Wo bí o ṣe le lo ojú òpó ayélujára lásìkò Ramadan láì ba ààwẹ̀ jẹ́

Aworan idanimọ oju opo ayelujara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Imọ ode oni laarin nkan bi ọdun mẹwaa sẹyin ti mu iyipda ba ọpọ nkan.

Anfaani imọ oju opo ayelujara ati lilo ẹrọ alagbeka ni paapa ti se pataki ni igbesi aye awọn eeyan.

Nitori ipa ti lilo oju opo ni yi, o ṣe pataki lati mọ bi eeyan yoo ṣe lo paapa lasiko oṣu Ramadan tawọn musulumi ti n gba aawẹ.

Eyi ṣe pataki ki wọn ma ba lugbadi aṣẹ ati ilana to de aawẹ gbigba.

BBC ba Sheikh Usman Gadon Kaya to jẹ onimọ ẹsin Islaamu ni Kano sọrọ lori ọrọ yi.

O ṣalaye ọna ti musulumi le fi lo oju opo ayelujara lasiko oṣu Ramadan.

O ni itumọ aawẹ gbigba ni ijanu nidi awọn iwa to le mu eeyan kọlugba Allah.

O sọ pe: ''Koda ki eeyan maa sọra ṣaaju aawẹ, asiko aawẹ lo yẹ ko mura daada ki o ma ba ja si inu aṣiṣe tabi iṣekuṣe''

Aworan afihan oju opo ayelujara

Oríṣun àwòrán, PA MEDIA

Ohun taa gbọdọ sọra fun

Ninu awọn alaye nkan ti a gbọdọ yago fun ti onimọ ẹsin yi sọ la ti ri:

  • Wiwo orin ati ijo kijo loju opo ayelujara
  • Wiwo ihoho obinrin
  • Sisọ tabi kikọ ọrọ alufansaa
  • Ṣiṣe alabapin iroyin ofege
  • Wiwo fiimu ati awọn fọnran ti ko bojumu

O lo ṣeni laanu pe bi eeyan ba lọ si oju opo YouTube orisi nkan ti ko yẹ ki oju alaawẹ ri lo wa nibẹ.

''Awọn nkan tawọn eeyan n ṣe loju opo TikTok afi ki eeyan tọrọ aforijin ni. Bi eeyan ba ri awọn nkan tawn eeyan n ṣe nibẹ, o di dandan ki aawẹ iru eeyan bẹ bajẹ ni.''

O ni lasiko aawẹ yi, o yẹ ki musulumi yago fun iwokuwo tabi igbọkugbọ loju opo TikTok,Instagram ati YouTube .

O fikun pe ti ko ba ni ṣe wọn lanfaani ti yoo si mu ki aahẹ ba aawẹ wọn, ki awọn musulumi yago fun awọn nkan wọnyi.

Bẹẹ naa lo sọ pe asiko kiko ara , oju eti ati ẹya ara mii ni ijanu lọwọ jijẹ mimu sisọ ati idunadura haraamu ni asiko Ramadan jẹ.

''Ni bayii, awọn oniwaasu n gbiyanju.Loju opo taa darukọ yi bakan naa,wọn n ṣe iwaasu alanfaani fawọn eeyan.Ibi ti aburu wa yi naa ni wọn le ri awọ́n nkan ti yoo ṣe aawẹ wọn lanfaani''

Nkan taa le ṣe lati fi ni laada lasiko aawẹ

Aworan Sheikh Abdullahi Gadon Kaya

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abdullahi GadonKaya

Sheikh Abdullahi Usman Gadon Kaya sọ pe awọn oju opo yi a maa gba asiko pupọ ti awọn eeyan ko si ni ribi ṣe iṣẹ ibadah bi kike Quraani ati gbigbọ waasi.

Tori naa o daba awọn nkan ti awọn musulumi le ṣe lasiko aawẹ ki laada wọn ba le jẹ ẹkunrẹrẹ.

Lara awọn nkan to da laba ni pe :

  • Ṣiṣe alabapin iwaasu lori ọrọ ẹsin. O ni gbogbo alaye ẹsin ti yoo ba ṣe awọn eeyan lanfaani ki musulumi maa ba wọn pin lasiko Ramadan yii.
  • Pinpin arọwa lati ke alqurani lasiko aawẹ .O ni ki awọn musulumi maa fi ọrọ tabi atẹjiṣẹ eleyi ti yoo gba ọrẹ ati mọlẹbi wọn niyanju lati ke Al Quran.
  • Wiwo nkan daada lasiko aawẹ
  • Fifi ọrọ ti yoo ṣe lekun igbagbọ lasiko aawẹ.

Lakotan, o ni awọn oniṣẹ iroyin tabi awọn to n gbe ọrọ jade loju opo yi ni ipa lati ko nipa iwaasu ti yoo ṣe araalu lanfaani.

O ni ki ijọba naa si wa ọna lati fi mu ayẹ dẹrun faraalu ati awọn to n wa na ijẹ imu wn lọna ẹtọ.