“Nínú àwa mẹ́fà, ó ku èmi nìkan, Taiwo ló ń ṣe ọkọ fún mi láti ọdún mẹ́fà tí mo ti di opó”
Ẹkun ati ayọ lo pade ara wọn nigba ti wọn se awari oku dẹrẹba ti awọn agbebọn yinbọn fun lati ọjọ kẹtadinlọgbọn osu Kinni ọdun 2024, Taiwo Razak Olugbaye.
Bẹẹ ba gbagbe, a mu iroyin wa fun yin saaju pe ọjọ yii ni awọn ajinigbe ji awn akẹkọọ ile ẹkọ kan gbe lọ ni ilu Emure Ekiti.
Bi o tilẹ jẹ pe wọn ri awọn ọhun gba pada amọ ẹpa ko boro mọ, awọn agbebọn yii ni wọn sọ pe wọn yin dẹrẹba ni ibọn, ti wn ko si ri oku rẹ, ti wọn sọ sinu igbo.
Lati igba yii waa ni aayan ti n lọ lati se awari oku ọkunrin naa titi di ọjọ Aiku, ọjọ Kẹwa osu Kẹta ti agbẹ kan ni oun ri oku ẹni to jọ dẹrẹba naa nilu Iporo Ekiti.
Awọn ọlọpaa, ọmọ, aya, atawọn ẹbi oloogbe naa lọ sibi ti oku ọhun wa, ti wọn si da mọ pe oku tawọn ti n wa lati ogoji ọjọ o le diẹ ni.
BBC Yoruba naa wa nibi ti wọn ti lọ gbe oku ọhun, ti a si ba ikeji oloogbe naa, tii se Kehinde rẹ sọrọ pẹlu aya atawọn ọmọ oloogbe ati ọlọpaa.

“Wọn ka mi leyin ọọkan, iwọnba owo ti Taiwo n gba lo n fun mi, oun ni olutọju ati alajọsọ mi”
Mama tii se Kehinde oloogbe naa salaye fun BBC Yoruba pe eeyan gidi ni Taiwo ikeji oun lasiko to wa laye, ko si yẹ ko jẹ iru rẹ ni yoo se agbako to se naa.
O ni lati ọdun kẹfa ti ọkọ oun ti ku, Taiwo yii lo n tju oun, to si n se bii ọkọ fun oun.
“Wọn ka mi leyin ọọkan, iwọnba owo ti Taiwo n gba lo n fun mi, oun ni olutju ati alajọsọ mi
N ko ni alajọsọ mọ nitori ninu awa ọmọ mẹfa ti obi wa bi, emi nikan soso lo ku.
Aaye Taiwo mi lo yẹ ki wọn gbe wa fun mi, kii se oku rẹ nitori ọmọ gidi ni ikeji mi ti ẹ ba mọ ọ.”

“Mo ti fẹ sa lọ lẹyin adura ogoji ọjọ ti wọn ko ba ri oku ọkọ mi tori eebu nla ni pe ko ri oju orori”
Nigba ti oun naa n sọrọ pẹlu BBC Yoruba, aya dẹrẹba to ku lati ọwọ awọn ajinigbe ọhun ni inu oun dun ni ẹgbẹ kan pe wọn ri ọkọ oun, ti inu oun si tun bajẹ ni ẹgbẹ keji.
“Eebu nla ni ko ba jẹ ti wọn ko ba ri oku ọkọ mi, wọn yoo maa sọ pe ko ni oju orori.
Emi gan ti n gbero lati sa lọ lẹyin ogoji ọjọ to ba jẹ pe wọn ko ri oku naa ni amọ inu mi dun pe wọn ri oku rẹ.”

“Ẹyin ni wọn ti yin ibọn fun baba mi, awọtẹlẹ rẹ, asọ ankara to wọ, oruka ọwọ rẹ ati ipakọ la fi da mọ”
Bakan naa ni ọmọ oloogbe yii salaye fun BBC Yoruba lori bi wọn se fidi ootọ mulẹ pe baba oun ni oku ti wọn ri.
O ni “ẹyin ni wọn ti gbe ibọn fun baba mi, ti wọn si doju bolẹ.
A ri awọtẹlẹ rẹ pẹlu ankara to wa lọrun wọn, oruka ti wọn fi sọwọ, pẹlu ipakọ wọn.
Alukoro Ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ni agbẹ oloko ẹgẹ kan lo ri oku awakọ naa, to si fi to ọlọpaa leti
Alukoro Ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, ASP Sunday Abutu, ni agbẹ oloko ẹgẹ kan to n dako ninu oko rẹ lo ri oku awakọ naa, ti o si fi to ọlọpaa leti.
Ọ́jọ́ kọ́kandinlọgbọn oṣu kinni ọdun 2024 ni awọn ajinigbe da awọn akẹkọọ ati awọn olukọ wọn lọna, ti wọn si ji awọn mẹsan gbe.
Wọn seku pa direba, ti awọn mẹjọ to ku si gba itusilẹ.
Lẹyin Ogoji ọjọ le kan ti iṣẹlẹ ibi naa sẹlẹ ni wọn pada ri oku dirẹba yii.
Alukoro Ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, ASP Sunday Abutu, ni agbẹ oloko ẹgẹ kan to n dako ninu oko rẹ lo ri oku awakọ naa, ti o si fi to ọlọpaa leti.
O ni iwadi si fi idi rẹ mulẹ pe oku awako ileẹkọ the Apostolic Faith Montessori School Emure Ekiti ti awọn ajinigbe pa sinu igbo aginju reserve nii ṣe.

Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, ọlọ́pàá rí òkú awakọ̀ àwọn akẹ̀kọ̀ọ́ Ekiti tó kó sọ́wọ́ ajínigbé
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti ṣe awari oku Taiwo Olugbaye, tii se awakọ ileẹkọ the Apostolic Faith Montessori School, Emure Ekiti, ti wọn fura si pe awọn ajinigbe pa si inu igbo.
Akọbi oloogbe naa, Tosin Olugbaye lo fidi ọrọ yii mulẹ fun akọroyin BBC Yoruba.
Tosin ṣalaye pe ni ọsan ọjọ Kẹsan-an oṣu Kẹta ọdun 2024, ni alaga ijọba ibilẹ Emure Ekiti pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ pe wọn ti ri oku baba awọn.
Bakan naa, lo ni alaga hun sọ fun oun pe ki awọn se eto lati tẹle awọn ọlọpaa lọ gbe jade oku naa kuro ninu igbo aginju ti wọn pa si.
Ọmọ oloogbe naa ṣọ pe kete ti oun de ilu Emure Ekiti pada, ni oun yọju si alaga ijọba ibilẹ ti o pe oun, ti o si fi aworan ibi ti wọn pa baba oun si han oun.
O ni oun ṣayẹwo aworan naa, ti oun si ri daju pe baba oun lo wa ninu rẹ.
O tẹ́siwaju pe nigbati awọn de inu igbo aginju naa ni oun to wa ri aridaju pe baba ohun ni.
"Oruka fadaka ọwọ rẹ, awọtẹlẹ̀ ti o fẹran lati ma wọ ati ankara ọrun rẹ̀, ni mo fi daa mọ̀.
Oku naa ti n jẹra, to si ti bẹrẹ si ni run."
Tosin fikun pe lẹyin igba naa lawọn eleto ilera da kẹ́míkà si, ti wọn si yi mọ inu ọra.
Ibanujẹ ati ayọ lo de ba ọkan mi tori bi wọn se ri oku ọkọ mi - Iyawo oloogbe
BBC Yoruba tun pade iyawo oloogbe ni ile igbokupamọsi to wa ni ile iwosan apapọ nilu Emure Ekiti.
Nibẹ lo ti ṣalaye pe inu oun dun pe wọn ri oku ọkọ oun ṣugbọn ohun ibanujẹ lo jẹ wi pe awọn padanu rẹ.
O ni ẹnu ẹgan yoo kuro lara mọlẹbi oloogbe bayii tori awọn yoo ri oku rẹ sin.
''Mo ti pinnu lọkan mi pe mo maa salọ ni ti mo ba fi jade opo ti wọn ko si ri oku ọkọ mii.''
Bakan naa ni ọmọ iya oloogbe to jẹ Kehinde rẹ sọ pe ibanujẹ ọkan nla lo jẹ nigba ti wọn tufọ iku rẹ.
O ni ko si ẹnikẹni to le di ipo ikeji oun pẹlu gbogbo nkan ti o ma n ṣe lati igba ti ko si ọkọ fun oun mọ.
Gbogbo mọlẹbi oloogbe ati iyawo ni wọn dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Ekiti, ijọba apapọ, ati awọn eekan nla nla ninu ilu fun aduroti ati iranlọwọ ti wọn ṣe fun wọn lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye.
















