The Queen of England: Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sínsin ẹṣin àti eré ìdíje ẹṣin

Oríṣun àwòrán, UK press via Getty
Ohun kan pàtàkì tí ènìyàn máa kọ́kọ́ ṣe àkíyèsí tó bá kọ́kọ́ wọ ibi tí Ọbabìnrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti máa ń sinmi, ni àwọn ère ẹṣin tàwọn eré ìdárayá ìdíje racehorse Estimate.
Ère ẹṣin tó wà ní Sandringham fìdí ìfẹ́ tí Ọbabìnrin náà ní sí eré ìje ti ẹṣin, eré ìdárayá tó máa ń ṣàfihàn díẹ̀ nínú bí ìgbésí ayé ẹni tó bá wà lórí oyè Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe rí.
Nígbà tó gba àmì ẹ̀yẹ wúrà ninu idije Estimate níbi ìdíje Royal Ascot lọ́dún 2013, ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ọba tó wà lórí ìtẹ́ yóò gbégbá orókè nínú ìdíje náà, láti igba ọdún lé méje sẹ́yìn.
Àwòrán àti fídíò ṣàfihàn bí Ọbabìnrin náà ṣe ń fi ìdùnnú rẹ̀ hàn pẹ̀lú bí alákoso rẹ̀ ṣe wà pẹ̀lú rẹ̀.
"Nígbà tí èsì ìdíje bá wáyé báyìí, ó túmọ̀ sí òpin ìrìnàjò tó pegedé."
Bíborí ìdíje Estimate wà lára àwọn àmì ẹ̀yẹ tó le ní ẹgbẹ̀sán àwọn ìdíje tí Ọbabìnrin borí nínú àwọn ìdíje àwọ̀ Purple, wúrà ati scarlet.
Bákan náà ni àwọn ipa takuntakun tí Ọbabìnrin tó wàjà kó sí eré ìje eré sísá ẹlẹṣin, gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń sin ẹṣin fúnra rẹ̀, èyí tí wọ́n fi gbà á wọlé sínú Hall of Fame àwọn tó ti gbégbá orókè nilẹ̀ Britain lọ́dún 2021.
Gígun ẹṣin fún Ọbabìnrin kọjá ṣíṣe òwò ẹṣin lásán tàbí ohun ìṣeré.
Ẹni tó máa ń kọ Ọbabìnrin ní ẹṣin gígùn, Richard Hannon ní Ọbabìnrin máa ń sọ fún òun wí pé ó máa ń dún mọ̀ òun láti máa wá sí ibi tí kò rùn fún èémí ọ̀dà tuntun.
Hannon ní ìwé ìròyìn nípa eré ìdárayá ní eré ìje ẹṣin máa ń wà lọ́wọ́ Ọbabìnrin ní gbogbo ìgbà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹṣin wà lára àwọn ohun tí Ọbabìnrin Elizabeth dàgbà láti máa fẹ́ràn. Ẹṣin Shetland Pony èyí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Peggy ni Ọbabìnrin Elizabeth fi kọ ẹṣin gùn.
Bàbá-bàbá rẹ̀, George V ló fun ní ẹṣin náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún mẹ́rin.
Nígbà ogun àgbáyé kejì ni ìfẹ́ rẹ̀ nípa ẹṣin gígùn bẹ̀rẹ̀ nígbà tó tẹ̀lé bàbá rẹ̀ lọ sí ibi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn ẹṣin oyè èyí tó wáyé ní Wiltshire.
Ọbabinrin nígbà kan tó ń sọ̀rọ̀ ní nígbà tí òun fọwọ́ kan àwọn ẹṣin náà, òun kò ì tíì rí kí ara ẹṣin jọ̀lọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí.
Ìgbà àkọ́kọ́ tí Ọbabìnrin yóò kọ́kọ́ kópa níbi ìdíje ẹṣin gígùn ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí ogun parí nínú oṣù karùn—ún, ọdún 1945, nígbà tó tẹ̀lé àwọn òbí rẹ̀ lọ sí Ascot.
Ìpáde àwọn lọ́balọ́ba Ascot ni ó yẹ kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjáde tó tí Ọbabìnrin náà fẹ́ràn júlọ níbi tí wọ́n ti gba àmì ẹ̀yẹ mẹ́rìnlélógún.
Ní ọdọọdún ni Ọbabìnrin máa gúnlẹ̀ síbi ìdíje náà láti ààfin Windsor níbi tí àwọn ènìyàn ti máa ń díje lórí àwọ̀ aṣọ tí Ọbabìnrin náà yóò wọ̀.
Ìdíje àkọ́kọ́ tí Ọbabìnrin yóò kọ́kọ́ gba àmì ẹ̀yẹ lé lórí ni Monaveen ní Fontwell Oark lọ́dún 1949, bákan náà ló sì gbégbá orókè ní ẹ̀ẹ̀mèjì níbí ìdíje àwọn tó ní ẹṣin ní Britain lọ́dún 1954 àti 1957.
Clare Blading ẹni tí Bàbábàbá, bàbá àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti bá Ọbabìnrin ṣe ìtọ́jú ẹṣin ní kété tí Ọbabìnrin bá ti rí àwọn ẹṣin rẹ̀ ló ti mọ àwọn èyí tó jẹ́ tirẹ̀.
Blading ní Ọbabìnrin kìí fi tùràrí sára nígbà tó bá fẹ́ ṣe àbẹ̀wò sínú ọgbà tí àwọn ẹṣin rẹ̀ wà.
"Ọbabìnrin Elizabeth jẹ́ ẹni tó fẹ́ràn láti máa tẹ̀lé Monty Roberys láti kọ́ nípa bó ṣe máa ń mú wọn rìn. Bí àpẹẹrẹ nípa mímú àwọn ẹṣin rìn lórí ike àláwọ̀ sánmọ̀ nítorí kí ẹ̀rù mále bàwọ́n láti rìn lórí omi.
"Èyí sì jẹ́ k;i àwọn ẹṣin náà gbọ́rọ̀, kí wọ́n sì lè hùwà bó ṣe tọ́ nígbà tí wọ́n bá wà níní ọgbà wọn."
Bákan náà ló ní Ọbabìnrin náà máa ń fún àwọn ẹṣin rẹ̀ ní àwọn orúkọ tó ní ìtumọ̀ tó ní ṣe pẹ̀lú iṣẹ́, ìwé òfin àti ọgbọ́n inú rẹ̀."
Ọbabìnrin fi bí agbára rẹ̀ nípa ẹṣin gígùn hàn nígbà tí agbébọn kan yìbọn bà á níbi ìdíje Trooping of the Colour parade lọ́dún 1981.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olùkọ́ni Sir Micheal Stoute, tó ti wo bí àwọn ìdílé Ọba ṣe ti gbégbá orókè nínú ìdíje tó lé ní ọgọ́rùn-ún tó fi mọ́ ìdíje Estimate ní Ọbabìnrin Elizabeth dùn-ún ṣiṣẹ́ fún.
Ó ni gbogbo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí òun ṣe fún Ọbabìnrin Elizabeth ló lọ ní ìrọ̀rùn nítorí òye àti ìmọ̀ rẹ̀ nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ kí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ ìrọ̀rùn fún òun láti ṣe.
"Ó máa ń ronú ṣaájú lórí bí ó ṣe fẹ́ kí àwọn ẹṣin náà rí, bóyá fún eré sísá ni tàbí kìmí tàbí kò le fa ìbínú yọ lójú ìjà.
Lára àwọn tí Ọbabìnrin fẹ́ràn láti máa bá díje ni Frankie Dettori, tí àwọn méjéèjì yóò sì máa fi ara wọn ṣe yẹ̀yẹ́ lẹ́yìn ìdíje kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí Dettori ṣe ṣo lẹ́yìn ìdíje King George VI àti Ọbabìnrin stakes ní Ascot.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní ẹṣin, Ọbabìnrin Elizabeth ló gbégbá orókè ní ẹ̀ẹmẹ̀rin nínú ìdíje British Classic.
Dunfermline ló gbégbá orókè nínú Oaks 1977, ọjọ́ mẹ́ta sí ìgbà tí yóò pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tó sì tún gba àmì St Leger ṣaájú pẹ̀lú Carrozza (Oaks 1957), Pall Mall (2,000 Guinea 1958) àti Highclere (1,000 Guinea 1974).
Àmì ẹ̀yẹ tó tóbi jùlọ, The Derby, ni wọ́n kò rí gbà, ní bó ṣe kù díẹ̀ sí ayẹyẹ ìwúyè rẹ̀ lọ́dún 1953 nígbà tí Aureole gbé ipò kejì sí Pinza gẹ́gẹ́ bí Sir Gordon Richards ṣe gba àmì ẹ̀yẹ ìdíje Epsom fún ìgbà kẹrìndínlọ́gbọ̀n tó gbìyànjú rẹ̀.
Ìgbà mìíràn tí wọ́n tún fẹ́ẹ̀ pàdánù rẹ̀ Ni lọ́dún 2012 nígbà tí Carlton gbé ipò kẹta.
Ìjáwé olúborí ìdíje Estimate ní Ascot lẹ́yìn oṣù méjìlá lẹ́yìn rẹ̀ mú $172,000 wọlé fún Ọbabìnrin Elizabeth lọ́dún náà àmọ́ ọ̀pọ̀ nínú owó náà ni wọ́n fi ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́, oúnjẹ àti àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n nílò fún ìdíje náà.
Warren ni ẹṣin jẹ́ àwọn snà tí àwón le fi fi iṣẹ́ mìíràn sílẹ̀ àti pé àtìlẹyìn tí Ọbabìnrin ṣe fún ìdíje eré sísá ẹṣin mú ìgbélárugẹ bá eré sísá ẹṣin ilẹ̀ Britain.
Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé tí wọn kò bá bí Ọbabìnrin Elizabeth sí ìdílé ọba, ẹṣin sínsìn ni kò bá jẹ́ ọ̀nà iṣẹ́ kan gbòógì tí kò bá mú ṣe ní ìgbé ayé rẹ̀.












