Wo ìpínlẹ̀ mẹ́rìnlá àti Abuja tó ṣeéṣe kí agbébọn kọlu ilé ẹ̀kọ́ wọn – ìjọba àpapọ̀

bandit attack

Oríṣun àwòrán, @ARISEtv

Lẹyin ti awọn agbesunmọmi bẹrẹ si n ji awọn akẹkọọ gbe ni iha Ariwa Naijiria, ijọba apapọ ti sọ pe o ṣeeṣe ki awọn agbesunmọmi kọlu oniruru ile ẹkọ ni ipinlẹ mẹrinla ni Naijiria, to fi mọ ilu Abuja.

Adari ajọ Financing Safe Schools in Nigeria, Hajia Halima Iliya, lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Punch.

Bo tilẹ jẹ pe Iliya kọ lati darukọ awọn ipinlẹ ti ikọlu naa yoo ti waye, adari ikọ National Safe Schools Response Coordination Centre ninu ajọ NCDC, Hammed Abodunrin mẹnuba awọn ipinlẹ ọhun.

Abodunrin sọ pe o ṣeeṣe ki ijinigbe awọn akẹkọọ nile ẹkọ waye nipinlẹ Adamawa, Bauchi, Borno, Benue, Yobe, Katsina, FCT, Kebbi, Sokoto, Plateau, Zamfara atawọn ipinlẹ mii.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ko din ni akẹkọọ ati olukọ 465 ti awọn agbebọn jigbe laarin ọsẹ diẹ si asiko yii nilẹ ẹkọ wọn, ti pupọ ninu wọn ṣi wa lakata awọn ajinigbe ọhun.

Awọn akẹkọọ to wa lakata ajinigbe bayii

Lọjọ Abamẹta ni wọn ji akẹkọọ 15 gbe nile ẹkọ Islamiya ni Sokoto, lẹyin wakati diẹ si ni wọn tun ji apapọ akẹkọọ 287 gbe mii nile ẹkọ LEA primary school ati Government Secondary School to wa ni ijọba ibilẹ Chikun, ni Kaduna.

Laarin ọjọ diẹ ṣaaju ijinigbe ipinlẹ Kaduna, awọn agbebọn kọlu igba obinrin to n gbe nibudo awọn ogunlende lasiko ti wọn lọ wa igi idana ni Borno.

Ọjọ keji iṣẹlẹ naa ni iroyin sọ pe awọn kan ti moribọ lara wọn, nigba ti awọn 191 ṣi wa lakata ajinigbe.

Lọjọbọ to kọja lawọn araalu fẹhunuhan loju ọna marosẹ Kaduna si Abuja latari bi awọn agbebọn mii ṣe ji awọn eeyan kan gbe lagbegbe Gonin-Gora, nijọba ibilẹ Chikun.

Ijọba apapọ di ẹbi ọrọ naa le awọn ẹgbẹ alatako lori

Ẹwẹ, ijọba apapọ ti di ẹbi ọrọ naa le awọn to fẹsun kan pe wọn fẹ doju ijọba to wa lode bolẹ lori.

Agbẹnusọ Aarẹ Bola Tinubu, Ajuri Ngelale lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin TVC.

Ngelale ni “Ohun ti mo maa sọ niyi, kaakiri Ariwa, amọ pe awọn oloṣelu kan wa to n gbimọ pọ lati doju ijọba Naijiria bolẹ.”

Ngelale pari ọrọ rẹ pe ijọba ko kawọ gbera lori ọrọ abo, o si ti ri ifọwọsowọpọ ijọba ilẹ Amẹrika lati doola awọn akẹkọọ ahamọ ajinigbe.