Ọlọ́pàá yìnbọn pa ọkùnrin kan lọ́jà Wuse ní Abuja, wàhálà bẹ́ sílẹ̀

Aworan iṣẹlẹ ikọlu ọja Wuse ni Abuja

Oríṣun àwòrán, Frank O. Ndubishi Gcfr

Ṣe ni ibẹrubojo gba ọkan awọn eeyan to wa ni olu ilu Naijiria, Abuja, ni ọjọ Iṣẹgun bi rogbodiyan ṣe waye ni ọja Wuse laarin gbungbun Abuja.

Isẹlẹ naa ko si sẹyin iku arakunrin kan ti iroyin sọ pe awọn igbimọ agbofinro inu ọja fofin mu lori ẹsun titapasofin ọja.

Ile ẹjọ alagbeka si gbe idajọ kalẹ pe ẹkunrin naa jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Amọ arakunrin naa, ẹni ọdun mẹtadinlogun, kagbako iku lọwọ ọlọpaa kan to yinbọn pa nigba to n ṣa mọ awọn to mu lọwọ.

Ibi to ti n salọ la gbọ pe ọlọpaa kan yinbọn pa.

Ibinu iku arakunrin yii mu ki awọn eeyan kan nibẹ fariga, ti wọn si dana sun awọn ṣọọbu ati ọfisi igbimọ alamojuto ọja naa.

Ibi ti wahala naa le de, akọroyin BBC jabọ pe wọn tun fọ gilaasi awọn ọkọ kan to jẹ ti awọn alakoso ọja naa.

Wọn ni lati pe panapana wa ki wọn to le dẹkun ina to ṣe akoba fun ọja awọn oniṣowo kan naa.

A ko le fidi rẹ mulẹ boya eeyan mii padanu ẹmi wọn ninu iṣele yii.

Aworan panapana nibi ti wọn ti n ba ina fa a lọja Wuse

Ìjọba ti ọjà Wuse pa bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń sá àsálà fún ẹ̀mi wọn

Lọwọlọwọ bayii, ọja naa ti wa ni titi pa, tawọn ọlọpaa si ti gba akoso rẹ.

Innocent Amaechina, to jẹ alukoro igbimọ alakoso ọja naa fidi iṣẹlẹ yi mulẹ fawọn akọroyin kan wi pe, lootọ ni wọn dana sun awọn ile itaja ati ọkọ kan ninu ọja naa.

Amọ o lohun ko le sọ pato ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Koda o ni ohun gan n ko ribi wọ inu ọja naa.

Iṣẹlẹ yii mu ki awọn eeyan maa sa asala fun ẹmi wọn, ti awọn to ni ọja ninu ṣọọbu naa si n sare kitakita lati ko ẹru wọn kuro ninu ọja.

Aworan iṣelẹ ikọlu ọja Wuse

Ọja Wuse ati wahala gbogbo igba

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọrọ gbogbo kii ṣe lori alabahun lọrọ ọja Wuse yii jẹ niluu Abuja.

Bi wọn ko ba maa fa wahala ija laarin awọn oniṣowo ati awọn alaṣẹ ọja naa, wọn yoo maa pari rogbodiyan laarin awọn oniṣowo lori ọrọ ẹlẹya mẹya.

Ninu ọja Wuse yii kanna, ni awọn kan ti lẹ oko mọ gbajumọ akọrin ati alariya nii, Charly Boy, nigba to gbe igba ipolongo ''Our Mumu don do'' de inu ọja naa laye ijọba aarẹ Buhari.

Inu fo aya fo lọpọ fi n ba ara wọn lo ninu ọja naa, to si ṣe pe ti wahala kekere ba fi le bẹrẹ, yoo di nnkan ranto mọ awọn alaṣẹ lọwọ ni.

Laipẹ yii lawọn ọlọja inu ọja naa wọ Minisita fun olu ilu Naijiria, Nyesom Wike lọ sile ẹjọ lori ẹ̀sùn pe wọn fẹ gba awọn owo kan ti ko tẹ awọn oniṣowo naa lọrun, ti wọn si fẹ́ gbe awọn ṣoọbu kan ta lowo iyebiye.

Awọn ọlọja pẹ pẹ pẹ ati awọn mii to maa n wa ninu ọja boya awọn naa le ri iṣẹ diẹ diẹ se wa lara awọn ti awọ́n igbimọ alamojuto ọja maa n ko ju lọpọ igba.

Iṣẹlẹ ki wọn maa mu awọn iru eeyan bayi pe wọn n dọti tabi tabuku ọja ko jẹ tuntun.