"Ilé ẹ̀kọ́ Chrisland tàpá sófin ààbò ọmọdé lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, Whitney Adediran"

Aworan Whitney Adediran

Oríṣun àwòrán, BAMBABYCARE

Igbakeji ọga agba ni ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to n ri ọrọ awọn ọdọ ati idagbasoke awujọ, Ọgbẹni Yakubu Abisogun ti sọ fun ile ẹjọ giga Ikeja niluu Eko pe, ile ẹkọ Chrisland huwa to lodi si ofin ipinlẹ Eko to da lori dida abo bo awọn ọmọde.

Abisogun ni iwadii ti fihan pe ile ẹkọ Chrisland ko wa ni imurasilẹ fun iṣẹlẹ pajawiri lasiko eto ere idaraya ti ile ẹkọ naa ṣe.

O ṣalaye pe nọọsi kan ṣoṣo ni ile ẹkọ naa ni ati pe ko si ọkọ itju alaisan pajawiri anbulansi nilẹ, to le gbe akẹkọọ to ba nilo itọju pajawiri lọ si ile iwosan.

Ti ẹ o ba gbagbe, ijọba ipinlẹ Eko gbe ile ẹkọ Chrisland, ọga agba ile ẹkọ naa ati igbakeji rẹ pẹ̀lú eeyan meji mii lọ ile ẹjọ lori iku akẹkọọ wọn, Adediran lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2023.

"Akẹkọọ to le ni 556 lo wa nile ẹkọ Chrisland, amọ 377 lo kopa nínu idije onilejile"

Ọgbẹni Abisogun to jẹri nile ẹjọ lori ọrọ iku Whitney sọ pe ile ẹkọ Chrisland ko ni oṣiṣẹ kankan to n ri ọrọ aabo awọn ọmọde, gẹgẹ bi ofin ipinlẹ Eko ṣe la a kalẹ.

O fikun ọrọ rẹ pe, o yẹ ki ile iwosan kan wa lẹgbẹ ibi ti ere idaraya naa ti n waye, amọ, ko si ohun to jọ bẹẹ.

"Oṣiṣẹ to n ri si ọrọ eto aabo awọn ọmọde lo yẹ ki o ṣiṣẹ lori ibi ti ile ẹkọ naa fẹ lo fun ere idaraya, o si ni lati wa ojutuu si ohun kohun to ba le mu ewu dani.

Amọ, ile ẹkọ Chrisland ko ni iru eeyan bẹẹ.

Ori ẹrọ ayelujara ni a ti gbọ iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni ile ẹkọ Chrisland.

A ni ẹgbẹ kan to n ri si ọrọ aabo awọn ọmọde, oniruuru ẹka ijọba ati ajọ aladani lo wa nibẹ.

Kete ti a gbọ ohun to sẹlẹ ni Chrisland ni a ṣe ipade ori ayelujara," Abisogun ṣalaye.

O ni iwadii tun fihan pe akẹkọọ to le ni 556 lo wa nile ẹkọ Chrisland, amọ 377 ninu wọn lo kopa nínu idije onilejile naa.

Agbẹjọro ile ẹkọ Chrisland ni ẹri ti Abisogun jẹ nile ẹjọ ko l'ẹsẹ nlẹ tori ko si nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye

Ọgbẹni Abisogun ni awọn akẹkọọ to le ni 500 ni wọn fi ọkọ ko lọ si ibi ti ere idaraya naa yoo ti waye lai naani eto abo to peye fun wọn.

Lẹyin iṣẹlẹ iku Whitney ni a ranṣẹ pe ile ẹkọ Chrisland, ọga agba ile ẹkọ naa, Belinda Amoo, nọọsi ile ẹkọ naa, olukọ kan, Fatai Kuku, Adebisi ati Onyema to jẹ adari ile Green House ati agbẹjọro wọn.

O ni awọn pe ipade naa lati gbọ lẹnu awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa lori ohun to ṣẹlẹ.

Amọ, agbẹjọro ile ẹkọ Chrisland ni ẹri ti Abisogun jẹ nile ẹjọ ko l'ẹsẹ nlẹ tori ko si nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Ọjọ kẹsan oṣu Keji ọdun 2023 ni iroyin kan lu ayelujara pa pe ina gba Adediran, akẹkọọ ọmọ ọdun mejila nibi ti ile ẹkọ Chrisland ti n ṣe ere idaraya onile-jile ni papa iṣere to wa ni Agege ti ọmọ naa si ku nile iwosan.

Ẹwẹ, adajọ Oyindamola Ogala ti sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹtala oṣu kẹta yii.