Ayedatiwa kéde èròngbà rẹ̀ láti díje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, Others
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Lucky Orimisan Ayedatiwa ti kéde ìpinnu rẹ̀ láti díje dupò gómìnà ìpínlẹ̀ náà fún sáà tuntun níbi ètò ìdìbò sípò gómìnà tí yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ náà nínú oṣù Kọkànlá, ọdún 2024.
Ní gbàgede Freedom Arcade, ìlú Akure, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ondo ni gómìnà Ayedatiwa ti kéde ìpinnu rẹ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, tó sì ní òun ti ṣetán láti tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ náà lọ́dún 2025 tí sáà rẹ̀ yóò parí.
Ẹ ó rántí pé gómìnà Ayedatiwa di gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo lẹ́yìn tí gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà, Rotimi Akeredolu papòdà.
Lẹ́yìn ìpapòdà Akeredolu ni wọ́n búra wọlé fún Ayedatiwa tó jẹ́ igbákejì rẹ̀ láti tẹ̀síwájú sáà tí wọ́n ń bá bọ̀.
Ayedatiwa nígbà tó ń kéde ìpinnu rẹ̀ láti díje gẹ́gẹ́ bí gómìnà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni òun ti gbé ṣe láti ìgbà tí òun ti gba ipò gẹ́gẹ́ bí gómìnà ní oṣù Kejìlá, ọdún 2023.
Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé inú Akeredolu yóò dùn ní ibi tó wà tí òun bá rí àtìlẹyìn àwọn ènìyàn láti tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí gómìnà.
Ó fi kun pé òun máa ri dájú pé ìgbáyégbádùn àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ondo ni awọn mú ní òkúnkúndùn tí òun bá fi lè di gómìnà ìpínlẹ̀ náà.
Gómìnà náà ní òun ti ṣetán láti tẹ̀síwájú àwọn iṣẹ́ ìdàgbàsókè tí àwọn ti bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìṣèjọba Akeredolu tí òun yóò sì ri dájú pé iṣẹ́ tí àwọn ń ṣe náà kò ní já kulẹ̀.
Ó ní lára àwọn nǹkan tí òun yóò ṣe ni láti ri pé ìṣẹ́ àti òṣì di ohun ìgbàgbé ní ìpínlẹ̀ Ondo, mú àgbéga bá ètò ẹ̀kọ́.
Bákan náà ló fi kun pé àwọn máa gbé agbára wọ àwọn ọ̀dọ́, tí obìnrin náà yóò sì rí ìrọgunsápá tó péye àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ni Ayedatiwa ti fẹ́ díje dupò gómìnà.

Ní oṣù Kẹrin, ọdún 2024 ni ìrètí wà pé ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú APC yóò wáyé níbi tí wọn yóò ti yan ẹni tí yóò gba àsíá ẹgbẹ́ náà láti díje níbi ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ náà nínú oṣù Kọkànlá.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye ló ti ń wáyé lórí ìpinnu Ayedatiwa láti díje dúpo gómìnà, tí ọ̀pọ̀ sì ń ṣe iye méjì pé bóyá ààrẹ Tinubu yóò ṣe àtìlẹyìn fún-un.
Kí Akeredolu tó jáde láyé, lásìkò tó sì wà lórí àárẹ̀ ni àwọn awuyewuye kan ti ń wáyé láàárín àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ àti Ayedatiwa.
Ìfaǹfà náà lágbára débi wí pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà gbèrò láti yọ Ayedatiwa nípò ṣùgbọ́n tí ààrẹ Tinubu padà báwọn dá sí ọ̀rọ̀ náà.
Ìròyìn tó gba ìgboro nígbà náà ni pé wọ́n ní kí Ayedatiwa lọ kọ ìwé láti fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ ṣùgbọ́n kó má ì tíì fi ọjọ́ sórí rẹ̀.
Bóyá Ayedatiwa yóò jẹ́ olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú APC níbi ètò ìdìbò oṣù Kọkànlá ọdún yìí wà lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ náà àti èsì ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ tí yóò wáyé lóṣù tó ń bọ̀.















