọjọ ti ogun agbaye pari, taa mọ si VE Day, o dara pọ mọ idile Ọba ni aafin Buckingham, nibi ti ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan peju si lati se ayẹyẹ pe ogun pari nilẹ Europe.

"A bi awọn obi mi boya a lee jade sita lati foju ara wa ri ohun to n sẹlẹ." O mu wa si iranti lẹyin-o-rẹyin. " Mo ranti pe ẹru n ba wa, ki wọn ma baa da wa mọ. Mo ranti ọpọ eeyan, ti wọn to lọwọọwọ, ti wọn fi ọwọ kọ ọwọ, ti wọn n rin lọ si isalẹ Whitehall, gbogbo wa kan n wọ tẹle ara wa ni, ninu ayọ ati ibalẹ aya."

Lẹyin ogun agbaye, ifẹ rẹ lati se igbeyawo pẹlu Ọmọọba Philip lo n koju ọpọ ipenija.

Ẹru n ba Ọba lati padanu ọmọ rẹ obinrin to nifẹ bii ẹyin oju, ti Phillip, naa si gbọdọ bori iwa isegbe sibi kan to n waye ni ileesẹ rẹ, ti wọn ko si fẹ fara mọ pe Phillip jẹ ọmọ ilẹ okeere.

Iku baba rẹ

Amọ ifẹ tọkọ̀-taya yii lo papa sẹ, ti wọn si se igbeyawo lọgunjọ, osu kọkanla ọdun 1947 ni Westminster Abbey.

Ọlọla, Duke ti Edinburgh, ti wọn n pe Ọmọọba Phillip bayii, si jẹ osisẹ ọmọogun oju omi sibẹ-sibẹ. Bi o tilẹ jẹ pe fun igba diẹ ni, Bi isẹ si se gbe e lọ si orilẹ-ede Malta tumọ si pe, tọkọ-taya kekere yii lee gbe igbe aye wọn gẹgẹ bii eeyan lasan.

Akọbi wọn, Charles, ni wọn bi lọdun 1948, ti aburo rẹ obinrin, Anne, si tẹle lọdun 1950.

Sugbọn Ọba George Kẹfa, ti wahala ogun agbaye ti da aisan si lara tẹlẹ, ni aisan jẹjẹrẹ ọna ọfun tun n ba finra, nitori aṣa siga amuju fun ọdun gbọọrọ.

Ni osu kinni ọdun 1952, Elizabeth, tii se ẹni ọdun mẹdọgbọn, ati Philip gbera lọ fun irinajo silẹ okeere. Ọba Edward Kẹfa si sin wọn lọ si papakọ ofurufu bi o tilẹ jẹ pe igbesẹ naa tako imọran awọn dokita. Amọ arimọ ni eyi jẹ fun Elizabeth ati baba rẹ, nitori wọn ko pada foju kan ara wọn mọ.

Ọbabìnrin Elizabeth kejì lasiko ayẹyẹ igbade baba rẹ lọjọ keji, osu kẹfa ọdun 1953 ni Westminster Abbey nilu London

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ayẹyẹ igbade Ọba George kẹfa ni akọkọ iru rẹ ti wọn yoo fi han lori mohun-maworan

Elizabeth gbọ nipa iku Ọba George kẹfa lasiko to lọ fun ere idaraya kan lorilẹ-ede Kenya, to si pada si ilu London lọgan gẹgẹ bii Ọbabinrin. To si niran gbogbo isẹlẹ naa pata-pata.

"Ni kukuru, Emi ko kọ́ isẹ yìí rara. Baba mi kere pupọ nigba to fi ku, nitori naa, o dabi ẹnipe mo tete gbera nilẹ, ti mo si fẹ sa ipa mi lati se eyi to dara."

Orilẹede Australia ati New Zealand

Mohun-maworan gbe ayẹyẹ igbade Ọbabìnrin Elizabeth kejì losu kẹfa ọdun 1957, bi o tilẹ jẹ pe Olootu ijọba nigba naa Winston Churchhill tako igbesẹ ọhun, ti ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan si taku si idi mohun-maworan wọn, fun ọpọ wọn, igba akọkọ niyi, ti wọn si n wo Ọbabìnrin Elizabeth kejì to n se ibura.

Ọbabìnrin Elizabeth kejì n sayẹwo awọn ologuin to to lọwọọwọ ni papakọ ofurufu ilu Kaduna ni orilẹ-ede Naijiria lasiko abẹwo si awọn orilẹ-ede to gba ominira lọwọ ijọba ilẹ Gẹẹsi - ni osu keji ọdun 1956

Oríṣun àwòrán, Fox Photos/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọbabìnrin Elizabeth kejì se abẹwo akọkọ si orilẹ-ede Naijiria lọdun 1956, nigba to ku ọdun mẹrin ki orilẹ-ede naa gba ominira.
White Line 1 Pixel

Pẹlu ilẹ Gẹẹsi to sẹsẹ n fara da ọda owo lẹyin ogun agbaye, awọn onwoye ri ayẹyẹ igbade naa bii ibẹrẹ igba ọtun lasiko saa Elizabeth.

Ogun agbaye keji lo tete fopin si agbara isejọba ilẹ Gẹẹsi, nigba ti yoo si fi di igba ti isejọba Ọbabìnrin tuntun yoo gbera sọ, o lọ se abẹwo ọlọjọ gbọọrọn sawọn orilẹ-ede ti ilẹ Gẹẹsi ti mu sin tẹlẹ, losu kọkanla ọdun 1953, sugbọn ọpọ awọn orilẹ-ede yii to jẹ dukia ilẹ Gẹẹsi, to fi mọ orilẹ-ede India, lo ti n gba ominira.

Elizabeth di Ọba akọkọ to wa lori itẹ, ti yoo se abẹwo lọ si orilẹ-ede Australia ati New Zealand. Wọn ni yoo to ida mẹta ninu ida mẹrin awọn eeyan to wa ni orilẹ-ede Australia, to tu yaaya sita lati wa foju se mẹrin Ọba tuntun .

Titi di opin saa ọdun 1950, ọpọ orilẹ-ede lo fa asia ajọse walẹ, tawọn orilẹ-ede ti wọn ti mu sin tẹlẹ si para pọ di mọlẹbi kan soso.

Ọpọ oloselu lo ro pe, ajọsepọ Commonwealth tuntun yii lee tako awujọ isọkan awọn orilẹ-ede nilẹ Europe, to n se ajọsepọ ọrọ aje, ati ni paapa julọ, ofin ijọba ilẹ Gẹẹsi lee kuro lawọn orilẹ-ede naa.

Ikọlu sara ẹni taara ta

Wahala adagun odo Suez to sẹlẹ lọdun 1956 lo tete se okunfa adinku to ba agbara ilẹ Gẹẹsi, nigba to foju han pe, ko si ipinnu ọkan alajumọse lati sisẹ papọ, lasiko ti isoro ba de laarin awọn orilẹ-ede to wa ninu ajọ isọkan Commonwealth.

Ipinnu lati ran awọn ọmọ-ogun ilẹ Gẹẹsi lọ tiraka dena idunkoko orilẹ-ede Egypt, ko ma baa sọ adagun odo Suez di tara rẹ, lo ja si pabo, ti ilẹ Gẹẹsi si yọwọ kuro pẹlu itiju nla, eyi to mu ki Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi nigba naa, Anthony Eden, kọwe fi ipo silẹ.

Isẹlẹ yii lo fa Ọbabìnrin sinu laasigbo oselu. Ẹgbẹ oselu to wa lori aleefa ko setan lati yan olori tuntun mii fun ilẹ Gẹẹsi, amọ lẹyin oniruuru ijiroro, Ọbabìnrin kesi Harold Macmillan lati gbe ijọba tuntun kalẹ.

Bakan naa ni Ọbabinrin tun di ẹni ti Lord Altrincham n koro oju si. Ninu ohun to kọ sinu iwe iroyin atigba-degba kan, O ni gbagede igbẹjọ Ọbabinrin naa ‘faramọ̀ asa ilẹ Gẹẹsi pupọ’ to si ‘tun jẹ tawọn ọlọla’. O tun fi ẹsun kan Ọbabinrin p,e ko lee sọrọ ranpẹ lai jẹ pe o wa ni akọsilẹ.

Awọn ọrọ yii lo fa awuye-wuye lawọn oju ewe iwe iroyin, tawọn ọmọ ẹgbẹ to n se atilẹyin fun idile Ọba, ti wọn n pe ni League of Empire Loyalists, si kọlu Lord Altrincham.

Sibẹ-sibẹ, isẹlẹ yii safihan pe, iyipada nla lo n ba iha ti awujọ ilẹ Gẹẹsi kọ si ipo ọba, ti wọn si n tako o nipa awọn asa atijọ rẹ.

Lati ‘ori itẹ ọba’ de ‘idile ọba’

Awọn ilana tuntun bẹrẹ si ni mọ Ọbabinrin lara lati ipasẹ iwuri to n ri lati ọdọ ọkọ rẹ, ẹni ti wọn mọ daada pe, ko ni suuru rara to ba di tawọn isẹlẹ to nii se pẹlu gbogbo ohun to ba jẹ mọ ilana isejọba.

Asa ki wọn tẹwọgba awọn majesin to sẹsẹ n di omida ni gbagede aafin, ni wọn tun wọgile pata-pata, bẹẹ ni wọn tun pa ede "Alasẹ ilu" da diẹ-diẹ si "Idile Ọba"

Ọbabinrin pẹlu Harold Macmillan

Oríṣun àwòrán, Terry Disney/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bi Harold Macmillan se kọwe fi ipo silẹ tun mu akọtun laasigbo mii lọwọ

Lẹẹkan sii, Ọbabinrin tun bọ si aarin gbun-gbun laasigbo oselu lọdun 1963, nigbati Harold Macmillan yẹba gẹgẹ bii olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi.

Akoko yii le koko pupọ fun Ọbabinrin, o jẹ ami nla fun ẹni ti saa rẹ lori aleefa kun fun ibọwọ fun ofin, eyi to tun mu ki ipo alasẹ ilu tubọ ta kete si ilana ijọba igba naa.

Ọbabinrin ko fi ẹtọ to ni lati mọ ohun to n lọ sere rara, to fi mọ ẹtọ lati gbe imọran kalẹ, ko si tun se ikilọ - sugbọn kii wa lati gbe igbesẹ kọja awọn ojuse yii.

O si fẹrẹ jẹ pe, igba to kẹyin ree ti wọn yoo fi sinu ipo yii. Lẹyin-lẹyin o rẹyin ni ẹgbẹ oselu to wa lode wa pa asa ki asaaju ẹgbẹ tuntun maa sẹsẹ "foju han" ti, ti wọn si fi se agbekalẹ ilana isejọba to yẹ.

Akoko Igbafẹ

Nigba ti yoo fi wọ ọdun 1960 siwaju, aafin Buckingham ti pinnu pe oun nilo lati gbe igbesẹ to yẹ, lati se afihan idile Ọba bii eyi ti ko ta kete si araalu, to si rọrun lati tọ lọ.

Abajade igbesẹ yii lo se okunfa akọjọpọ ẹkunrẹrẹ otitọ ọrọ nipa idile Ọba, eyi to milẹ titi, ti wọn si pe akọle rẹ ni "Idile Ọba". Wọn gba ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC laaye lati ya aworan ile ọba to wa ni Windsor. Wọn ri awọn aworan nibiti idile Ọba ti n se apejẹ ati ibi ti idile Ọba naa ti n to ẹsọ mọ ara igi keresimesi, ibiti wọn ti n wa awọn ọmọ jade ninu ọkọ ayọkẹlẹ - Awọn isẹlẹ yii dabi nkan lasan ti ko fi bẹẹ se pataki sugbọn araalu ko ri wọn ri tẹlẹ.

Awọn eeyan kan to n se ariwisi ni, fidio ti Richard Cawston se jade naa, ti ba adiitu ati ẹwa itẹ ati ori ade jẹ, pẹlu bo se se afihan idile Ọba gẹgẹ bii ẹnipe eeyan lasan ni wọn, to fi mọ awọn aworan ibiti Ọlọla Duke ti Edinburgh ti n se ipanu ni ori ilẹẹlẹ ni Balmoral.

Abala kan lara fidio Idile Ọba
Àkọlé àwòrán, Ẹkunrẹrẹ Fidio ti wọn pe ni ‘Idile Ọba’ lo se afihan oju ati iwa awọn idile Ọba tawọn araalu ko tii ri ri, eyi ti ko sẹlẹ ri.

Sugbọn fidio yii lo n fọn rere ipo gbẹfẹ ti idile Ọba wa ni igba naa, to si ko ipa to pọ lati da atilẹyin tawọn araalu ni ninu idile Ọba pada.

Nigba ti yoo fi di ọdun 1977, tara-tara lawọn araalu fi kopa ninu ayẹyẹ ọdun kẹẹdọgbọn ti Ọbabinrin Elizabeth keji gun ori itẹ, ti awẹjẹ-wẹmu si n waye loju popo, ati lawọn apejẹ to n waye jake-jado ẹkun isejọba naa. O dabi ẹni pe ọkan idile Ọba balẹ ninu iwa ifẹ tawọn eeyan fi han si wọn yii, eyi ti ọpọ rẹ lọ si ọdọ Ọbabinrin gan-gan.

Lẹyin ọdun meji, Ilẹ Gẹẹsi ni obinrin akọkọ ti yoo jẹ olootu ijọba ni ilẹ naa, eyiun Margaret Thatcher. Sugbọn o dabi ẹni pe ibasepọ laarin obinrin akọkọ to jẹ olori ijọba pẹlu obinrin to jẹ olori orilẹede, ni ko fi bẹẹ dan mọran.

Isẹlẹ Ibanilorukọjẹ ati Ajalu buruku

Isẹlẹ kan to le koko, ni bi Ọbabinrin se gbajumọ ajọ Common wealth, eyi to jẹ olori fun. Ọbabìnrin Elizabeth kejì mọ awọn asaaju orilẹede Africa daada, ti kii si fi ọrọ wọn se awẹwa.

A gbọ pe Ọbabìnrin ri ihuwasi ati ilana isejọ̀ba ọyaju ti Thatcher n se, gẹgẹ bii iwa to n kọ ni lominu, paapa atako ti Olootu ijọba n se si fifi ofin de ijọba ẹlẹya-mẹya ni orilẹede South Afrika.

Aarọ ọjọ keji ti isẹlẹ ina waye ni ile ọla Windsor.

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán, Ijanba ina to waye ni ile ọla to wa ni Windsor tun da kun akọsilẹ '"ọdun to buru" ti Ọbabìnrin ni

Bi ọdun se n gori ọdun, awọn ojuse Ọbabìnrin si araalu si n tẹsiwaju. Lẹyin ogun aarin gbun-gbun agbaye, taa mọ si Gulf War ni ọdun 1991, O lọ si orilẹede Amẹrika, eyi to mu ko di Ọba ilẹ Gẹẹsi akọkọ ti yoo ba ipejọ apapọ awọn asofin sọrọ. Aarẹ Amẹrika nigba naa, George HW Bush ni Ọbabìnrin jẹ " Ololufẹ Alaafia fun igba pipẹ ti awọn lee ranti".

Amọ sa, lẹyin ọdun kan, oniruuru isẹlẹ iwa ibanilorukọjẹ ati ajalu bẹrẹ si ni ipa lori idile Ọba.

Ọmọkunrin keji ti Ọbabìnrin bi, Ọlọla Duke ti York, ati iyawo rẹ, Sarah lọ ni ọtọọtọ, nigbati igbeyawo Ọmọọbabinrin Anne pẹlu Mark Phillip naa fi ori sanpọn. Bakan nii ni afẹfẹ fẹ, taa si ri idi adiẹ pe Ọmọọba ati Ọmọọbabinrin ti Wales naa, ni inu wọn ko dun si ara wọn pupọ, ti wọn si papa tuka lẹyin- o- rẹyin.

Bakan naa tun ni ọdun ọhun pari pẹlu isẹlẹ ina alagbara to waye ni ilegbe ti Ọbabinrin fẹran julọ, eyiun Windsor Castle. O si dabi ẹni pe, ami idamọ ile ọla lo ni isoro yii. Bẹẹ si ni awuye-wuye araalu to tun tẹle isẹlẹ ina yii, eyi to da lori boya owo ori ti ara ilu n san ni ki wọn fi tun ile naa se, abi Ọbabìnrin fun ra rẹ ni ko se atunse ile ọhun, ko seranwọ rara fun Ọbabìnrin lori ajalu to sẹlẹ naa.

Iyi nla ati Ariyan-jiyan ita gba-n-gba

Ọbabìnrin se apejuwe ọdun 1992 gẹgẹ bii "ọdun to buru pupọ", fun oun, ọrọ apilẹkọ rẹ kan ni ilu London lo si dabi ẹni pe, o fara mọ pe, ki wọn se agbekalẹ ilana isejọba oriade to han kedere, nibamu pẹlu agbekalẹ awọn ileesẹ iroyin ti ko ni gbe oju agan.

" Ko si ibudo kan, ilu, Ọba alaye abi ohun-kohun, ti yoo reti lati bọ lọwọ agbeyẹwo finni-finni lati ọdọ awọn eeyan to n se atilẹyin ati otitọ inu sii, ka ma sẹsẹ sọ lati ọdọ awọn eeyan ti ko se atilẹyin fun-un . Amọ ara asọ kan soso ni gbogbo wa ti wa, ara iyawo kan naa si la n to asọ mọ. A jẹ ara asọ fun awujọ wa, ti agbeyẹwo yoo si wulo taa ba fi ẹsọ, ẹsọ se odiwọn rẹ, lati ipasẹ ẹ̀fẹ̀ to dara ati igbọra-ẹni ye."

Ọbabìnrin Elizabeth kejì ati Aarẹ Nelson Mandela n rin lọ si ile asofin orilẹede South Afrika. to wa ni Cape Town. Osu kẹta ọdun 1995.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọbabìnrin Elizabeth kejì se abẹwo si orilẹede South Afrika lọdun 1995, eyiun ọdun ti Nelson Mandela di aarẹ oloselu akọkọ ni orilẹede naa

Ipo ori ade yii lo wa n wa awijare lati raga bo ara rẹ. Aafin Buckingham ni wọn si silẹ fawọn alejo lati ko owo jọ fun atunse ile nla to wa ni Windsor, ti ikede si waye pe, Ọbabinrin ati Ọmọọba ti Wales yoo san owo ori lori awọn owo to ba wọle fun wọn, lati awọn ara idokowo wọn.

Ẹwẹ, nilẹ okeere, ireti nipa ajọ Commonwealth, tobi pupọ ni ibẹrẹ isejọba Ọbabinrin, ti afojusun rẹ lori eyi ko si ti wa si imusẹ. Ilẹ Gẹẹsi si ti kẹyin si awọn alajọsepọ rẹ atijọ nidi ilana tuntun fun ilẹ Europe.

Ọbabinrin si ri ohun to se iyebiye ninu ajọ Commonwealth, ti inu rẹ si dun nipa orilẹede South Afrika, eyi to ti goke agba, lẹyin o rẹyin, o sọ iwa ẹlẹya mẹya si ẹgbẹ kan. Ọbabinrin si fi abẹwo si orilẹede naa safihan idunnu rẹ ninu osu kẹta ọdun 1995.

Ni ile rẹ, Ọbabinrin wa ọna lati ri daju pe, iyi ati ọwọ ti wọn n fun idile ọba ko lọ si okun igbagbe, ti ariyan-jiyan si n tẹsiwaju ni aarin ilu lori boya ọjọ iwaju wa fun ipo ori ade naa.

Iku Diana, Ọmọbabinrin ti Wales

Bi ilẹ Gẹẹsi se n tiraka lati wa ayanmọ tuntun fun ara rẹ, sibẹ Ọbabinrin sa ipa rẹ lati wa ni ipo to duro sin-sin ati ifini-lọkan balẹ fun awọn araalu, ti ẹrin ojiji si lee mu imọlẹ ba akoko naa. ojuse to se iyebiye julọ fun-un ni pe, o jẹ ami idamọ fun orilẹede.

Ọbabinrin ati Ọmọọba Phillip n se ayẹwo awọn ododo tawọn araalu to kalẹ lati sami iku Ọmọọbinrin ti ilu Wales

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán, Ọbabinrin koju ipenija awọn to n se ariwisi lẹyin iku Diana, Ọmọọbabinrin ti Wales

Sibẹ-sibẹ, jinni-jinni bo idile Ọba, ti ọpọ ariwisi ti kii saba waye si n wa sori Ọbabinrin funra rẹ lẹyin iku Diana, Ọmọọba-binrin ilu Wales, eyi to waye lati ipasẹ ijanba ọkọ ayọkẹlẹ kan ni ilu Paris, ninu osu kẹjọ ọdun 1997.

Bi awọn araalu se ya bo aafin naa ni ilu London pẹlu obiti-biti ododo, o nira fun Ọbabinrin diẹ lati pese imulọkanle to maa n tiraka lati se lasiko awọn akoko to se pataki ni orilẹede naa.

Ọpọ awọn to n na ika aleebu si Ọbabinrin lo kuna lati loye pe, o wa lati iran ti akọ igi wọn kii tete se oje, ti wọn kii si tete se afihan idaamu ọkan ti wọn ba n la kọja, paapaa, lasiko ti awọn ara ilu ba n safihan ẹdun kan wọn, nigba ti ajalu nla ba ba ilu, gẹgẹ bo se waye lẹyin iku Diana.

Bakan naa lo ri ara rẹ gẹgẹ bii iya agba to ni ifẹ, to si ni ojuse lati tu awọn ọmọkunrin Diana ninu ni kọrọ yara idile wọn.

Lẹyin o rẹyin, Ọbabinrin ba awọn araalu sọrọ, to si n kọrin rere ki aya ọmọ rẹ to di oloogbe, bẹẹ lo tun n fọwọ sọya pe, idile ọba yoo la ipo naa kọja laisi wahala.

Awọn akoko Adanu ati Idunnu

Iku iya Ọbabinrin ati aburo rẹ, Ọmọọbabinrin Margaret, to bọ si asiko ti Ọbabinrin n se ajọdun aadọta ọdun to de ori itẹ ni ọdun 2002, tun mu ki kuru-kuru raga bo ilẹ Gẹẹsi, lasiko awọn ayẹyẹ ti wọn fi n sami isejọba rẹ.

Sugbọn lai naani isẹlẹ yii, ati ariyan-jiyan to tun suyọ lori ọjọ ọla ipo ori ade naa, sibẹ miliọnu kan eeyan lo tun ya wa si gbagede igbalejo to wa ni iwaju aafin Buckingham ti wọn n pe ni The Mall, ni irọlẹ ọjọ ayẹyẹ aadọta ọdun ti Ọbabinrin gori itẹ awọn baba nla rẹ naa.

Ọbabinrin Elizabeth keji n gba ododo lowọ ololufẹ idile Ọba kan, Terry Hutt, niwaju ile ijọsin Paulu Mimọ to wa ni ilu London, lẹyin akanse isin idupẹ lati sami ọjọ ibi ọgọrin ọdun rẹ

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán, Ifẹ ti araalu ni si Ọbabinrin ko yin jẹ rara

Ni osu kẹrin ọdun 2006, ẹgbẹlẹgbẹ awọn afẹnifẹre lo ya bo awọn oju popo nilu Windsor, lasiko ti Ọbabinrin seto irin rinrin kan ti wọn ko kede rẹ tẹlẹ, eyi ti wọn fi sami ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun rẹ.

Ninu osu kọkanla ọdun 2007, Ọbabinrin ati ọkọ rẹ, Ọmọọba Philip, sami ayẹyẹ ọgọta ọdun ti wọn se igbeyawo pẹlu akanse isin idupẹ kan ti eeyan bii igba peju si, ile ijọsin Westminster Abbey si ni isin idupẹ naa ti waye.

Sibẹ akoko ajọdun miran tun waye ni osu kẹrin ọdun 2011, nigba ti Ọbabinrin bawọn peju si ibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọ-ọmọ rẹ, William, tii se Ọlọla Duke ti Cambridge ati aya rẹ, Catherine Middleton.

Ni osu karun-un ọdun naa, Ọbabinrin di ori ade akọkọ ti yoo se abẹwo si orilẹede olominira Ireland, eyi tii se ayẹyẹ pataki to jẹ manigbagbe.

Ninu ọrọ rẹ, eyi to bẹrẹ pẹlu ede Irish, Ọbabinrin bẹbẹ fun ipamọra ati inu rere pẹlu ifọwọsowọpọ, eyi to pe akori wọn ni " awọn nkan ti a ti se lọtọọtọ tabi ti a ko se rara."

Idibo lati mọ ero araalu

Lẹyin ọdun kan, lasiko to se abẹwo si orilẹede Northern Ireland, gẹgẹ bii ara ayẹyẹ to fi n sami ọjọ ibi ọdun karundinlọgọrin rẹ, o bọ ọwọ pẹlu oludari ikọ ọlọtẹ IRA tẹlẹ, Martin McGuinness.

Akoko pataki ni eyi jẹ fun idile ọba, ẹni ti ibatan ọkọ rẹ kan to nifẹ si pupọ, Ọlọla Louis Mountbatten, se alaisi lati ipasẹ ado oloro ti ikọ ọlọtẹ IRA yin ni ọdun 1979.

Martin McGuinness n bọ Ọbabìnrin lọwọ

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán, Bi Ọbabìnrin se bọ Martin McGuinness lọwọ lo wa lati se iranwọ ki egbo atijọ lee tete jinna

Ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun karundinlọgọrin Ọbabìnrin lo mu ki omilẹgbẹ eeyan ya si oju popo, eyi to mu ko di opin ọsẹ ọlọpọ ayẹyẹ ni ilu London.

Eto idibo lati mọ ero araalu lori ominira ilẹ Scotland losu kẹsan ọdun 2014, jẹ akoko idanwo fun Ọbabìnrin. Ọpọ ni ko ranti ọrọ apilẹkọ Ọbabìnrin mọ ni ile asofin lọdun 1977, nibi to fi tẹ pẹpẹ ojuse rẹ si United Kingdom.

"Mo ka ikọọkan awọn ọba ati ayaba to wa lati ilẹ gẹẹsi ati ni Scotland, ati awọn ọmọọba to wa lati Wales laarin awọn baba ati iya nla mi, eyi to mu ki ilakaka yii ye mi yeke. Sugbọn wọn de mi ni ade gẹgẹ bii Ọbabìnrin ti United Kingdom ni orilẹede Great Britain ati Northern Ireland"

Ninu ọrọ rẹ sawọn afẹnifẹre ni Balmoral, ni aisun ọjọ idibo lati mọ ero araalu naa ni Scotland, eyi ti wọn hu gbọ, Ọbabìnrin ni, oun lero pe awọn eeyan yoo ronu daada nipa ọjọ iwaju.

Ni kete ti wọn mọ esi ibo naa, Ọrọ to sọ sita fun araalu se afihan itura to ni pe, ajọsepọ naa si wa digbin, bi o tilẹ jẹ pe o mọ pe ilana eto oselu ti yi pada.

Ọbabìnrin Elizabeth kejì. Yousuf Karsh lo ya aworan yii lọdun 1966

Oríṣun àwòrán, Yousuf Karsh / Camera Press

White Line 1 Pixel

" Ni bayii, baa se n tẹ siwaju, o yẹ ka ranti pe bi o tilẹ jẹ pe oniruuru ero ni wọn ti se afihan rẹ, a ni ohun kan lapapọ eyiti i se ifẹ pipe, to si tọjọ fun ilẹ Scotland, eyi to jẹ ara nkan to se iranwọ lati se gbogbo wa ni ọkan."

Ni ọjọ kẹsan, osu kẹsan-an ọdun 2015, Ọbabìnrin di Ọba to tii pẹ lori oye julọ ninu itan ilẹ Gẹẹsi, to si pẹ lori itẹ ju iya iya iya baba rẹ lọ, eyiun Ọbabìnrin Victoria lọ. Gẹgẹ bii abuda rẹ, o kọ lati se yanga pe oye naa, " kii se eyi ti oun ko foju sun rara"

Ko to ọdun kan lẹyin eyi, ninu osu kẹrin ọdun 2016, o se ayẹyẹ aadọrun ọjọ ibi rẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe, ipo ọba lee ma lowura mọ lẹyin saa isejọba Ọbabìnrin Elizabeth keji gẹgẹ bo se ri ni ibẹrẹ isejọba rẹ, sibẹ, o pinnu pe oun yoo maa tẹsiwaju lati gba ipo ọwọ ati ifẹ ni ookan aya awọn eeyan ilẹ Gẹẹsi.

Nigba ayẹyẹ ọdun kẹẹdọgbọn to gun ori itẹ awọn baba nla rẹ, Ọbabìnrin ranti ẹjẹ to jẹ lati se abẹwo si orilẹede South Africa ni ọgbọn ọdun sẹyin.

" Ni igba ti mo wa ni ẹni ọdun mọkanlelogun, mo seleri lati fi ara mi jin fun isisẹ sin awọn eeyan wa, mo si bẹbẹ fun iranlọwọ Ọlọrun lati se amusẹ ileri naa. Bi o tilẹ jẹ pe aye igba ti ara dẹ mi, ti idajọ sise si jẹ ajeji si mi ni mo jẹjẹ naa, emi ko kabamọ rara tabi ko ikankan ninu ọrọ mi naa jẹ",