Ìjàmbá bàálú Cuba; Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí sọnú ní Havana

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkọ ofurufu kan to gbe eniyan to le ni ẹgbẹrun ti jabọ to si gbana, lẹyin to gbera kuro ni papakọ ofurufu to wa ni Havana, lorilẹede Cuba.
Aarẹ orilẹede Cuba, Miguel Diaz-Canel, to wa nibi isẹlẹ naa sọ wi pe, o seese ki ọgọọrọ eniyan segbe sinu ijamba ọkọ ofurufu naa.
Amọ, wọn ko i ti sọ iye eniyan to ku sinu ijamba naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iwe iroyin ẹgbẹ oselu kan lorilẹede Cuba fi lede wipe, eniyan mẹta lo bo ninu ijamba naa, ti wọn si wa ni ile iwosan, nibi ti wọn ti n gba itọju pajawiri.








