Wo ọ̀nà tó lè fí ṣe ìtọ́jú ara rẹ̀ lásìkò ààwẹ̀ Ramadan tó wọlé yìí

Aworan musulumi to tẹwo adura

Oríṣun àwòrán, Getty

Lasiko oṣu Ramadan ọpọ musulumi lagbaye lo maa n kopa ninu aawẹ gbigba.

Eyi tunmọ si pe wọn yoo yago fun jijẹ ati mimu lasiko ti al fajari ba ti yọ titi ti oorun yoo fi wọ.

Lati ri pe aawẹ yi lọ ni irọwọrọsẹ, o ṣe pataki lati ṣo nkan ti wa jẹ ṣaaju ati lasiko igba ti o ba n gba aawẹ.

Ohun to dara ni ki a jẹ ounjẹ ti yoo fun ara lokun lasiko saari tii ṣe ounjẹ afẹmọju.

Nigba ti eeyan yoo ba si tun ṣinu, o ṣe pataki lati jẹ awọn ounjẹ ti yoo fun ara lokun ki a si yago fun ounjẹ to ba ni iyọ pupọ.

Ohun o yẹ ka mojuto

Awọn ti ko ba ni ipenija ilera, aawẹ gbigba kii ṣaba jẹ isoro fun wọn.

Amọ awọn to ba ni ailera kan tabi omiran ti wọn koju, aawẹ le fẹ mu inira diẹ ba wọn.

Tori pe aawẹ gbigba a maa lapa lara ifunpa eeyan paapa awọn to ba ni aarun itọ ṣuga,o le lewu diẹ fun wọn lati gba aawẹ.

Tori naa o ṣe pataki ki awọn musulumi to ba ni aisan itọ ṣuga lara ki wọn kan si dokita ṣaaju ki wọn to gunle aawẹ gbigba.

Awọn eeyan kan wa to ṣepe kii pe rẹ ara wọn ti wọn ba ti ṣe wahala diẹ.

Ori fifọ ati ọkan rinrin a tun maa ba awọn miran finra lọsan aawẹ.

Eleyi ni ṣe pẹlu awọn ti wọn ba kọ lati jẹ ounjẹ saari.

O ṣe pataki lati tọju ounjẹ taa ba jẹ nigbakugba amọ eleyi taa jẹ lasiko aawẹ ṣe pataki lati mojuto.

Awọn ilana to le tẹle lasiko aawẹ

O ṣe pataki lati mọ wipe aimu omi fun igba pipẹ nitori awẹ gbigba amaa mu adinku ba iye omi to wa lara wa.

Ki a baa le mu adinku ba iru nkan bayii, o ṣe pataki lati mu omi daada ni asiko iṣinu tabi ni saari ta ba n jẹun.

Aṣiṣe kan tawọn eeyan a tun maa ṣe lasiko aawẹ ni pe wọn kii fẹ jẹ ounjẹ lasiko saari tori pe wọn fẹ sun oorun daada.

Bi eeyan ba jẹ ounjẹ saari to lokun daada, iru ru eeyan bẹe ko ni mọ inira ori fifọ, aisi agbara ati awọn ipenija mii to maa n koju alaawẹ lọsan.

Ounjẹ saari wa taa ba jẹ gbọdọ kun fun awọn ounjẹ aṣaraloore ati afuni lagbara ounjẹ.

Ni iwọn si lo yẹ ki a jẹ ounjẹ yi ki ṣuga inu ẹje wa baa le ṣe deede ki ara si le ni okun to nilo lati fi gba aawẹ lọsan.

Iṣinu nkọ?

Aworan ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni asiko iṣinu o di dandan ka wa ounjẹ ti yoo da okun taa padanu lasiko aawẹ pada sinu ara wa.

Sunnah kan taa le tẹle lasiko yi ni ki a fi dabino ṣinu,omi tabi miliiki.

Bi a ba pa wọn pọ ko buru tori awọn nkan wọnyi kun fun okun, ṣuga ati omi ti ara nilo.

Musulumi jakejado agbaye lo ni aṣa ki wọn jẹ ounjẹ alata lẹyin ti wọn ba fi bi eso tabi omi ṣinu tan.

Eleyi naa ko buru tori pe yoo pẹlu lati da okun pada si ara lẹyin aawẹ ti wọn ba gba.

Ẹfọ, ounjẹ okele ti ko pọju tabi ounjẹ wooro naa lanfaani fun ara ẹni to ba fi eleyi ṣinu lẹyin aawẹ to foju ọsan gba.

Ni agbegbe Guusu Asia, niṣe lawọn eeyan a maa fi eso ṣinu gẹgẹ bi ọna ati da okun pada si ara wọn.

Ounjẹ tawọn eeyan a si maa jẹ ni iṣinu yoo da bi pe wọn ṣe apejẹ nla ni.

Wọn a maa pe ọrẹ ati ara lati wa kopa ninu ounjẹ iṣinu yi lọpọ igba.

O ṣe pataki lati ranti wi pe ounjẹ to ni epo tabi ororo pupọ ninu a maa mu irẹwẹsi ba alaawe ti ko si ni jẹ ko lalaafia ti yoo fi gbajumọ ijọsin to yẹ ko ṣe ninu oṣu Ramadan.

Amojuto ilera lasiko aawẹ

ṢIṣe amoju ara wa lasiko aawẹ ko mọ nibi ounjẹ nikan.

Oorun sisun naa ṣe pataki lasiko aawẹ lati le jẹ ki ara alaawẹ ji pepe daada.

O yẹ ka ṣeto tabi ki a ni ilana taa fi sun lasiko yi yala lasiko taa n gba aawẹ lọwọ tabi ni igba ta baa n sun laarin oru.

O ṣe pataki lati la asiko taa maa ji kal atiigba taa ma sun lati ibẹrẹ titi di ipari aawẹ.

ṢIṣe awọn iṣẹ ti ko ni jẹ ki o rẹ ara wa pupọ lasiko awẹ naa ṣe apataki.

O le rin diẹ tabi ko ṣe awọn iṣe agbara diẹ ki gbogbo kaṣan ati orike rike ara to le baa le dẹ diẹ.

Awọn to baa n mu tea tabi coffee lasiko saari yoo ri wi pe lọwọ ọsan ori fifọ diẹ diẹ yoo maa waye.

Idi ni pe lasiko yi ni caffeine to wa ninu nkan ti wọn mu yi yoo tan ninu ara wa.

Amọ nigba ti yoo ba fi to osẹ kan ti wọn ti n gba aawẹ, yoo pada mọra ti wọn ko si ni mọ ori fifọ yi lara mọ.

Ohun to ṣe pataki ni ka maa kiyesi ikilọ eyikeyi ti ara wa ba n fun wa.

Eyi ni yoo jẹ ka mọ ohun to yẹ lati ṣe ki iru rẹ ma ba waye mọ.

Bi o ba ti n rẹ ara rẹ, ri wi pe o sinmi ko si jawọ ninu awọn nkan ti yoo mu ki o rẹ ara rẹ pupọ lasiko awẹ.

Ẹmi wa yoo rẹyin oṣu.