N15m si N20m là ń ná lọ́sẹ̀ lórí àwọn tó faragbá nínú ìbúgbàmú tó wáyé n‘Ibadan - Ìjọba Oyo

Ibadan explosion

Oríṣun àwòrán, bbc

Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe owo ti iye rẹ to miliọnu marundinlogun si ogun miliọnu naira ni oun n na laarin ọsẹ lori awọn to faragba nibi ibugbamu to waye lagbegbe Bodija, niluu Ibadan ni nkan bii oṣu meji sẹyin.

Kọmiṣọna eto iroyin, Dotun Oyelade, lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi sita lẹyin ti iroyin kan ni ijọba Oyo ti kọ awọn eeyan to faragba nibi ibugbamu naa silẹ.

Ninu atẹjade naa to fi ṣọwọ si awọn akọroyin, Oyelade sọ pe eeyan mejidinlogoji ni ijọba fi sile itura igbalode, ti ijọba si n san owo wọn nibẹ.

O fi kun pe ko din ni milọnu meji naira ti ijọba n san fun awọn ẹṣọ alaabo to n ṣọ agbegbe ibugbamu ọhun.

Oyelade ṣalaye siwaju si pe ijọba tun ti san owo ti iye rẹ to miliọnu mẹtadinologun gẹgẹ bii owo itọju awọn eeyan to ṣi wa nile iwosan.

Idubo ibugbamu

"Ijọba oyo ti na owo to le ni N160m lori ibugbe ati ounjẹ awọn ti a ko sile itura"

Kọmiṣọna naa ni irọ ni iroyin to sọ pe ounjẹ awọn eeyan ọhun dinku, ati pe ijọba ko le awọn to gba ile itura fun jade nibi to fi wọn pamo si.

Oyelade ni dipo ki ijọba ṣe bẹẹ, o ni ṣe ni wọn ko wọn kuro nile itura ti wọn wa tẹlẹ, lọ sile itura mii lagbegbe Jericho.

O ni “Bi a ṣe n sọrọ yii, ijọba ti na owo to le ni N160m lori ibugbe ati ounjẹ awọn ti a ko sile itura, mejidinlogoji ninu wọn lo ṣi wa lawọn ile itura kaakiri.

“Ko si ootọ kankan ninu awọn iroyin to sọ pe a ti le awọn eeyan jade nile itura ti a fi wọn si.

“Ọkan lara awọn ile itura to wa ni Idi Ape sọ pe oun fẹ fi oogun apa kokoro sile itura oun, ijọba si pese ọkọ lati ko awọn eeyan naa ati ẹbi wọn kuro nibẹ lọ sile itura mii ni Jericho.”

“Lori iroyin pe ijọba ti din ounjẹ awọn eeyan naa ku si igba kan loojọ, irọ ni, nitori ọpọ awọn ile itura naa lo n pese ounjẹ owurọ fun awọn alejo wọn.

“Niwọn igba to jẹ pe awọn eeyan maa kii si nile lọsan an ni ijọba ṣe n fun wọn ni ounjẹ alẹ.

O pari ọrọ rẹ pe inu ijọba dun bi awọn ti ọrọ naa kan atawọn araalu ṣe mọ riri ohun ti ijọba ṣe fun awọn eeyan ọhun.