Ológun Israel daṣọ bojú, tì wá mọ́lé, lù wá nílù bàrà lásìkò tí wọ́n kọlu ilé ìwòsàn - Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera Gaza

Medics detained outside emergency building at Nasser hospital - from video supplied to BBC
    • Author, Alice Cuddy
    • Role, BBC News, Jerusalem

Awọn adoola ẹmi ọmọ orilẹ-ede Palestine ti sọ fun BBC pe awọn ọmọ ogun Israel fi aṣọ boju awọn, wọn ti awọn mọle, wọn tun lu awọn nilu bara lẹyin ti awọn ọmọ ogun ọhun kọlu ile iwosan wọn loṣu to kọja.

Ahmed Abu Sabha, to jẹ dokita nile iwosan Nasser ṣalaye bo ṣe lo ọsẹ kan gbako ni atimọle, nibi ti wọn ti dẹ aja si oun ti awọn ọmọ ogun Israel si kan oun lapa.

Nnkan yii kan naa ni awọn meji mii, ti wọn ko fẹ darukọ wọn sọ fun BBC sọ.

Wọn ṣalaye pe awọn ologun naa na awọn laibikita, wọn si ni ki wọn kunlẹ fun ọpọ wakati.

Nigba ti BBC kan si ileeṣẹ ọmọ ogun Israel, Israel Defense Forces (IDF), lori ẹsun naa, o kọ lati sọ ohunkohun.

Ikilọ: Awọn iroyin to wa nibi le ba inu awọn eeyan kan jẹ

Ṣaaju ni IDF ti kọkọ kọlu ile iwosan kan niluu Khan Younis laarin oṣu to kọja lẹyin to ni oun gbọ pe awọn jagunjagun Hamas wa nibẹ.

IDF tun sọ pe ibẹ ni awọn ọmọ ogun Hamas ko awọn ọmọ ogun Israel ti ọwọ rẹ ba pamọ si.

Fidio kan ti wọn ya ni bonkẹlẹ, eyii ti BBC ri ṣafihan bi wọn ṣe fi iya jẹ awọn eeyan naa bii ẹranko.

Fidio ọhun ṣafihan awọn ọkunrin ti wọn bọ aṣọ wọn titi de awọtẹlẹ, ti wọn si ka ọwọ wọn si ẹyin ori wọn.

Adari ile iwosan naa, dokita Atef Al-Hout sọ fun BBC pe ẹnikẹni to ba gbe ori rẹ soke yoo jẹ ọpalamba iya.

Onimọ kan nipa eto ilera ati ẹtọ ọmọniyan, Lawrence Hill-Cawthorne sọ pe nnkan ti awọn ologun naa ṣe ko ba ofin mu.

Ṣaaju lọjọ kejidinlogun, oṣu Keji ni ajọ WHO sọ pe ko si omi ati ounjẹ nile iwosan ọhun.

Dokita: ‘Mo ro pe ṣe ni wọn maa gbẹmi mi’

Awọn eeyan naa, ti wọn ti moribọ ninu ikọlu naa, jiyin fun BBC pe ibi ti wọn ti n ṣetọju awọn alaboyun, eyii ti wọn n pe ni Mubarak, ni IDF ti n fiya jẹ awọn oṣiṣẹ naa.

Dokita Abu Sabha sọ pe wọn mu oun lọ sinu Mubarak naa, to jẹ ile ifiyajẹnu fun IDF.

O ni “Wọn gbe mi sori aga kan, mo gbọ iro okun, ṣe ni mo ro pe wọn fẹ yẹgi fun mi.

“Lẹyin naa ni wọn fọ igo kan ti wọn fi ge ẹsẹ mi, wọn si fi ẹjẹ naa silẹ koo maa ṣan jade lara mi.”

Amọ ṣa, IDF ti sọ fun BBC pe oun kii wu irufẹ iwa bẹẹ rara.

Graphic showing parts of Nasser Hospital Complex in Khan Younis where medics say they were detained and interrogated by Israeli forces

"Awọn ologun Israel fi igi atawọn nnkan oloro miran na wa"

Awọn eeyan naa sọ siwaju si pe lẹyin akoko diẹ ni wọn ko awọn sinu ọkọ lọ si agbegbe miran.

Wọn ni awọn ologun naa fi igi atawọn nnkan oloro miran na awọn lasiko irinajo ọhun.

IDF kọ lati sọrọ lori ẹsun ti dokita Abu Sabah fi kan wọn.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ ogun Israel ko sọ fun awọn eeyan naa ni pato ẹsẹ wọn, amọ wọn ni lara ohun ti wọn n beere lọwọ awọn ni boya awọn ri ọmọ ogun Hamas lagbegbe ile iwosan naa.

Ileeṣẹ eto ilera Palestine ti Hamas n dari rẹ sọ pe, ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn eeyan to ti jade laye bayii latari ado oloro Israel si awọn ile iwosan.

Israel Defense Forces say evidence of Hamas using Nasser hospital includes weapons, medicines for hostages and a vehicle that had been used in the 7 October attacks

"Ajọ UN sọ pe ọpọ igba ni awọn ọmọ ogun Israel in fiya ti ko tọ jẹ awọn ọmọ Paletine ti wọn n mu"

Ẹwẹ, ajọ International Committee of the Red Cross (ICRC) ti sọ pe inu oun bajẹ gidi lori iroyin bi Israel ṣe n fiya jẹ awọn adoola ẹmi ni Gaza.

ICRC ni “Ko tọ ki IDF maa fiya jẹ awọn to wa ni ahamọ rẹ, o si yẹ ki wọn maa tọju wọn gẹgẹ bii eeyan ẹlẹran ara.

Atẹjade kan lati ọdọ ajọ UN sọ pe ọpọ igba ni awọn ọmo ogun Israel in fiya ti ko tọ jẹ awọn ọmọ Paletine ti wọn n mu.

Ṣugbọn IDF ti ni ko si ootọ kankan ninu ọrọ UN.

Still images from two videos showing patients with hands tied. One video was from the IDF, the other was filmed from inside the hospital