Ẹ gbà wá, ìjọba Ogun ń ni àwa òṣèré tíátà lára pẹ̀lú òfin oníkùmọ̀ àti sísan owó gọbọi - ANTP figbe ta

Oríṣun àwòrán, Theatre Arts Dept, Olabisi Onabanjo University
Ẹgbẹ oṣere ilẹ wa, Association of Nigeria Theatre Arts Practitioners (ANTP), ti fẹsun kan ijọba ipinlẹ Ogun lori ohun to pe lilo awọn ofin onikumọ ati sisan owo gọbọi.
ANTP ni ijọba Ogun n beere ẹgbẹrun lọna ọgun naira (20,000) lọwọ awọn osere gẹgẹ bi owo ti yoo san fun lilo abẹ igi to wa ni ibùdó aṣa (Cultural center) tawọn fún igbaradi ere ori itage tawọn fẹẹ ṣe .
Bashir Sanni, Alaga ANTP nipinlẹ Ogun lo sọ ọrọ yii di mímọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ kejila, oṣu kẹta ọdun 2024.
ANTP ṣalaye pe owo ọjọ kan ṣoṣo ni ẹgbẹrun lọsan ogun Naira náà, b'awọn ba fẹẹ lo abẹ igi náà fún ọsẹ kan.
Amọ ẹgbẹrun lọna ogoje Naira (N140,000) láwọn yóò san fún lílò abẹ igi lasan ni Cultural center to wa ni Kutọ, l'Abẹokuta.
"N20,000 lọ́jọ́ kan, N140,000 lọsẹ kan níjọba Ogun ní ká san fún lílo abẹ igi"
Alaga ANTP Ogun náà sọ pé, "ọjọ kẹjọ oṣu kẹta la gba lẹta lati ileesẹ Aṣa ati Irinajo afẹ, lẹyin ta a beere fun lilo abẹ igi ni Cultural center lati fi ṣe igbaradi (Rehearsal) fun ere ta a fẹẹ ṣe.
" F.J Ọsanyinpeju lorukọ ẹni to buwọ lu lẹta yii, akanti Wema to jẹ ti ileesẹ Aṣa lo ni ka san ẹgbẹrun lọna ogun Naira naa sí, ta a ba fẹ lo abẹ igi náà lọjọ kan ṣoṣo.
" Iyen ni pe N140,000, ẹgbẹrun lọna ogoje Naira la máa san lọsẹ kan nítorí abẹ igi lasan.
Abẹ igi to jẹ ojo le rọ, ko pa wa, ti a ko le sọ bo ṣe máa jẹ, ni wọn ni ka máa waa san ẹgbẹrun lọna ogun Naira fún ''
'Ìgbésẹ tijọba Dapọ Abiọdun n gbe yii tako ofin ere ori itage ni Naijiria'
Ẹgbẹ ANTP tẹsiwaju pe owo tijọba Gomina Dapọ Abiọdun n beere yii tako abala 613 òfin to de eré ori itage ṣiṣe ni Naijiria.
Wọn ni ofin naa sọ pe kijọba ipinlẹ ran awọn ẹgbẹ lọwọ nípa didin owo ku fún wọn ni, ki i ṣe ki wọn máa fi ara ni wọn pẹlu owo gọbọi.
Wọn ni ijọba Dapọ Abiọdun nikan lo n beere owo gọbọi bii eyi, awọn ko ri iru rẹ ri latigba ti ipinlẹ Ogun ti wa.
ANTP Ogun láwọn n pe gbogbo alẹnulọrọ lori ìṣẹlẹ yii, lati dide si atunṣe rẹ.
Wọn láwọn ko le faramọ ofin onikumọ tijọba Dapọ Abiọdun gbe wa.
Ijọba Ogun ko tapa sofin ere tiata, owo yii la fẹ́ fi tun dukia ijọba ti araalu n lo ṣe - Kọ̀misana
Kọmiṣanna fun Aṣa ati Irinajo afẹ nipinlẹ Ogun,Ọnarebu Ṣẹsan Fagbayi, ṣalaye pe irọ gbuu ati ohun to le ba orukọ rere tijọba Dapọ Abiọdun ni jẹ ni ANTP n ṣe.
Fagbayi sọ pe ohun ti ANTP Ogun sọ yii ko ṣee fìdí ẹ mulẹ, ko sí dáa rara funjọba at'awọn ẹka to ti n ti wọn lẹyìn tipẹ.
" Ẹgbẹ ANTP lawọn fẹẹ lo Cultural center, a sì gba fún wọn.
Owo ti wọn gba lọwọ wọn ki i ṣe fún nnkan meji, bi ko ṣe lati fi tun awọn nnkan ijọba ti araalu n lo ṣe ni.
"Awọn nnkan bíi ileegbọnsẹ gbogbogbo, ati ọgba ti wọn ti n ṣe igbaradi wọn ọhun paapaa."
Fagbayi sọ pe ANTP Ogun ko yanju ọrọ tan, ki wọn too lọọ máa bá orukọ ijoba jẹ nita.
O ni ijọba Ogun ko tapa sofin 6.1.3 to dé ere ori itage, wọn ko sí huwa aleebu kankan.
Bákan náà lo ni ijọba Dapọ Abiọdun yóó máa tẹsiwaju lati ran awọn ẹka Àṣà ati Irinajo afẹ lọwọ lọjọ gbogbo ni.
















