Wo kókó tó wà nínú òfin tuntun tí UK ṣe fún ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ jápa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìjọba orílẹ̀ èdè United Kingdom (UK) ti kéde ìgbésẹ̀ tuntun lórí àwọn àjèjì òṣìṣẹ́ tó ń pèsè ìtọ́jú fáwọn èèyàn tó wá ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè náà.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí ìjọba UK fí sórí ẹ̀rọ ayélujára X lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹta ọdún 2024 ni wọ́n ti kéde pé àwọn kò ní fi ààyè gba òṣìṣẹ́ ìlera láti ilẹ̀ òkèrè tó bá fẹ́ ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀ àwọn, láti máa kó ẹbí wọn dání mọ́.
Wọ́n ní ìgbésẹ̀ yìí ń wáyé láti mójútó bí àwọn èèyàn ṣe ń ya wọ orílẹ̀ èdè náà.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àtẹ̀jáde tí UK Home Office fi síta, ẹni tó bá fẹ́ máa pèsè ìtọ́jú nílò láti fi orúkọ sílẹ̀ pé bóyá wọ́n ń ṣe ìrànwọ́ fún ẹnikẹ́ni.
James Cleverly tó jẹ́ akọ̀wé Home Office sọ wí pé lóòótọ́ ni àwọn òṣìṣẹ́ yìí ní iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fún orílẹ̀ èdè àwọn àmọ́ àwọn kò lè fojú fo àwọn ìwà ìbàjẹ́ tó ń ti ibẹ̀ jáde.
Cleverly ní àwọn kò lè fàyè gbà kí àwọn ìwà ìbàjẹ́ yìí máa tẹ̀síwájú.
“A ṣèlérí fú àwọn èèyàn ilẹ̀ Britain pé wọn yóò rí ìyípadà, a ò sì ní káàárẹ̀ ọkàn títí a ó fi mú àdéhùn wa ṣẹ pé àwọn tó ń wá gbé orílẹ̀ èdè wa láti ilẹ̀ òkèrè ni àdínkù bá jọjọ.
Akọ̀wé náà ni ìgbésẹ̀ tuntun yìí dára nítorí ó ń dá ààbò bo àwọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Britain, tó sì tún fàyè sílẹ̀ fún àwọn àlejò láti kàwé àti ṣiṣẹ́ láti mú àgbéga bá ètò ọrọ̀ ajé UK.
Èèyàn 120,000 tó ti ń gbé UK láti ọdún tó kọjá ni òfin náà yóò ṣàkóbá fún
UK Home Office ní àwọn fẹ́ mú àdínkù bá bí àwọn àlejò ṣe ń gbé orílẹ̀ èdè àwọn – àwọn enìyàn 745,000 ló fi orílẹ̀ èdè wọn sílẹ̀ láti máa lọ gbé UK ní ọdún 2022.
“Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ à ń pèsè ìtọ́jú kiò ní lè máa mú àwọn ẹbí wọn wá mọ́, èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn èèyàn 120,000 tẹ̀lé òṣìṣẹ́ 100,000 wọ UK lọ́dún 2023.”
Ohun tí èyí túmọ̀ sí pé èèyàn 300,000 tó lè wọ UK lọ́dún tó kọjá, kò ní àǹfàní láti wọ orílẹ̀ èdè náà ní ọdún yìí.
James Clerverly fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ kan ń parọ́ gba físà láti wá ṣiṣẹ́ ìtọ́jú àti pé wọn kò gba àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè àwọn láàyè láti rí iṣẹ́ ṣe.
“Ẹ̀rí wà pé àwọn òṣìṣẹ́ tó ń pèsè ìtọ́jú kan ń parọ́ gba “visa”, tí wọn yóò rìnrìnàjò fún iṣẹ́ tí kò sí, ọ̀pọ̀ ló ń gba owó tó dín sí owó ọ̀yà tó kéré jùlọ.”
Mínísítà fún ìpèsè ìtọ́jú, Helen Whately ní àwọn máa ṣe àgbéyẹ̀wò òfin tó de àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ òkèrè láti ri pé wọn kò máa ṣì í lò àti láti dá ààbò bo ètò ẹ̀kọ́ gíga.
Àjọ tó ń rí sí gbígba àwọn èèyàn láti ilẹ̀ òkèrè ní àwọn ṣe àmójútọ rẹ̀ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 175,872 tí wọ́n ti fún ní visa ló jẹ́ àwọn tó kájú òṣùwọ̀n.
Wọ́n ní èyí kò sẹ̀yìn pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà wọ UK láàárín ọdún 2018 sí 2022 tí wọn kò sì yege nínú ẹ̀kọ́ wọn ni wọ́n ti wọ ìdá 250%.
Ìjọba ni àwọn máa ṣàrídájú rẹ̀ pé gbogbo iṣẹ́ ni yóò nílò láti ní ìmọ̀ kan pàtó àti pé àwọn kò ní máa dara dé àwọn ará ilẹ̀ òkèrè mọ́.
"Owó oṣù tó kéré jùlọ fún àwọn òṣìṣẹ́ tó ní ìwé ẹ̀rí ti lé pẹ̀lú ìdá mejidinlaadọta"
Òfin tuntun tí ìjọba UK gbé kalẹ̀ tún ti mú àlékún bá iye tí òṣìṣẹ́ yóò máa gbà, kí ó tó balẹ̀ sí UK.
Láti ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹrin, owó tó kéré jù tí òṣìṣẹ́ yóò gbà ti lékún láti £26,200 sí £38,700.
Èyí ni èròńgbà wà pé yóò mú àdínkù bá bí àwọn kan ṣe máa ń gba àwọn èèyàn ilẹ̀ òkèrè síṣẹ́.
Iṣẹ́ wà lára àwọn ọ̀nà tí àwọn èèyàn máa ń lò, lẹ́yìn ètò ìkẹ́kọ̀ọ́, láti fi gba visa lọ sí UK.
Ní ọdún 2023 ni ẹ̀ka Home Office United Kingdom kéde pé àwọn kò ní fàyè gbà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti máa mú àwọn ènìyàn wọn wá sí orílẹ̀ èdè náà.
Nínú oṣù Karùn-ún, ọdún 2023 akọ̀wé tẹ́lẹ̀ rí fọ̀rọ̀ iléeṣẹ́ ọ̀rọ̀ abẹ́nú, Suella Braverman ní láti ọdún 2024 ni àwọn kò ní fi ààyè gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ òkèrè láti máa mú àwọn ẹbí dání mọ́ àyàfi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ onípò kejì (ọ̀mọ̀wé).
Braverman ní èyí ni láti mú àdínkù bá iye ènìyàn tó ń wá gbé UK ní ọdọọdún.
Ìjọba UK ní Nàìjíríà ló ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wá láti Nàìjíríà ló mú àwọn ẹbí wọn wọ orílẹ̀ èdè náà jùlọ láàárín ọdún 2019 sí 2023.















