Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìdìbò ààrẹ tó bẹ̀rẹ̀ ní Chad

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọjọ́ Kẹfà, oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 ni àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Chad yóò dìbò láti yan Ààrẹ tuntun.
Àwọn olùdíje mẹ́wàá ló ń díje, tí wọ́n sì ń jìjàdù kí ipò náà já mọ́ àwọn lọ́wọ́.
Ilé aṣòfin orílẹ̀ èdè Chad ti ṣe àtẹ̀jáde orúkọ àwọn olùdíje tí wọ́n ti fi èròńgbà wọn hàn láti díje dupò Ààrẹ náà.
Ètò ìdìbò ọ̀hún ló ń wáyé lẹ́yìn ikú Ààrẹ àná, Idriss Deby tó dágbére fáyé lórí ipò lọ́dún 2021.
Ọmọ rẹ̀, Mahamat Idriss Deby, tí òun náà ń díje dupò Ààrẹ, ló gba ipò bàbá rẹ̀ láti inú oṣù kẹrin ọdún 2021 tí bàbá rẹ̀ tí jáde láyé.
Succès Mastra, tó jẹ́ Olóòtú ìjọba fún Mahamat, náà wà lára àwọn tó ń wá ipò láti di Ààrẹ Chad, òun sì ni alátakò gbòógì tí Deby ń kojú.
Olùdíje ogún ló fi ìwé ẹ̀rí wọn kalẹ̀ síwájú ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ètò ìdìbò èyí tó wáyé láàárín ọjọ́ Kẹfà sí ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹta fún àyẹ̀wò.
Àmọ́ olùdíje mẹ́wàá ni ìgbìmọ̀ náà buwọ́lù pé wọ́n yege láti díje pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí tí wọ́n gbé dání àtàwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n yẹ̀wò.
Lára àwọn tí wọn kò buwọ́lu ni àwọn alátakò gbòógì méjì; Nassour Ibrahim Neguy Koursami àti Rakhis Ahmat Saleh nítorí wọ́n kùnà láti ni àwọn nǹkan tí ìgbìmọ̀ ọ̀hún ń bèèrè fún.
Ètò ìdìbò ààrẹ lásìkò tí orílẹ̀ èdè kò fararọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Láti ìgbà tí ìjọba ti fi owó kún iye owó bẹntiróòlù, tó fi mọ́ ọ̀rọ̀ àwọn tó ń ṣe àtìpó ni nǹkan kò ti fararọ ní orílẹ̀ èdè Chad èyí tó mú kí ìjọba kéde pé ìlú kò fararọ lórí ọ̀rọ̀ oúnjẹ ní orílẹ̀ èdè náà.
Àjọ tó ń gbógunti ebi lábẹ́ àkóso àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ní àwọn ọmọdé tí iye wọn tó 480,000 ni wọn kò rí oúnjẹ tó dára jẹ ní Chad.
Bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo ìgbìyànjú àwọn àjọ Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọniyan láti ṣe ìwọ́de láti tako gbogbo nǹkan tó ń lọ ní orílẹ̀ èdè náà ni ìjọba ń wọ́gilé.
Mahamat Idriss Deby ń díje láti di ojúlówó Ààrẹ orílẹ̀ èdè náà táwọn èèyàn bá dìbò fun.
Ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kẹwàá, ọdún 2024 ni ìrètí wà pé wọ́n yóò gbé ìjọba kúrò lọ́wọ́ àwọn ológun bọ́ sí ọwọ́ alágbádá.
Ahmet Barchiret, ẹni tó jẹ́ alága àjọ tó ń ètò ìdìbò ní ọjọ́ yìí ni orílẹ̀ èdè náà yóò padà sọ́wọ́ ìjọba alágbádá.
Iye ènìyàn tí yóò kópa nínú ìdìbò náà
Nínú oṣù Kejìlá ọdún 2023 ni ètò ìdìbò kan wáyé láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá àwọn ti ṣetán láti dìbò Ààrẹ.
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Chad, ANGE ní ìdá mẹ́tàlélọ́gọ́ta àwọn èèyàn orílẹ̀.èdè Chad ló kópa nínú ìdìbò náà.
Pẹ̀lú iye yìí, èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ ló ti forúkọ sílẹ̀ láti dìbò nínú àpapọ̀ èèyàn mílíọ̀nù 17.72 tó wà ní orílẹ̀ èdè náà.
Àwọn èèyàn yìí ló máa dìbò níbi ètò ìdìbò Ààrẹ.
Àjọ tó ń mójútó ètò ìdìbò ní Chad

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìwé òfin orílẹ̀ èdè Chad ló ní àṣẹ láti ṣètò ìdìbò ààrẹ àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin. Lẹ́yìn ètò ìdìbò, ìgbìmọ̀ yìí náà ló ní àṣẹ láti kéde èsì ìdìbò àtàwọn tó jáwé olúborí lẹ́yìn tí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò bá ti fi àwọn èsì ìbò náà ránṣẹ́ sí wọn.
Ìgbìmọ̀ ìwé òfin orílẹ̀ èdè Chad, èyí tí Jean-Bernard Padaré jẹ́ alága rẹ̀, ní ọmọ ìgbìmọ̀ mẹ́sàn-án tó fi mọ́ àwọn Adájọ́ ilé ẹjọ́ Májísíréètì márùn-ún.
Ìgbìmọ̀ yìí ló ní àṣẹ láti ṣe ìwádìí olùdíje, kí wọ́n sì tẹ orúkọ àwọn dáńtọ́ láti díje síta fún gbogbo ènìyàn.
Níbi ètò ìdìbò àpapọ̀ orílẹ̀ èdè tó wáyé gbẹ̀yìn, àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ló ṣètò ìdìbò tí wọ́n sì kéde èsì ìdìbò àmọ́ tí èyí yí padà nínú oṣù kìíní nígbà tí wọ́n gbé iṣẹ́ kíkéde èsì ìdìbò sábẹ́ àjọ National Election Management Agency (ANGE).
Ìgbìmọ̀ ANGE jẹ́ ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ẹ̀dógún èyí tí wọ́n yàn látara àwọn ará ìlú tí wọ́n gbàgbọ́ pé wọ́n ṣe dédé láwùjọ.
Ọdún méje ni sáà kan ló wà fún ìgbìmọ̀ yìí, tí wọ́n sì lè tún wọn yàn fún sáà kan péré si. Èyí túmọ̀ sí pé èèyàn kò lè lò kọjá sáà méjì lọ nínú ìgbìmọ̀ ANGE.
Iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ANGE ni láti àmójútó ìgbáradì fún ètò ìdìbò, ri dájú pé àwọn ohun èlò ìdìbò péye, gbé orúkọ àwọn tó lè dìbò jáde gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe là á kalẹ̀.
Fún àwọn ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ àti ẹkùn, ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Chad ni yóò gbé èsì wọn síta.
Ta ló lẹ́tọ̀ọ́ láti dìbò ní Chad?
Abala kẹta òfin ètò ìdìbò ní Chad ní ẹnikẹ́ni tó bá ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún ló ní àǹfàní láti dìbò.
Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ dìbò gbọ́dọ̀ forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò orílẹ̀ èdè náà.
Òfin náà ní ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ dìbò kò gbọdọ̀ ní ohun tí wọn kò fi ní gbà á láyè láti dìbò lára
Báwo ni ètò ìdìbò náà yóò ṣe rí?
Ètò ìdìbò Chad máa ń wáyé nípa pé olùdìbò yóò dìbò fún olùdíje kan péré, olùdíje tí wọ́n bá dìbò fún jùlọ ló máa jáwé olúborí.
Ọdún márùn-ún ni sáà kan tí Ààrẹ tí wọ́n bá dìbò fun yóò lò, tí wọ́n sì tún lè tun yàn fún sáà kan péré si.
Olùdíje tó bá ní ìbò tó pọ̀ jùlọ ló jáwé olúborí.
Àmọ́ tí kò bá sí ẹni tó ní ìbò tó pọ̀ jù níbi ètò ìdìbò àkọ́kọ́, ètò ìdìbò mìíràn yóò wáyé ní ọjọ́ Àìkú kejì tó bá tẹ̀lé ọjọ́ tí wọ́n ṣètò ìdìbò àkọ́kọ́.
Àwọn olùdíje méjì tó bá ń léwájú ni wọ́n máa ṣètò ìdìbò kejì yìí fún.
Olùdíje tó ní ìbò tó pọ̀ jùlọ níbi ètò ìdìbò kejì yìí ni wọ́n máa kéde gẹ́gẹ́ bí ẹni tó gbégbá orókè.
Ta ló lè díje dupò Ààrẹ Chad?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abala 148 òfin ètò ìdìbò Chad là á mọ́lẹ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ díje dupò Ààrẹ Chad gbọ́dọ̀ ní àwọn nǹkan wọ̀nyí:
- Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Chad, bàbá tàbí ìyá rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Chad, kò sì gbọ́dọ̀ ní ìwé ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè mìíràn.
- Ó gbọ́dọ̀ ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógójì
- Ó ní ẹ̀tọ́ láti kópa nínú òṣèlú àti láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀.èdè
- Ó gbọ́dọ̀ ní ìlera tó péye lára àti ní ọpọlọ
- Ó gbọ́dọ̀ ti gbé ní orílẹ̀ èdè náà fún odidi ọdún kan gbáko láàárín ọdún mẹ́ta
- Gbé ní agbègbè tí wọ́n yóò ti máa ri tó bá jẹ́ òṣìṣẹ́ ètò ààbò
- Ó gbọ́dọ̀ fi mílíọ̀nù tí saif sí akoto owó orílẹ̀ èdè Chad, èyí tí wọ́n máa dá padà fún un tó bá ní ìdá mẹ́wàá nínú gbogbo ìbò tí wọ́n bá dì.
Àwọn tó ń díje nínú ètò ìdìbò yìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Láàárín ọjọ́ Kẹfà sí ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kẹta ni àwọn olùdíje ti fi ìwé ẹ̀rí wọn ṣọwọ́ láti fi ìfẹ́ wọn sí ìdíje sípò Ààrẹ hàn.
Adelé Ààrẹ Chad, Mahamat Idriss Deby, tí àgbáríjọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ‘Chad United Coalition’ ń ṣe àtìlẹyìn fún ń díje níbi ètò ìdìbò náà.
Bákan náà ni Olóòtú ìjọba orílẹ̀ èdè Chad, tó ti ń lòdì sáwọn ètò ìjọba fún ìgbà pípẹ́, Succès Mastra wà lára àwọn tí wọ́n ní ó yege láti díje.
Àwọn méjèèjì yìí ni àwọn olùdíje gbòógì tó ń léwájú nínú ìdíje náà
Bákan náà ni Lydie Beassemda tó jẹ́ obìnrin kan ṣoṣo nínú àwọn olùdíje náà. Ìgbà kejì rèé tí Lydie yóò máa díje dupò Ààrẹ.
Ó díje dupò lọ́dún 2021 tó sì gba ipò Kẹta lẹ́yìn Pahimi Padacké Albert tó gbé ipò Kejì.
Pahimi Padacké Albert, tó jẹ́ Olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ rí ní Chad náà ń díje níbi ètò ìdìbò ọdún yìí.
Yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí, àwọn mìíràn tó tún ń díje ni:
- Alladoum Djarma Baltazar
- Assyongar Masra Success
- Bebzouné Bongoro Theophile
- Lydie Beassemda
- Mahamat Idriss Deby Itno
- Mansiri Lopsékréo
- Mbaimon Guedmbayë Brice
- Nasra Djimasngar
- Pahimi Padacke Albert
- Yacine Abderamane Sakine
Báwo ni wọ́n ṣe ń kéde èsì ìbò ní Chad?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Òfin ètò ìdìbò tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ látọwọ́ àwọn aṣòfin fìdí ẹ ní wọn kò ní lẹ èsì ìbò sí ibùdó ìdìbò lẹ́yìn tí wọ́n bá kà á tán.
Bákan náà ni wọn kò ní fún àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú ní ẹ̀dà ìwé èsì ìdìbò. Èyí yàtọ̀ sí nǹkan tó ti máa ń wáyé tẹ́lẹ̀.
Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ètò ìdìbò, ANGE ní ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún lẹ́yìn ètò ìdìbò láti fi kéde èsì ìdìbò náà.
Àwọn ìgbìmọ̀ ANGE yóò gba èsì ìbò lẹ́yìn tí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò bá ti kà á tán gẹ́gẹ́ bí abala 67 ìwé òfin ètò ìdìbò ṣe là á kalẹ̀.
ANGE ni yóò gba èsì ìbò ibùdó kọ̀ọ̀kan àmọ́ àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ni yóò gbé èsì ìbò ẹkùn kọ̀ọ̀kan síta.
Ní Chad, ìgbìmọ̀ Constitutional Council ló lẹ́tọ̀ọ́ láti kéde èsì ìdìbò ààrẹ.
ANGE yóò fi èsì ìbò náà ránṣẹ́ sí ilé ẹjọ́ gíga níbi tí wọ́n ti máa ṣàyẹ̀wò àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó bá wà nínú ètò ìdìbò náà.
Gbèdéke ọjọ́ tí wọ́n yóò fi kéde èsì ìdìbò wà lọ́wọ́ bí àwọn olùdíje bá ṣe faramọ́ ètò ìdìbò náà sí.
Tí olùdíje kan bá ní ètò ìdìbò náà kò tẹ́ òun lọ́rùn, ìgbìmọ̀ náà ní ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún lẹ́yìn tí ANGE bá fi èsì ìbò ránṣẹ́ sí wọn kí wọ́n tó kéde rẹ̀.
Àmọ́ tí kò bá sí kọ́nú-n-kọ́họ kankan, wọn yóò kéde èsì ìdìbò náà láàárín ọjọ́ mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí òfin ètò ìdìbò Chad.
Níbi ètò ìdìbò tí yóò wáyé yìí, tí kò bá sí ẹnikẹ́ni tó jáwé olúborí, ANGE yóò ṣàgbékalẹ̀ ètò ìdìbò mìíràn lọ́jọ́ Kejìlélógún oṣù Kẹfà ọdún 2024.
Ní ọjọ́ Keje, oṣù Keje ni ìrètí wà pé wọn yóò kéde èsì ìbò tó bá jẹ́ pé wọ́n ṣètò ìdìbò kejì.
Ní ogúnjọ́, oṣù Keje, ọdún 2024 ni ìrètí wà pé wọ́n yóò fi èsì ìdìbò léde pátápátá.















