Silas Robotic Engineer: Kò sí ǹkan rere tí ọmọ Nàìjíríà kò lè ṣe

Àkọlé fídíò, Silas Robotic Engineer: Kò sí ǹkan rere tí ọmọ Nàìjíríà kò lè ṣe

O da mi loju pe ọpọlọ awọn ọmọ Naijiria pe- Silas Adekunle

Mi ò lérò pé mo lè di ìlúmọ̀ọ́ká onímọ̀ Rọ́bọ̀ọ̀tì gẹ́gẹ́ bí i ọmọ tíṣà Ọdẹ-Omu

Silas Adekunle, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn ti wọn bi si Ibadan ba BBC sọrọ lori bo ṣe bẹrẹ aye rẹ ko too maa ṣe rọbọọti lagbaye.

Aṣeyọri silas fihan pe ootọ ni ọrọ awọn agba to sọ pe ori lo mọ iṣẹ aṣela ati pe gbogbo ọmọde lo kuku jọn n rin bẹẹ a ko mọ ori olowo.

Ọ̀rọ̀ ìdàgbásókè ìmọ̀ ẹ̀rọ ọ̀dọ́ Nàìjíríà ni mo ṣe padà wálé- Silas Adekunle

Silas ni ẹẹkan pere ni oun de ilu Eko ri ni kekere nitori pe o dabi ilu oyinbo si oun ni Ọdẹ-Omu ni ṣugbọna bayii ko si orilẹ-ede ti wọn ko ti n pee nipa iṣẹ imọ ẹrọ rọbọọti to yan laayo.

Silas Adekunle gba awọn ọdọ Naijiria ni imọran lati ma bẹru ọjọ ọla ṣugbọn ki wọn tẹpa mọ iṣẹ wọn nitori pe atẹlẹwọ ẹni ni awọn agba ni kìí tan ẹni jẹ.