Ambassadorial Nominee: Ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ti buwọ́luàwọn ọ̀gágun ti ààrẹ Buhari yàn sípò, Olonisakin, Buratai gẹgẹ bi aṣoju Naijiria ni oke okun

Oríṣun àwòrán, NASs
Ile igbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria ti fi aṣẹ si orukọ awọn adari ikọ ọmọogun lorilẹede Naijiria gẹgẹ bi aṣoju Naijiria ni oke okun.
Ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ti buwọ́lu àwọn ọ̀gágun tí ààrẹ Buhari yàn sípò, Olonisakin, Buratai gẹ́gẹ́ bi aṣojú Naijiria ní òkò òkunAwọn ọgagun ti wọn buwọlu naa ni ọgagun Gabriel Olonisakin; ọgagun Tukur Buratai; ọgagun Ibok Ibas ati ̣ọgagun Abubakar Sadique.
Ọgagun Olonisakin ni adari ẹka ileeṣẹ Ologun Naijiria mu tẹlẹ, nigba ti Buratai je adari fun awọn ọmọ ogun ori ilẹ, ti Ibok Ibas si jẹ adari fun ikọ ọmọogun ori omi, ti ọgagun Sadique si jẹ adari tẹlẹ fun ikọ ọmọogun ofurufu.
- Àwọn ǹkan ti a mọ̀ nípa àbùdá tuntun tó wà lára iphone 13
- Auxiliary àtàwọn míì gba ìwé ìyànsípò tuntun gẹ́gẹ́ bí ìjọba ìbílẹ̀ ṣe gba ìṣàkóso àwọn ibùdókọ̀ nípinlẹ̀ Oyo
- Ìtumọ̀ orúkọ ọmọ Banky W àti àwọn ìtàn míràn nípa gbájúgbajà tọkọtaya naa
- Fifi òfin de dída máàlù kiri kò lè dẹ́kun àawọ̀ láàrin àwọn àgbẹ̀ àti darandaran àyàfi... - Fayemi
- Toríi Damilare, mo kara bọ agbo àwọn oní fíìmù, k'óun náà lè gòkè - "Uncle" Mide Funmi Martins
Igbesẹ ile aṣ̣ofin yii waye lẹyin ọjọ marun un ti igbimọ aṣofin lori ọrọ ilẹ okeere ṣe ọfintoto lori wọn lẹyin ti aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari fi orukọ wọn sọwọ si ile aṣofin agba.
Ile igbimọ aṣofin ninu ọrọ wọn ni awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti awọn igbimọ beere awọn ibeere lọwọ wọn to jọ mọ iṣẹ ti wọn ti ṣe tẹlẹri ati awọn ipo ti wọn ti yan wọn si laipẹ yii.
Ijọba orilẹede Naijiria ni fifi orukọ wọn sọwọ si ile igbimọ aṣofin ba ofin orilẹede Naijiria mu ni ti ọdun 1999.
Amọ igbimọ naa ni wipe awọn gba iwe ipẹjọ meji to tako iyansipo wọn, ti wọn si fi ọwọ osi daanu.









