Ṣé ó tọ́ láti fòfin mú Mùsùlùmí tó ń jẹun lọsán ààwẹ̀? Àlàyé Islam rèé

Aworan ounjẹ

Oríṣun àwòrán, @MATSECOOKS

Asiko aawẹ Ramadan jẹ asiko kan tawọn musulumi jakejado agbaye maa n ṣẹnu mọ nidi jijẹ tabi mimu.

Ati ọmọde ati agba ni wọn a maa fi asiko aawẹ yi wa oju rere Alllah.

Gẹgẹ bi ọpọ ilana ninu ẹsin Islaam, aawẹ Ramadan ni awọn ofin to de gbigba rẹ ati ohun ti yoo ṣẹlẹ ti musulumi to yẹ ko gba aawẹ ba n jẹun lọsan aawẹ.

Laipẹ yi la gbọ iroyin kan lati ipinlẹ Kano, nibi ti awọn ẹṣọ amojuto ẹsin Islam, ti wọ́n n pe ni Hisbah, ti mu awọn eeyan mọ̀kànlá pe wọn n jẹun lọsan aawẹ.

Iroyin naa sọ pe, wọn tun mu arabinrin kan to n ta ẹpa, to si n jẹun nidi igba rẹ ati awọn ọkunrin mẹwaa kan ti wọn mu, to n jẹun lọsan aawẹ.

Iṣẹlẹ yii mu iriwisi orisirisi wa lati ọdọ awọn eeyan kaakiri oju opo ayelujara, ti o si mu ki wọn maa beere pe ṣe o tọ ki wọn maa tọpinpin awọn ti ko gba aawẹ lasiko oṣu Ramadan.

Lati le yanju ọrọ yii, a kan si onimọ ẹsin Islaamu kan, to si tan imọle lori ọrọ yi fun wa.

"Ko boju mu ki a maa wa awọn ti ko gba aawẹ kaakiri"

Imam Abdulsalam Olayiwola Imam jẹ onimọ nipa ẹsin Islaamu niluu Ilorin.

Bakan naa lo si ti fi igba kan jẹ adari ẹka eto Islaamu nileeṣẹ redio Radio Kwara ni ilu Ilorin.

Imam ṣalaye pe Islammu ko kan ṣadede gbe aawẹ Ramadan kalẹ, bi kii ṣe pe ko kọ awọn musulumi lẹkọ kọokan.

Lara rẹ lo ni ikora ẹni niijanu wa nidi jijẹ tabi mimu.

O ni bi o ba wa ṣẹlẹ pe eeyan kan ko gba aawẹ, to si n jẹun lọsan aawẹ, o ni eleyi ko wa ni ibamu pẹlu ẹsin.

O ni bi ko ṣe wa ni ibamu pẹlu ẹsin naa ni ko ṣe ba ẹsin mu, wi pe ki awọn eeyan kan ma wa kaakiri pe awọn n tọpinpin awọn ti ko gba aawẹ.

''Islaamu ko ni ka maa toju bọ nkan ti ko kan wa.Bi eeyan ko ba gba aawẹ laarin rẹ ati Allah ti yoo san lẹsan aawẹ lo wa.Ki a maa wa kaakiri pe a n wa eeyan ti ko gba aawẹ ko ba ojumu''

Imam tẹsiwaju pe, ki a ma gbagbe pe ẹlesin Islaamu nikan ni aawẹ di dandan fun lati gba.

O ni tori naa, ẹnikẹni tabi ikọ kankan to ba n jade lati wa awọn ti ko gba aawẹ, ko gbọdọ de ọdọ awọn ẹlẹsin mii lawujọ ti musulumi ati ẹlẹsin mii ba wa.

"Eyi ni awọn eeyan ti Islaamu faaye silẹ fun pe wọn le ma gba aawẹ"

Ninu alaye rẹ, Imam Olayiwola sọ pe igbalaye wa fun awọn musulumi kan lati mase kopa ninu aawẹ ninu oṣu Ramadan.

Lara awọn to ṣe lalaye pe wọn gba laaye lati mase gba aawẹ̀ ni oloyun, iya to n fun ọmọ lọ́mú, arugbo jọkujọku, obinrin to n ṣe nkan oṣu, arinrinajo ati ọmọde ti ko tii lagbara lati bẹrẹ si ni gba aawẹ.

''To ba ṣẹlẹ pe ẹni kan wa lara awọn ta a ka kalẹ yii, ti ko si gba aawẹ, ohun to tọ ni pe ki ẹni naa mase bọ si ita gbangba lati maa jẹun.''

Imam sọ pe wọntun wọnsi ni gbogbo nkan.

''Bi Islaamu ko ṣe faaye gba ki eeyan maa wa awọn ti ko gba aawẹ kiri, bẹẹ naa ni ko ni ki awọn ti ko gba aawẹ naa maa jẹun ni ita gbangba''

O ṣalaye pe lara ẹkọ Islaamu naa ni wi pe ki eeyan bo aṣiri nkan ti yoo mu ki awọn eeyan maa beere pe, ki lo de ti o fi n ṣe nkan to yatọ si awọn ara yoku.

"Ijiya ẹni ti ko gba aawẹ wa laarin oun ati Allah, idanilẹkọ lo ṣe pataki, kii ṣe ifiyajẹni"

Lootọ la o ri akọsilẹ wi pe awọn to mu awọn to n jẹun lọsan aawẹ fi iya jẹwọn ṣugbọn Imam ṣalaye pe eleyi to ṣe anfaani ju ni ki wọn ṣe idanilẹkọ fun wọn.

O ni kii ṣe gbogbo eeyan naa lo gbọ alaye nipa ẹsin.

''Bi wọn ba ṣe n ri awọn eeyan yii, idanilẹkọ lo ṣe koko dipo pe ki wọn ni lọkan lati fi iya jẹ wọn.

Wọn ko le ṣo boya iru ẹni naa wa lara awọn ti aaye gba lati maṣe gba aawẹ.''

Imam ni lopin igba ti wọn ba ṣalaye fun ẹni to jẹun nita, yoo jẹ ko mọ wi pe nkan to ṣe ko bojumu.

''Ati pe ti ijiya kankan ba wa fun iru eeyan bẹẹ, aarin oun ati Alaah lo wa.

Idi ni pe Allah lo ni ẹsan aawẹ lọdọ, ohun naa lo si ni ijiya lọdọ fun ẹni ti o ba n jẹun lọsan aawẹ.''