Royal Rebranding: Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn owó, òǹtẹ̀ àti ìwé ìrìnnà tí àwòrán Ọbabìnrin wà?

Òǹtẹ̀ UK

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fún àádọ́rin ọdún lórí àpèrè gẹ́gẹ́ bí Ọba ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì, Ọbabìnrin Elizabeth Keji ti di ọ̀kan lára ohun tí a gbọ́njú mọ̀ ní ìgbé ayé wa.

Rírí àwòrán àti àwọn ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ lára owó, àti ibikíbi jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tí àwọn ènìyàn dàgbà bá tí àyípadà sì lè báwọn báyìí - kí ni àwọn nǹkan tó le yàtọ̀?

Àwọn àyípadà tó le wáyé

Gbogbo owó ẹyọ bílíọ̀nù mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tó wà ní UK báyìí ló ní àwòrán orí Ọbabìnrin Elizabeth nínú.

Èyí tí wọ́n tún ṣẹ̀sẹ̀ ṣe àyípadà sí ní ọdún 2015 nígbà tí Ọbabìnrin náà pé méjìdínláàdọ́rùn-ún ọdún ni ìgbà karùn-ún tí wọ́n ṣe àyípadà àwòrán rẹ̀ lásìkò tó jọba.

Ààfin kò ì tíì sọ ìgbà tí wọ́n yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe tàbí lo owó ẹyọ èyí tí yóò ní àwòrán Ọba Charles Kẹta nínú àmọ́ ohun tó dájú ni wí pé àwọn owó ẹyọ èyí tó ní orí Ọbabìnrin Elizabeth yóò jẹ́ ṣíṣe àmúlò fún ìgbà pípẹ́.

Bákan náà ètò láti pààrọ̀ wọn yóò máa lọ ní díẹ̀díẹ̀.

Owó tí wọn yóò kọ́kọ́ ya àwòrń Ọbabìnrin Elizabeth sí ni lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí wọ́n fi gègé yà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Owó tí wọn yóò kọ́kọ́ ya àwòrń Ọbabìnrin Elizabeth sí ni pọun kan lọ́dún 1960

Saájú kí sísọ gbogbo owó ẹyọ ní Britain tó di ẹyọ̀kan ní ọdún 1971, ó ṣeéṣe láti rí àwọn owó ẹyọ tó ní àwòrán oríṣiríṣi ọba lórí owó.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì mọ bí owó ẹyọ tí yóò ní àwòrán Ọba Charles Kẹta nínú yóò ṣe rí, àwòrán èyí tí wọ́n gbé jáde lọ́dún 2018 láti ṣàmì ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àádọ́rin ọdún rẹ̀ ti ṣàfihàn bí yóò ṣe rí.

Àmọ́ ohun kan tó dájú ni wí pé apá òsì ní àwòrán Ọba Charles Kẹta yóò kọjú sí gẹ́gẹ́ bí òfin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe làá kalẹ̀ wí pé apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kí àwòrán Ọba tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ yàtọ̀ sí èyí tó bá gbésẹ̀.

Owó ẹyọ tí wọ́n kọ́kọ́ ya àwòrán Ọba Charles Kẹta sí láti fi ṣàmì ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ lọ́sún 2018

Oríṣun àwòrán, The Royal Mint

Ní kété tí ìjọba bá ti fọwọ́ si, iléeṣẹ́ tó ń pèsè owó ní Ààfin, Llantrisant, South Wales.

Láti ọdún 1960, gbogbo owó tí wọ́n ń tẹ̀ jáde ní ilé ìfowópamọ́ Bank of England ló ń ní àwòrán Ọbabìnrin Elizabeth nínú (ṣùgbọ́n èyí tí wọ́n ń tẹ̀ jáde ní àwọn ilé ìfowópamọ́ Scotland àti Nothern Irish kò ní àwọn Ọbabìnrin Elizabeth).

Kò dín ní bílíọ̀nù mẹ́rin lé ọwọ́ márùn-ún owó tí ilé ìfowópamọ́ Bank OF England gbé jáde tí iye rẹ̀ tó ọgọ́rin bílíọ̀nù pọ́ùn tó wà ní ìgboro lọ́wọ́ àmọ́ ìrètí wà pé gbogbo rẹ̀ náà yóò tán nílẹ̀.

Gbogbo àwọn owó ẹyọ àti ti pépà ló ṣì wúlò báyìí títí tí Bank of Enland yóò fi ṣe àyípadà sí wọn.

Òǹtẹ̀ lára àwọn ẹrù ìfiránṣẹ́

Láti ọdún 1967, gbogbo àwọn òǹtẹ̀ tó ń wà lára ẹ̀rù tó bá ń jáde láti ààfin ló máa ń ìtàn ìgbésí ayé Ọbabìnrin Elizabeth II ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

Royal Mail yóò ṣe ìdádúró pípèsè àwọn òǹtẹ̀ wọ̀nyí ṣùgbọ́n wọn yóò ṣì máa lò wọ́n lórí ìwé àkọránṣẹ́ àti ẹ̀rù títí tí wọ́n fi máa bẹ̀rẹ̀ láti ṣe àwọn tuntun.

Àwọn òǹtẹ̀ mẹ́fà tí wọ́n gbé jáde lọ́dún 2018 ní orúkọ Ọba Charles ní àyájọ́ ọjọ ìbí àádọ́rùn-ún ọdún

Oríṣun àwòrán, Royal Mail

Àkọlé àwòrán, Àwọn òǹtẹ̀ mẹ́fà tí wọ́n gbé jáde lọ́dún 2018 ní orúkọ Ọba Charles ní àyájọ́ ọjọ ìbí àádọ́rùn-ún ọdún

Ọba Charles kẹta ni àwòrán àti àwọn ìtàn rẹ̀ ti wà lára òǹtẹ̀ rí ṣùgbọ́n Royal Mail kò ì tíì lè kéde bí àtẹ tuntun tí wọ́n yóò gbé jáde lórúkọ rẹ̀ yóò ṣe rí.

As well as putting the monarch on stamps, the Royal Mail puts royal cyphers on many postboxes.

More than 60% of the UK's 115,000 postboxes carry the EIIR mark of Queen Elizabeth II - E for Elizabeth and R for Regina, which means queen. In Scotland, they feature the Scottish crown.

Outside Scotland, any new postboxes will now feature the King's cypher - but as the number of new boxes installed is quite low, it could be some time before you spot one of these.

Àwọn nǹkan tí ààfin ń buwọ́lù fún lílò

Ṣaaju akoko yii awọn ohun elo ile bii igo tomato, paali ounjẹ ati turari ni o ṣeṣe ki o ti ṣalabapade awọn ọntẹ Ọbabinrin pẹlu akọle "pẹlu asẹ Ọbabinrin". Ohun ti eyi tumọ si ni pe aafin Ọbabinrin Elizabeth fun wọn laṣẹlati maa pese wọn ti wọn si n gbe wọn lọ si aafin loorekore.

Àwòrán ìbuwọ́lù lórí ìgò oúnjẹ

Fun ibi ọpọlọpọ ọdun bayii, Ọba, awọn iyawo ati awọn arole ni wọn ti fi ontẹ ti wọn sita leyii to ti sọ awọn naa di oniduro, ni bayii ontẹ ẹẹdẹgbẹrun lati aafin ni ileeṣẹ ẹgbẹrin jẹ anfani rẹ.

Ti oniduro kan ba papoda, lẹyin ọdun meji ni ontẹ to wa lọwọ ileeṣẹ to ba n lo wọn ni ko ni wulo mọ ti awọn ileeṣẹ naa yoo si dẹkun lati ma lo ontẹ ọba naa.

Gbogbo ontẹ ti Charles fi sita gẹgẹ arẹmọ Wales ni yoo tẹsiwaju nigba to ti di ọba bayii.

Ireti wa pe Ọba tuntun yoo gba ọmọ rẹ ati arẹmọ rẹ, Ọmọba Williams laye lati le gbe ontẹ jade.

Iwe irinna si ṣe lo

Kii ṣe owo, ontẹ ati awọn ontẹ nikan ni atunṣe yoo ba.

Gbogbo iwe irinna ti wọn gbe sita ni orukọ Ọbabinrin ni o si ṣe lo lati ṣe irinajo, sugbọn fun awọn iwe irinna tuntun, aworan Ọba tuntun ni yoo wa nibẹ.

Ileeṣẹ Ọlọpaa ni orilẹede Gẹẹsi ati Wales yoo ṣe atunṣe si ami idanimọ to ni aworan Ọbabinrin Elizebeth lara asọ ati fila wọn. Awọn agbẹjọro ti wọn jẹ labẹ iṣejọba Ọbabinrin yoo bọ si abẹ Ọba tuntun lẹsẹkẹsẹ.

Ni ipari, orin orilẹede yoo ni ayipada lati "Ki Ọlọrun dabobo Ọbabinrin".

Lẹyin ti wọn ba kede Charles gẹgẹ bi Ọba tun nibi ayẹyẹ ajọyọ, ikede yoo jade lati aafin St James pe ki orin orilẹ ede naa maa pari pẹlu "Ki Ọlọrun dabo bo Ọba."

Orin orilẹede yoo ri ayipada akọkọ lati ọdun 1952 lẹyin ti wọn fi ọrọ naa kun orin orilẹede.