Kí ló ṣẹlẹ̀ láàrin PrimeBoy àti Wunmi, aya Mohbad, tí ọlọ́pàá ṣe pè é fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò?

Mohbad ati Primeboy

Oríṣun àwòrán, Collage

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fidi ẹ mulẹ pe oun ti fọrọ wa Ibrahim Owodunni,(Primeboy) to jẹ ọrẹ timọtimọ Ilerioluwa Alọba (Mohbad), lẹnu wo lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejila oṣu kẹta ọdun 2023 yii.

Eyi waye lẹyin ti iyawo Mohbad, Ọmọwumi Alọba, kọwe ifisun pe o ba oun lorukọ jẹ.

Gbogbo ọjọ Iṣẹgun ni Primeboy maa n lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Panti, Yaba, nipinlẹ Eko, fun ifọrọwanilẹnuwo lori iku Mohbad, gẹgẹ bi aṣẹ ti wọn pa fun un.

Ṣugbọn lọjọ Iṣẹgun ọjọ kejila, oṣu kẹta yii, oun ati Ayọbami Fisayọ (Spending) ni wọn jọ lọ.

Amọ awọn ọlọpaa yọnda Spending lati maa lọ, wọn si da Primeboy duro sọdọ wọn nitori iwe ifisun ti Ọmọwumi Alọba, Iyawo Mohbad kọ sawọn ọlọpaa pe o ba oun lorukọ jẹ.

Wunmi ati Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad

A ti yọ̀ǹda PrimeBoy lẹyin ta fi ọrọ wa lẹnu wò tán - Ọlọpaa

Alukoro ọlọpaa Eko, Benjamin Hundeyin, ṣalaye pe awọn yọnda Primeboy lẹyin tawọn fi ọrọ wa a lẹnu wo tan.

‘’ A sọ fun Primeboy pe ko maa wa si agọ wa ni gbogbo ọjọ Iṣẹgun lati maa waa kọwọ bọwe, ka le ri aridaju pe ko ni i sa lọ lori iku Mohbad ta a n wadii rẹ lọwọ.

‘’Ṣugbọn o pẹ gan-an ju ti tẹlẹ lọ ka too fi i silẹ lọjọ Iṣẹgun yii, idi si ni pe Iyawo Mohbad kọwe ifisun nipa rẹ, ẹsun ibanilorukọ jẹ si wa ninu rẹ.

‘’Lẹyin to dahun awọn ibeere wa tan, mo gbọ pe DC ni ko maa lọ.

‘’Nigba ti yoo si fi di aago mẹfa kọja iṣeju mejila nirọlẹ, a ti yọnda rẹ pe ko maa lọ.’’

Awijare awọn ọlọpaa yii ni lọọya ti wọn lo lọọ gba beeli Primeboy tako. O ni irọ ni.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejila oṣu kẹsan-an ọdun 2023 ni Mohbad jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27).

Ki lo ti waye saaju?

Latigba ti olorin sufee-taka naa ti ku iku ojiji yii ni ọrọ naa ti di ẹjọ.

Ọkan lara awọn eeyan tawọn ọlọpaa n wadii latigba naa ni Primeboy yii, ẹni ti wọn ni oun ati Mohbad jọ ja n’Ikorodu lalẹ ọjọ ti oloogbe kọrin gbẹyin.

Ọjọ kẹrin oṣu kẹwaa ọdun 2023 ni awọn ọlọpaa Eko kede pe awọn n wa Primeboy lori iku Mohbad, ki ọmọkunrin naa too lọọ fa ara rẹ kalẹ fun wọn lẹyin ọjọ meji.

Yatọ si Naira Marley ati Sam Larry ti ẹnu kun gidi lori iku Mohbad yii, ẹni kan ti wọn tun n ba ṣẹjọ ni Primeboy ti wọn lawọn ọlọpaa tun ti mu bayii.

Wọn ko ti i sinku Mohbad titi dasiko yii, nitori awọn ọlọpaa ni awọn ko ti i gba esi ayẹwo iku to pa a gan-an.

Àkọlé fídíò, Ekiti Driver‘s Corpse: Kehinde dẹ́rẹ́bà ní wọn ká òun léyín ọ̀ọ́kán, òun kò ní alájọsọ mọ́

Bàbá Mohbad fẹ́ àṣẹ́ ilé ẹjọ́ láti ṣe DNA fún ọmọ ọmọ rẹ̀ àmọ́ wọn kò rí Wunmi fún ní ìwé ìpẹ̀jọ́

Mohbad ati Baba rẹ

Oríṣun àwòrán, Collage

Gbogbo eto lo ti to bayii lori ẹjọ kan ti Joseph Aloba, ẹni tii se baba gbajumọ akọrin takansufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ eeyan mọ si Mohbad pe.

Ẹjọ yii ni baba Mohbad pe aya ọmọ rẹ, Wunmi Aloba, lati beere pe ki ile ẹjọ fi ontẹ lu pe ki wọn se ayẹwo ta lo ni ọmọ, DNA fun ọmọ ti wọn ni Mohbad bi, ti orukọ rẹ n jẹ Liam.

Atẹjade kan ti agbẹjọro fun ẹbi Aloba, Monisola Odumosu fisita fawọn akọroyin, lo fidi ẹjọ naa mulẹ.

Ile ẹjọ Majisireti to kalẹ si ilu Ikorodu nipinlẹ Eko lo ni igbẹjọ naa yoo ti waye.

Atẹjade naa salaye pe gbogbo igbesẹ ofin to yẹ ni ẹbi naa yoo se lati ri pe ẹjọ naa kẹsẹjari.

"Gbogbo aayan lati fun aya Mohbad, Wunmi ni iwe ipẹjọ lo ja si pabo"

Atẹjade naa fikun pe “Baba Mohbad fẹ gba asẹ ileẹjọ lati se ayẹwo fun Liam nile iwosan ijọba tabi ti aladani ti owo rẹ ko wọn ju ohun ti agbara rẹ ka lọ.

Bakan naa ẹbi Aloba tun n fẹ gba asẹ ile ẹjọ pe ki oagba osisẹ to n se ayẹwo oku ti oku Mohbad wa nikawọ rẹ, lati mu ẹya ara oloogbe naa fi se ayẹwo DNA ọhun.”

Amọ sa, atẹjade naa ni gbogbo aayan lati fun aya Mohbad, Wunmi ni iwe ipẹjọ ninu ile rẹ to wa ladugbo Lekki nilu Eko, lo ja si pabo.

Agbẹjọro ẹbi Mohbad ni o nira lati fun Wunmi ni iwe ipẹjọ naa nitori pe wọn ko fi bẹẹ ri ninu ile naa lẹnu lọọ lọọ yii.

Sugbọn ikọ agbẹjọro naa ni oun yoo wa ọna miran labẹ ofin lati ri daju pe gbogbo iwe ipẹjọ ati ilana igbẹjọ naa ni wọn fun Wunmi.