Ọ̀pọ̀ èrò ya bo ààfin Buckingham láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Ọbabìnrin Elizabeth

Iwaju aafin Buckingham

Bi ilẹ se n su ni aafin Buckingham. Se ni awọn obitibiti ero n pe jọ pọ siwaju aafin naa.

Awọn eeyan naa lo si wa lati se asaro lori iku Ọbabinrin Elizabeth.

Awọn ọdọ ati arugbo si lo n tiraka lati de awọn ẹnu ọna aafin naa lati gbe ododo kalẹ sibẹ.

Debbie Thomas to wa lati South Shields lo wa ni London nigba ti ikede iku Ọbabinrin Elizabeth naa waye.

O ni “Ọmọkunrin mi lo pe wa lori foonu pe Ọbabinrin ti jade laye, iroyin naa ba wa lojiji, ta si wa sibi lati wa se ẹyẹ ikẹyin fun Ọbabinrin.

Debbie, tii se ẹni aadọta ọdun fikun pe “Ọbabinrin to kanka ni Elizabeth lati aadọrin ọdun o le diẹ, n ko tiẹ le gbagbọ pe eyi ri bẹẹ.

Bi wọn se n tan ina alẹ ni aafin Buckingham , se ni awọn eeyan pariwo, ti wọn si n patẹwọ.

Awọn eeyan naa, ti ori wọn da bi omi, lo n wa, ti wọn si n pọ si lakoko naa.