Wo nǹkan tí Sanyeri, Kamilu àti àwọn akẹẹgbẹ́ Sisi Quadri sọ nípa rẹ̀ níbi àdúrà Fidau

Aworan

Ogunlọgọ awọn eeyan lo peju si eto adura ọjọ kẹjọ, oṣere tiata, Tolani Oyebamiji, ẹni ti ọpọ mọ si Sisi Quadri niluu Iwo nipinlẹ Osun.

Bakan naa ni awọn oṣere tiata naa peju si bi eto adura naa lati bu ọla ikẹyin fun akẹgbẹ wọn to jade laye ni ọsẹ to kọja.

Iku Oyebamiji, Sisi Quadri ṣi n ṣe ọpọ awọn ololufẹ rẹ paapa awọn akẹgbẹ ti wọn jọ n sisẹ bi iran ati ala.

Kaakiri oju opo ayelujara lawọn eeyan ti n beere pe ki lo ṣokunfa iku rẹ ati pe ipo wo ni o wa ti ọlọjọ fi de baa.

Ninu ọrọ rẹ, Olaniyi Afonja ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Sanyeri ni ọmọluabi ati olotitọ eeyan ní Sisi Quadri jẹ, to si tun jẹ akikanju lẹnu isẹ gẹgẹ bii oṣere tiata.

Sanyeri rọ gbogbo eeyan paapa awọn ọmọ ẹgbẹ osere tiata lati kọ iwa rere lara oloogbe Sisi Quadri.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ ẹbi, ara ati gbogbo ẹgbẹ osere tiata lapapọ pe wọn ku ara fera ku ati pe ọdun yoo jinna sira.

Gomina fun ẹgbẹ osere TAMPAN ni Ipinlẹ Osun Maruf Olayiwola sọrọ lori iku sisi Quadri, o ni iku oloogbe naa jẹ iyalenu pupọ fun ohun ati fun gbogbo ẹgbẹ TAMPAN nipinlẹ Osun.

Olayiwola tun sọ ninu ọrọ wi pe, Aarẹ ẹgbẹ osere TAMPAN Bolaji Amusan eni tí gbogbo eeyan mọ sì Mr Latin, ti se eto fun eto ilera fun awọn ọmọ ẹgbẹ kọkan ní nipínlẹ kowa wọn.

Aworan

Bose Akinola, eni to jẹ Gomina ẹgbẹ osere tiata TAMPAN ti ipinlẹ Oyo ba BBC Yoruba sọrọ lori iru eeyan ti Tolani Oyebamiji jẹ.

Akinola ni Sisi Quadri jẹ ẹni to ko eeyan mọra ati eni to nI ItẹrIba fun ọpọlọpọ eeyan, paapa julọ ninu ẹgbẹ osere tiata.

O ni ijalu nla ni iku sisi Quadri jẹ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ osere tiata ati fun ẹbi, ara ati ilu Iwo lapapọ.

Bakan naa lo gba gbogbo ọmọ ẹgbẹ osere tiata ni imọran lati ma se ayẹwo ara wọn daada ati lati ma wa isinmi fun ara wọn.

O wa jẹ ki o di mimọ pe ẹgbẹ TAMPAM ko ní fi ẹbi oloogbe sisi Quadri silẹ ati wipe, awọn yoo se ohun kan pataki lorukọ Oloogbe Sisi Quadri.

N ko ti gbagbọ pe Sisi Quadri ti ku, o si da bi ala - Abiola Fowosere

Aworan Abiola Fowosere

Abiola Fowosere ẹni ti oun naa jẹ ọkan lara ọwọ ọtun oloogbe Sisi Quadri, naa tí sọrọ nipa iru eeyan tí oloogbe Sisi Quadri jẹ.

Fowosere ni eeyan ti o ní ifẹ ẹbi, ọrẹ ati gbogbo eeyan ni oloogbe naa jẹ.

“Sisi Quadri jẹ ẹni to ma toju ara rẹ gidigidi, bẹẹ si ni ki fi ara ẹlòmíràn sere rara.”

O ní oun ko tí gba wi pe Sisi Quadri ti ku nitori bi ala lo si jẹ ni oju oun bayi.

Gbogbo ọrọ yii lo waye ni Adura ọjọ Kẹjọ oloogbe Tolani Oyebamiji ẹni ti gbogbo eeyan mọ sí Sisi Quadri loni ọjọ Kẹsàn-án osu Kẹta ọdun 2024.

Aworan