Iléeṣẹ́ iná mọ́nàmọ́ná kéde àdínkù owó ìná ẹ̀lẹ́ńtíríkì

Awon opo ina mọnamọna

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin ayọ de fun gbogbo awọn onibara ileeṣẹ ina mọnamọna Ikeja Electricity Distribution Company, IKEDC nilu Eko pẹlu bi ileeṣẹ naa ti ṣe kede mimu adinku ba owo ina ti awọn onibara to wa loju owo Band A.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ amunawa naa, Olufadekẹ Omo-Omorodion ṣalaye lọjọ Aje pe pe dipo igba ati marunlelokoo naira, (N225) ti awọn onibara to wa loju opo ina manamana naa n san fun ọwọ ina kọọkan ti wọn ba n lo, wọn ti din in ku si igba o le mẹfa naira.

Gẹgẹ bi ọrọ to sọ, Ọjọ Aje, ọjọ kẹfa oṣu karun un ni adinku naa bẹrẹ ifidimulẹ.

O ni eyi ko ni ṣe akoba fun ipese ina fun ogun wakati si wakati mẹrinlelogun lojumọ fun awọn eeyan wọnyii rara.

Igbesẹ ileeṣẹ ina manamana IKEDC yii ko ṣai nii ṣe pẹlu ariwo irora araalu to wọ tọ ikede afikun owo ina fun awọn to wa loju opo ina mọnamọna Band A loṣu diẹ sẹyin.