Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba àpapọ̀ ṣe àgbékalẹ̀ ètò ìṣúná méjì fún ọdún 2024?

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale
Ijọba apapọ ti sọ pe irọ ni iroyin to n lọ laarin ilu pe oun fi owo ti iye rẹ to tiriliọnu mẹta naira kun iṣuna ọdun 2024 lairotẹlẹ.
Ọrọ yii lo n jade lẹyin ti sẹnetọ to n sọju aringbungbun Bauchi ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Abdul Ningi, sọ pe owo ti ijọba n na pọ ju iye owo to kede ninu eto iṣuna ọdun yii lọ.
Amọ ṣa, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ti sọ pe awọn yoo ṣepade lori ọrọ naa lonii.
Ṣaaju ni Ningi ti kọkọ sọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC labẹ asia ẹgbẹ Northern Senators’ Forum pe, owo iṣuna ti Aarẹ Bọla Tinubu n na pọ iye ti awọna asọfin buwọlu lọ.
A gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo ṣe iwadii bi N3trn ṣe wọ inu eto iṣuna ọdun 2023 - Ningi
Gẹgẹ bii ohun to sọ fun BBC, N25tn ni iṣuna ti awọn aṣofin buwọlu ṣaaju, kii ṣe N28.7tn ti ijọba Tinubu n na lọwọ.
O ni “Yatọ si iṣuna ti a fọwọ si, eto iṣuna mii wa ti wọn ṣe ni bonkẹlẹ ti a ko mọ nipa rẹ.
“A ko mọ nnkankan nipa awọn ohun tuntun ti a ri ninu eto iṣuna tuntun naa nitori ko si ninu abadofin ti a jiroro le lori ninu ile igbimọ aṣofin.”
O ni awọn yoo gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo ṣe iwadii bi N3trn ṣe wọ inu eto iṣuna ọdun 2023, ti awọn yoo si fi abajade esi iwadii awọn to Aarẹ leti.
O ni “Eto ti wa nilẹ, a o si fa abajade iwadii wa le Aarẹ Tinubu funra rẹ lọwọ lati sọ boya o mọ nnkankan nipa owo naa tabi bẹẹ kọ.”
Ijọba apapọ fesi...
Ẹwẹ, ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga fi lede, o ni ko si ootọ kankan ninu ọrọ Ningi.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, eto iṣuna N27.5tn ni Aarẹ gbe lọ siwaju awọn aṣofin ninu oṣu Kọkanla ọdun to kọja, ti wọn si buwọlu.
Onanuga ni yoo ṣoro fun ile igbimọ aṣofin ọhun lati buwọlu eto iṣuna N25trn ti Aarẹ ko gbe lọ siwaju wọn.














