Àwọn àǹfàní àti àléébù wo ló wà nínú fífi owó kún owó òṣìṣẹ́?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Àwọn kan gbàgbọ́ pé kò sí ohun tó dára tí kìí ní àléébù tirẹ̀.
Àmọ́ tó bá di ọ̀rọ̀ àlékún owó òṣìṣẹ́, àwọn òṣìṣẹ́ kì í fẹ́ gbà pé àléébù kankan wá nínú kí àlékún gorí owó ọ̀yà.
A ò lè sọ pé wọ́n lẹ́bi fún ìgbàgbọ́ yìí nítorí àwọn onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé gan náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn àǹfàní tó wà nínú ṣíṣe àlékún owó òṣìṣẹ́ ju àléébù rẹ̀ lọ.
Ní Nàìjíríà, ìjọba àpapọ̀ ní àwọn ti fi ìdá mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sí márùndínlógójì kún owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà ń sọ pé kí ìjọba ṣe àtúngbéyẹ̀wò oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́, tí wọ́n sì ń bèèrè fún ₦615,000 gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí gbogbo nǹkan ṣe ń gbówó lórí. Ọ̀wọ́n gógó àwọn ọjà ní Nàìjíríà ti wọ ìdá 33.20 gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí àjọ tó ń rí sí òǹkà ní Nàìjíríà ìyẹn National Bureau of Statistics ṣe gbe jáde.
Pẹ̀lú bí àwọn nǹkan ṣe ń gbówó lórí yìí, àwọn onímọ̀ sọ pé ìjọba nílò láti rí pé wọ́n pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn kan kí owó tí wọ́n bá máa fi kún owó òṣìṣẹ́ le ní ìtumọ̀.
Èyí ló mú wa ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àǹfàní àti àléébù tí yóò wà tí ìjọba bá fi owó kún owó òṣìṣẹ́.
'Kìí ṣe òṣìṣẹ́ ìjọba nìkan ni yóò jẹ àǹfàní àlékún owó náà'

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/SHUTTERSTOCK
Nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ bá ń sọ fún ìjọba pé kí wọ́n fi owó kún owó oṣù àwọn, ọ̀pọ̀ àwọn tí kìí ṣe òṣìṣẹ́ ìjọba ni wọ́n máa ń bèrè pé àwọn ńkọ́.
Àwọn onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé ní òṣìṣẹ́ tó ń gba owó nìkan kọ ni yóò jẹ àǹfàní yìí pàápàá lásìkò tí Nàìjíríà wà lónìí.
Olùkọ́ ìmọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Umar Musa Yar’Adua, Katsina, Ọ̀mọ̀wé Abdussalam Abubakar ní ipele èèyàn tó máa jẹ àǹfàní náà pọ̀.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ló jẹ́ pé ayálégbé ni wọ́n àti pé lára owó oṣù tí wọ́n bá gbà náà ni wọ́n ti máa san owó fún onílé wọn.
Ọ̀mọ̀wé Abdussalam Abubakar ṣàlàyé pé bí owó bá ṣe wà lọ́wọ́ òṣìṣẹ́ sí ni yóò sọ bí yóò ṣe ra nǹkan sí tí ó bá dé ọjà.
Ó ní iye nǹkan tí òṣìṣẹ́ bá rà lọ́jà ló máa sọ iye tí àwọn ọlọ́jà máa mú lọ sílé àti pé owó náà ń tàn ká ní, pé ọrọ̀ ń gba bẹ̀ tàn bẹ́ẹ̀ náà ni.
O fi kun pé fífi owó kún owó òṣìṣẹ́ yóò fún ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ní àǹfàní láti tọ́jú ìdílé wọn dáadáa àtàwọn tí wọ́n gbọ́kàn lé wọn fún àtijẹ, àtimu pẹ̀lú ìtọ́jú.
Ọ̀mọ̀wé Murtala Abdullahi Kwarah ti ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Umaru Musa Yar’Adua bákan náà kín àwọn ọ̀rọ̀ yìí tó sì ní dandan ni kí ìjọba ṣe àlékún owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́.
“Tí ìjọba kò bá ṣe àfikún owó oṣù, kò sí ohun tó ṣeéṣe, ó dára kí ìjọba fowó kún owó kí òṣìṣẹ́ lè máa rí nǹkan rà bó bá léwó.”
Ọ̀mọ̀wé Murtala Abdullahi Kwarah ní ìjọba nílò láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan tí wọ́n bá fẹ́ kí àlékún owó oṣù ní ìtumọ̀ sáwọn òṣìṣẹ́.
Ó ní àkọ́kọ́ ohun tí ìjọba nílò láti ṣe ni láti wá ojútùú sí bí owó náírà ṣe ń já wálẹ̀ sí owó dọ́là ní gbogbo ìgbà.
Ọ̀mọ̀wé Abdussalam ní àwọn nǹkan tí òṣìṣẹ́ nílò ni ohun tí wọ́n yóò máa gùn lọ sí ibi iṣẹ́ lójúmọ́, ètò ìlera wọn àtàwọn nǹkan míì.
Ó ní àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìjọba gbọ́dọ̀ mójútó yàtọ̀ sí owó oṣù.
Àwọn nǹkan tó lè má mú àlékún owó oṣù wúlò

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/SHUTTERSTOCK
Pẹ̀lú bí àwọn òṣìṣẹ́ ṣe ń pòùngbẹ àlékún owó oṣù, bí èèyàn bá wo bí àwọn ọjà ṣe ń gbówó lórí, ó fẹ́ ẹ̀ dàbí pé àlékún náà kò wúlò.
Èyí tó burú jùlọ ni ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ.
Ọ̀mọ̀wé Abdussalam ní bí owó oṣù òṣìṣẹ́ bá lọ sókè, ó túmọ̀ sí pé owó tí àwọn ilé iṣẹ́ fi ń pèsè ọjà wọn ti gbẹ́nu sókè nìyẹn.
Ó ní bí owó bá ṣe pọ̀ lọ́wọ́ àwọn èèyàn sí máa ń fa àlékún owó orí ọjà lọ́pọ̀ ìgbà.















