Yorùbá tone mark: Fífi àmì ohùn sí orí ọ̀rọ̀ Yorùbá ṣe pàtàkì
Ede olóhùn ni èdè Yoruba jẹ.
Ọrọ kan ṣoṣo le ni itumọ mẹfa ṣugbọn ami ohun ori rẹ lo maa ṣafihan irufẹ itumọ to yẹ ki ọrọ naa ni.
Nitori pe BBC Yoruba ko fẹ ki ede Yoruba parun ni aṣe jade lọ beere ami ori ọrọ Konko-jabele lọwọ awọn eniyan.
Awọn ọkunrin lo gbiyanju julọ ninu idahun wọn lasiko ti BBC Yoruba jade lọ beere idahun naa
Wọn fihan pe awọn ko gbagbe ede Yoruba ti wọn ti kọ.
Ẹyin naa ẹ gbiyanju rẹ wo!
Idahun si ibeere naa ni: Kó ń kó-jabele eyi to jẹ: mi mi mi re re re
Ede Yoruba ko ni parun o!