Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Kwasu mẹ́rin bínú lu akẹẹgbẹ́ wọn pa nítorí pé o ya àwòrán wọn

Awọn akẹkọo fasiti ipinlẹ Kwara,Kwara, KWASU, mẹrin kan,ni wọn ti fẹsun kan pe wọn lu akẹẹgbẹ́ wọn kan pa.
Wọn ni awọn akẹkọo yi lu akẹgbẹẹ wọn ọhun nitori pe ko gba iyọnda ko to bẹrẹ si ni ya fọnran lati gba ohun wọn silẹ.
A gbọ pe o ṣe diẹ ti iṣẹlẹ naa waye ṣugbọn awọn alaṣe ṣẹṣe gbe igbesẹ lori rẹ ni.
Iṣẹlẹ lilu akẹgbẹẹ wọn yi waye ni ọkan lara awọn ibugbe akẹkọo to wa nita ọgba ile ẹkọ naa.
Saadat Bola Aliyu to jẹ alukoro fasiti naa fidi iṣẹlẹ yi mulẹ fun BBC.
Ṣugbọn ko darukọ awọn akẹkọo yi tabi orukọ ẹni ti wọn lu doju iku.
Bawo lo ṣe di ọrọ a n lu ara ẹni doju iku?
Ohun taa gbọ ni pe akẹkọọ ti wọn ṣeku pa yi n gba ọrọ ẹnu awọn akẹẹgbẹ rẹ silẹ, toto si tun n ya fidio wọn lai ṣe pe wọn mọ si i.
Nigba ti ọkan ninu wọn ri nnkan to n ṣe lo ta awọn iyoku lolobo.
Lẹyin igba naa ni wọn sun mọ ọ, ti wọn si beere pe kilode to fi n gba ohun awọn silẹ.
Ko ri alaye kan pato ṣe fun wọn lo ṣokunfa ti awọn mẹrin yii fi bẹrẹ si ni da bantẹ iya fun un.
Lilu yi pọ debi pe wọn ni akẹkọọ naa daku mọ wọn lọwọ.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Toun Ejire Adeyemi, fidi ọrọ yi mulẹ fawọn akọroyin to kan si lori foonu nirọlẹ Ọjọbọ.
O sọ pe afurasi mẹrin lawọn taa n wi yi ṣugbọn mi oun ko le fidi ọrọ mulẹ nipa orukọ wọn.
Bakan naa lo sọ pe iwadii si n tẹsiwaju lori ọrọ naa.
BBC ko le fidi ọrọ mulẹ lori akoko ati ibi ti akẹkọọ yii fi gbẹmi mi.












